Ìpolongo ìbò Gómìnà bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ètò ìdìbò 2027, àmọ́, ìgbà wo ni Oriyomi àti Gudugudu yóò mọ ìpín wọn fẹ́gbẹ́ Accord l'Oyo?

Oríṣun àwòrán, Obafemi Hamzat/X/Sharadeen Alli/X/Solomon Adeola/X
Awọn oludije sipo gomina kaakiri orilẹede Naijiria bẹrẹ ipolongo ibo l'Ọjọru ọjọ kẹsan an oṣu Kẹsan an ọdun yii, ṣaaju eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Amọ, ẹgbẹ oṣelu Accord ko tii ni oludije gomina kan pato ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo ninu idibo ọdun 2027 tori ko si orukọ Oriyomi Hamzat ati Olakunle Busari ninu akọsilẹ ajọ eleto idibo INEC, gẹgẹ bi iwadii ti BBC News Yoruba ṣe sọ.
Bi ipolongo ibo ṣe bẹrẹ bayii, awọn oloṣelu yoo maa ṣabẹwo si awọn ileeṣẹ iroyin, bakan naa ni wọn yoo maa ṣe ipolowo lori redio ati ẹrọ amohunmaworan to fi mọ patako ipolowo to maa n wa loju popo kaakiri.
Amọ, o ni awọn ofin kan tawọn oludije sipo gomina gbọdọ tẹle lasiko ipolongo ibo.
Awọn ofin yii jẹ ilana to wa ninu ofin eto oṣelu 2026 eyi to sọ pe oludije sipo gomina ko gbọdọ na ju biliọnu mẹta naira lọ.
Ṣugbọn ki ni ofin sọ ti oludije ba na ju biliọnu mẹta naira lo lasiko ipolongo ibo.
Ki ni awọn nnkan ti oludije le ṣe ati nnkan ti ofin ko gbawọn laye lati ṣe lasiko ipolongo ibo?
Elo ni oludije gomina le na lasiko ipolongo ibo, ati pe ki ni ijiya to wa labẹ ofin fun oludije to ba na ju bẹẹ lọ?
Gẹgẹ bi akosilẹ ofin eto oṣelu ọdun 2026 abala 92(3) ṣe sọ, oludije sipo gomina ko gbọdọ na ju biliọnu mẹta naira lọ lasiko ipolongo ibo.
Amọ, nnkan to wa nibẹ ni pe biliọnu mẹta naira ni oludije sipo gomina le na lasiko ipolongo ibo.
Eyi yatọ si owo tawọn eeyan le fi ṣeranwọ fun oludije sipo gomina to n dupo oṣelu.
Abala 92(8) ofin eto oṣelu Naijiria sọ pe awọn eeyan le fi owo to le N500m ran oludije sipo gomina lọwọ.
Fun apẹẹrẹ, ti ẹnikan ba fun oludije sipo gomina ni N600m, owo naa ti fi N100m tayọ iye ti ofin la kalẹ wi pe awọn eeyan le fi ṣeranwọ fun oludije sipo gomina lọ.
Abala 92(10) ofin eto oṣelu Naijiria sọ pe iru ẹni bẹẹ le san faini ilọpo marun un iye ti owo na fi ju iye ti ofin la kalẹ lọ.
Fun apẹẹrẹ, N500m ni yoo jẹ faini ti iru ẹni bẹẹ yoo san labẹ ofin.
Ki ni yoo ṣẹlẹ ti oludije sipo gomina ba na ju N3bn lọ lasiko ipolongo ibo?
Abala 92(9) ofin eto oṣelu Naijiria sọ pe irufẹ oludije sipo gomina to ba ti na ju biliọnu mẹta naira lọ yoo:
San ida 1% faini iye owo ti ofin faye gba pe ki o na lasiko ipolongo ibo
Le lọ sẹwọn oṣu mejila tabi ko lọ sẹwọn ko si tun san faini.
Eyi tumọ si pe oludije sipo gomina to ba na ju biliọnu mẹta naira lọ lasiko ipolongo ibo le san ọgbọn miliọnu naira ko si tun fi ẹwọn ọdun kan jura.
Ki ni ofin sọ nipa awọn ẹgbẹ oṣelu?
Abala 93 ofin eto oṣelu Naijiria yanana iye owo ti ẹgbẹ oṣelu le na yatọ si owo ti oludije sipo oṣelu lanfaani lati na.
Ajọ eleto idibo pẹlu ajọṣepọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu lo le sọ iye ti ẹgbẹ oṣelu le na lori ipolongo ibo.
Ofin la a kalẹ fun awọn ẹgbẹ oṣelu lati jabọ iye ti wọn ba na fun ajọ eleto idibo laarin oṣu mẹfa tie to idibo ba ti waye.
Awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ salaye iye ti wọn na, ohun ti wọn na owo naa le lori atawọn nnkan ti wọn ba lo fun eto idibo naa.
