Orí mi ni Garuba fẹ́ gé féú, ọwọ́ tí mo fi dáàbòbo ara mi, ló padà fi àdá ọwọ́ rẹ̀ gé – Adájọ́ tí olújẹ́jọ́ fi àdá gé lọ́wọ́ lásìkò ìgbẹ́jọ́ sọ̀rọ̀ síta

Aworan arakunrin kan to mu ada dani.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iṣẹlẹ agbayanu kan waye ninu ileẹjọ kan ni ijọba ibilẹ Fufore ni ipinlẹ Adamawa, lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria. Arakunrin kan to n jẹjọ niwaju ileẹjọ kan fi ada ge ọwọ adajọ to n gbọ ẹjọ̀ naa kuro.

Orukọ adajọ ti iṣẹlẹ laabi yii ṣẹlẹ si ni Dauda Hamman to gbọ ẹjọ ni ileẹjọ agbegbe Mayo-Ine Area Court, Ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2026 ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ lasiko to n gbọ ẹjọ ọrọ ilẹ laarin Dauda Garba ẹni ọdun mẹtadinlaadọrun kan ati arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ismail Yusuf.

Gẹgẹbi iroyin ti iwe iroyin abẹle Daily Trust gbe jade, ọkan lara awọn ti ọrọ ẹjọ naa ṣoju wọn lo n sọrọ niwaju ileẹjọ lọwọ, Adajọ Garba n bi arakunrin naa leere ibeere ti ko ye e, bi adajọ naa ṣe n gbiyanju lati da si ọrọ naa nipa ṣiṣe alaye ibeere rẹ fun un ni Ọgbẹni Garba ba bẹrẹ si ni yọ ṣuti ete si adajọ naa.

Adajọ naa ṣalaye iṣẹlẹ naa funrarẹ fun awọn akọroyin ni ile iwosan to ti n gba itọju. O ni bi Ọgbẹni Garba ṣe n bu oun yii, lo tun n lerileka pe oun le ṣe nnkan to ju eebu ti oun n bu adajọ naa lọ.

Ori mi lo fẹ fi ada ge amọ ọwọ ni mo fi daabo bo ori mi - Adajọ Hamman

Aworan ẹnu ọna to wọ yara igbẹjọ kan.

Bi awọn agbofinro ṣe n gbiyanju lati gbe ọkunrin naa jade kuro ninu yara igbẹjọ naa l o ba sa mọ wọ̀n lọwọ ti o si lọ fa ada to ti yọ kẹlẹkẹlẹ mu wọ ileẹjọ naa to si sare si adajọ ni.

Adajọ Hamman ṣalaye siwaju sii pe bi Garba ṣe n gbe ada naa bọ lori oun loun sare gbe ọwọ soke lati daabo bo ori oun. Feu lada naa ge ọwọ oun to si ku diẹ ki o ge ọwọ̀ naa ja.

Awọn eeyan to wa ninu yara igbẹjọ parapọ kawọ arakunrin naa ko, wọn gba ada naa lọwọ rẹ ki ọlọpaa to fi panpẹ ofin mu u, ti wọn si gbe adajọ naa lọ si ileewosan fun itọju.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Adamawa sọ pe wọn ti gbe arakunrin naa lọ si ile ẹjọ Majisireeti agba kan ni Yola, olu ilu ipinlẹ naa nibi ti wọn ti fi ẹsun ṣiṣe eeyan ni ijamba kan an ni ibamu pẹlu abala igba o le mọkandinlogun iwe ijiya iwa ọdaran ti ipinlẹ Adamawa.

Ṣe ofin faye gba mimu nnkan elo aṣenilọṣẹ wọ ile ẹjọ?

Ile ẹjọ jẹ ibi to ni ọwọ pupọ, tobẹ gẹgẹ to jẹ wi pe gbogbo awọn to ba farahan nibẹ, titi kan awọn agbẹjọro lo gbọdọ maa ṣọ iwa hu nibẹ.

Agbẹjọro kan ba BBC News sọrọ, o ni lootọ ko si ofin to la ihuwasi ni ile ẹjọ kalẹ, ṣugbọn o ni awọn iwa ọmọluwabi kan ti eniyan gbọdọ maa hu to ba di ti ọrọ ileẹjọ.

Lara awọn iwa naa niwọnyii:

Ko gbọdọ si ohun ija kankan ni sakani ile ẹjọ

Idakẹ jẹẹ ni ile ẹjọ gbọdọ wa

O ko gbọdọ ka fọnran kankan silẹ tabi ya fidio ni ile ẹjọ ayafi ti adajọ ba fun ọ laṣẹ lati ṣe bẹẹ.

Gbogbo eeyan lo gbọdọ̀ dide ki adajọ lasiko to ba fẹ wọle tabi jade ninu yara igbẹjọ.