Wo àwọn olùdíje sípò ààrẹ tí INEC fòntẹ̀ lu láti kópa nínú ètò ìdìbò ọdún 2027

Awọn oludije sipo aarẹ ti INEC kede

Oríṣun àwòrán, Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ti kede awọn oludije ti yoo kopa ninu eto idibo sipo aarẹ ti yoo waye lọdun 2027.

Yatọ si awọn oludije sipo aarẹ ti ajọ INEC fi sita, wọn tun kede orukọ awọn igbakeji ti wọn yoo jọ dije du ipo naa ninu oṣu Kinni, ọdun 2027.

Ninu orukọ naa ti INEC gbe jade, eyi ti akọwe rẹ, Rose Oriaran-Anthony, buwọ lu lọjọ Abamẹta to kọja niluu Abuja, lo ti fidi rẹ mulẹ pe awọn oludije naa ni ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun fi ranṣẹ si wọn.

Awọn wo ni oludije naa?

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima ni yoo dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC

Atiku Abubakar to ti figba kan ri jẹ igbakeji aarẹ nilẹ Naijiria niegbẹ oṣelu ADC fa kalẹ fun ipo aarẹ, pẹlu igbakeji rẹ, Chibuike Rotimi Amaechi.

Peter Gregory Obi, to jẹ gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra, ẹni to tun jẹ oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu LP lọdun 2023 ni ẹgbẹ oṣelu NDC fa kalẹ bayii pẹlu igbakeji rẹ, Onimọ-ẹrọ Rabi'u Musa Kwankwaso.

Ẹgbẹ oṣelu APM, fa Gomina Seyi Abiodun Makinde tipinlẹ Oyo kalẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ lọdun 2027, ati igbakeji rẹ, Musa Lawal Daura, to jẹ ọga ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tẹlẹ.

Ẹgbẹ oṣelu AAC, fa Omoyele Sowore kalẹ gẹgẹ bi oludije, ati igbakeji rẹ to jẹ Haruna Garba Magashi.

Awọn miran nkọ?

Sunday Chibuzo Okereke, ni ẹgbẹ oṣelu Labour fa kalẹ lati dije fun ipo aarẹ, nigba ti igbakeji rẹ jẹ Hajja Bintu Konto.

Ni ti PDP, Sandy Ojang Onor, ni wọn fa kalẹ fun ipo aarẹ, nigba ti Umaru Babangida yoo jẹ igbakeji rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu AA, Rufai Adekunle Omo-Aje, kalẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ, pẹlu Shehu Hussaini, ti yoo ṣe igbakeji rẹ.

Aliyu Abbas-Bin ni ẹgbẹ oṣelu ADP fa kalẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ, ati Chinazam Ike, ti yoo ṣe igbakeji rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu APP fa Kabiru Yusuf kalẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ, nigba ti igbakeji rẹ jẹ Peace Egobia Ofordile.

Awọn wo tun ni?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbẹ oṣelu BP ni Sunday Adenuga yoo ti dije fun ipo aarẹ, oun pẹlu igbakeji rẹ tii ṣe Usman Turaki Mustapha.

Ẹgbẹ oṣelu DLA lo fa Moses Olusoji Adebisi ati Nafisat Usaku Abubakar, kalẹ gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ ati igbakeji aarẹ.

Ada Elizabeth Fredrick Okwori ni ẹgbẹ oṣelu NDP fa kalẹ gẹgẹ bii oludije sipo aarẹ, pẹlu Uchenna Anthony Chukwuemeka ti yoo ṣe igbakeji rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu NRM buwọ lu Nkem Esther Okereke gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ Naijiria, ati Nasir Muhammed Sulaiman ti yoo ṣe igbakeji rẹ.

Ẹgbẹ oṣelu PRP buwọ lu Donald Duke, fun ipo aarẹ, oun pẹlu Kabiru Rabiu to jẹ igbakeji rẹ.

Awọn yooku ni ẹgbẹ oṣelu SDP to fa Adewole Ebenezer Adebayo kalẹ fun ipo aarẹ, ati Usman Muhammed Bugaje, ti yoo ṣe igbakeji rẹ.

YPP fa Peter Ada Agada kalẹ lati dije fun ipo aarẹ, nigba ti Patience Ndidi Key, yoo ṣe igbakeji rẹ.

Lakotan, ẹgbẹ oṣelu ZLP, Daniel Daberechukwu Nwanyanwu kalẹ lati dije fun ipo aarẹ, nigba ti wọn buwọ lu Hassan Khalid, gẹgẹ bi igbakeji aarẹ.