Ìṣẹ́ alájótà, àtàwọn ohun tuntun míràn tí o kò mọ̀ nípa Temitope Osoba, gbajúmọ̀ òṣèré tí wọ́n ń sin òkú rẹ̀ lónìí

Oríṣun àwòrán, Temitope osoba/instagram/Abiola Adekunle/Facebook
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja oṣerebinrin nni, Temitope Kofoworola Osoba ti jade laye, Ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni Temitope Osoba jade laye lẹni ogoji ọdun, oni ọjọbọ ọjọ kẹwaa oṣu kẹsan an ni wọn yoo sin oku rẹ ni ilu Ipẹru Rẹmọ.
Ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Temitope Osoba. Ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 1985 ni wọn si bi oloogbe naa niluu Abẹokuta, nibẹ si lo ti bẹrẹ sii nifẹ si iṣẹ tiata, lati kekere.
Temitope Osoba tan mọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Olusegun Osoba, nitori pe inu idile kan naa ni Segun Osoba ati baba Temitope ti jọ jade. Amọṣa, ko duro lati maa lo orukọ naa fi gbe ara rẹ, o jade sita, o si ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe oun ni orukọ toun, fun igbelarugẹ orukọ idile Osoba.
Ẹkọ imọ nipa okoowo (Business Education) ni Osoba ni, ni fasiti Olabisi Onabanjo to wa niluu Ago-Iwoye, ipinlẹ Ogun.
Imọ ẹkọ naa lo fi kun iṣẹ rẹ to yan laayo, eyi tii ṣe tiata, fun igbelarugẹ gbigbe ere jade, ati kikopa ninu ere.
Temitope Osoba di Alajota

Oríṣun àwòrán, Temitope Osoba/Instagram
Temitope ko ṣa deede bẹrẹ iṣẹ tiata lojiji. ṣaaju iṣẹ tiata, tipẹtipẹ ko too bẹrẹ sii farahan ninu awọn ere agbelewo, lo ti n ṣiṣẹ alajota, to si tun n jo ninu awọn awo orin loriṣiriṣi.
Nigba to ṣiṣẹ alajota titi, lo ri anfaani lati wọnu iṣẹ tiata, to si ẹrẹ lẹkunrẹrẹ ni nnkan bi ọdun 2005. Gbara to wọle, lo ti bẹrẹ sii lokiki, to jẹ ki wọn maa lo o kaakiri.
Awọn iṣẹ fiimu agbelewo to ti kopa
Ọpọ ere agbelewo ti ko lonka ni Osoba kopa ninu rẹ nigba to wa laye, lara rẹ si ni Gucci Girls ti ọdun 2012, Accident to jade lọdun 2013, ati Ifedolapo to jade lọdun 2015, ati awọn miran ti a ko le mẹnuba tan.
Bi Osoba ṣe n kopa inu ere gẹgẹ bii jagidijagan, bẹẹ lo n kopa alawada ati iyaale ile, to fi mọ awọn miran.
Bo ṣe kofiri aisan jẹjẹrẹ ọmu
Ọdun 2024 ni Osoba ṣakiyesi koko kan lẹgbẹ ọmu rẹ. Kaka ko pa ẹnu rẹ mọ, ko si maa woran, niṣe lo.
O ṣeni laanu pe kaka ki awọn oniṣegun oyinbo fun un ni amoran, nipa bi yoo ṣe tete tọju ara rẹ, ko si ṣiṣẹ abẹ, niṣe ni wọn sọ pe ko si nnkan nibẹ.
Diẹdiẹ ni jẹjẹrẹ naa n dagba, ko to tun sare pada lọ, leyi to jẹ ko pada ṣiṣẹ abẹ.
Lasiko ti iṣẹ abẹ naa n lọ lọwọ, Osoba ṣe fọnran sita lati fi gba awọn obinrin lamọran nipa itọju ara ẹni, to si fi ara rẹ ṣe apẹẹrẹ.
Ọpọ awọn ololufẹ ati ọrẹ rẹ ni wọn dide iranlọwọ fun un nigba to jade lati ṣalaye nipa iṣoro to n koju.
Lẹyin to pada ṣiṣẹ abẹ tan, ti wọn si gbe jẹjẹrẹ naa jade, awọn dokita sọ fun un pe o gbọdọ lo oogun fun ọdun kan, ti ko si gbọdọ loyun, depodepo wi pe yoo bimọ.
Eyi lo jẹ ko jade lati bẹbẹ fun iranlọwọ awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ rẹ lori oogun ti awọn dokita ni ko maa lo loore-koore.
Si iyalẹnu, awọn ẹlẹyinju aanu dide kaakiri Naijiria ati lagbaye, ko to tun pada sidi iṣẹ tiata rẹ.
Lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo ti Osoba ṣe lẹyin iṣẹ abẹ, awọn dokita sọ fun un pe jẹjẹrẹ naa ko tii tan kaakiri ara rẹ.
Eyi lo si ṣalaye lori ayelujara fun awọn ololufẹ rẹ, nibi to ti n dupẹ.
Bi ara rẹ ṣe pada bọ sipo, lo n jẹ iyalẹnu nla fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ, ti wọn si n wo o gẹgẹ bi awokọṣe nipa awọn ti ori ko yọ lọwọ aisan jẹjẹrẹ.
Ipolongo aisan jẹjẹrẹ ọmu
Temitope Osoba di ohun to ja geere fun ipolongo aisan jẹjẹrẹ ọmu fawọn obinrin.
Lẹyin to ti gbadun, ti ara rẹ ya, o bẹrẹ sii ṣe ipolongo fun awọn obinrin lati maa ṣayẹwo ara, paapaa ọmu wọn loore-koore, lati le tete kofiri aisan naa lara, ko too pẹ ju.
Bi ko ṣe fi ọrọ sabẹ ahọn sọ fawọn eeyan, lo fa a ti gbogbo bi awọn obinrin ṣe n bo ẹnu lati sọrọ jade, paapaa lagboole amuludun.
Iku Temitope
Bi iroyin Temitope Osoba ṣe jade sigboro aye lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 to dakẹ, lẹni ogoji ọdun, lo ti jẹ kayeefi fun awọn eeyan, paapaa awọn to sunmọ ọn.
Bi awọn kan ṣe n gbera ṣanlẹ, lawọn miran n wa ẹkun mu, pẹlu bi iku naa ṣe ba wọn lọkan jẹ to.
Gbajugbaja oṣere kan ti wọn n pe ni Alesh Sanni lo kọkọ gbe iroyin naa jade sori ikanni ayelujara, leyi to ṣe ọpọ ni kayeefi.
Latigba naa lawọn akẹgbẹ rẹ ti bẹrẹ sii gbe e kaakiri, ti wọn si n ṣedaro iku rẹ.
Ipa to fi lelẹ
Yatọ si idi iṣẹ tiata, ipa rere ni Temitope Osoba fi lelẹ.
Awọn ipa to fi lelẹ yii ni ko le jẹ ki awọn eeyan tete gbagbe rẹ, paapaa loju iworan.
Osoba fi awọn igbe aye rẹ to ṣokunkun lati tan imọlẹ fun awọn obinrin bii tiẹ, to si fun awọn obinrin to n koju ipenija aisan jẹjẹrẹ ni ireti ọjọ iwaju rere.
O fun ọpọ obinrin ni igboya lati koju iṣoro aisan jẹjẹrẹ nigbakugba to ba wọle de.



