Abala 93(8) la a kalẹ wi pe abọ inawọ ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ni orukọ, adirẹsi, iṣẹ ati iye ti awọn eeyan to ba fowo silẹ fun ipolongo ibo ninu.
Abala 93(6) ofin eto idibo Naijiria sọ pe ẹgbẹ oṣelu gbọdọ ṣafihan iye ti wọn na lori ipolongo ibo ninu iwe iroyin meji ati lori itakun agbọrọkaye ẹgbẹ.
Ofin sọ pe ẹgbẹ gbọdọ ni akọsilẹ ẹnikẹni to ba fun ẹgbẹ ni owo to ju N100m lọ.
Ofin eto idibo Naijiria sọ pe yoo san N10,000,000 ti wọ ba na ju iye ti ofin la kalẹ lọ.
Ki lawọn oludije le ṣe lasiko ipolongo ibo atawọn nnkan ti wọn o le ṣe?
Ofin sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu to forukọ silẹ atawọn oludije sipo oṣelu lati ṣe oniruuru ipade ati ipolongo ṣaaju eto idibo.
Awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ eleto aabo mii gbọdọ pese aabo to peye fawọn ẹgbẹ oṣelu atawọn oludije sipo oṣelu lasiko ti wọn ba pejọ fun ipolongo ibo tabi ipade.
Amọ, ko gbọdọ si ede abuku si ẹsin, ẹya lasiko ti wọn ba n ṣe ipolongo ino.
Fun apẹẹrẹ, oludije le tako eto ti alatako rẹ ba fẹ ṣe, ṣugbọn ko le le ede abuku yala lori ẹsin tabi ẹya alatako oṣelu.
Awọn nnkan mii tawọn oludije gomina le ṣe atawọn nnkan ti wọn o le ṣe niyii:
Awọn oludije sipo oṣelu le kawọn eeyan jọ lati ṣatilẹyin fun wọn, amọ, wọn o le ko ikọ to n lo ohun ija jọ.
Awọn oludije le ṣe ipolongo amọ wọn o gbọdọ ṣe ipolongo ibo ni wakati mẹrinlelogun si ọjọ idibo gan an gan an.
Oludije sipo gomina le na biliọnu mẹta naira lori ipolongo ibo, amọ, wọn o le ju bẹẹ lọ.
Awọn oludije sipo gomina le ṣe ipolongo ibo nileeṣẹ iroyin, amọ, wọn o le lo ileeṣẹ lọna ti ko tọ.
Awọn oludije sipo gomina le ṣepade oṣelu nibi kibi ṣugbọn wọn o le ṣe iru ipade naa ni ṣọọṣi tabi ni mọṣalaaṣi.
Awọn oludije sipo gomina le ṣe oriṣiiriṣii lati ni atilẹyin oludibo, amọ, wọn o le fun awọn oludibo ni riba.
Ko si orukọ Oriyomi Hamzat ati Olakunle Busari fẹgbẹ Accord ninu akọsilẹ INEC fun eto idibo gomina Oyo
Awọn Oludije mejeeji sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord, Oriyomi Hamzat ati Olakunle Busari tawọn eeyan mọ si Guduudu ti n sọ kede wi pe awọn ni yoo soju ẹgbẹ oṣelu Acoord ninu eto idibo fun ipo gomina ipinlẹ Oyo, abọ iwadii BBC News Yoruba ti fidi rẹ mulẹ pe ko si orukọ ẹnikankan ninu awọn mejeeji ninu akọsilẹ INEC.
Ninu ọsẹ yii ni Oriyomi Hamzat ti ṣe abẹwo si ọpọ awọn ile iṣẹ iroyin ati awọn lẹgbẹ lẹgbẹ lati rọ wọn ki wọn le dibo fun ninu eto idibo ọdun to un bọ.
Ṣugbon iwadii BBC News Yoruba si ọfiisi ajọ eleto idibo INEC ẹka ipinlẹ Oyo fi han wi pe ko si orukọ oludije sipo gomina lati inu ẹgbẹ oṣelu Accord kankan ninu orukọ awọn oludije sipo gomina to wa ninu akọsilẹ INEC fun eto idibo ọdun 2027.
Oṣisẹ ajọ INEC kan to sọrọ ṣalaye wi pe edeaiyede to wa ninu ẹgbẹ oṣelu Acoord ni ko jẹ ki orukọ oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu naa ko wa lara awọn orukọ awọn ti yoo dije dupo gomina ipinlẹ Oyo lati ẹgbẹ oṣelu naa.
O ni, ajọ INEC yoo gbe orukọ awọn ti wọn yoo soju ẹgbẹ kọkan jade lọjọ kejila oṣu yii,eleyii ti yoo ṣe afihan awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idiboyan sipo gomina ipinlẹ Oyo.




























