'Mo wá sí Naijiria láti kojú ọmọ Yahoo tó fẹ́ lu ìyá mi ni jìbìtì àmọ́ ohun tí mo bábọ̀ rèé'

Oríṣun àwòrán, Carlos Barragán
"Mi o ri wọn bii ẹni to nimọ to dabi alara, wọn o ja fafa bẹẹ naa, wọn yami lẹnu."
Nigba ti Carlos barragán gbera wa si Naijiria lati wa ẹni to lu iya rẹ ni jibiti fifẹ lori ayelujara, o ro wi pe ẹni onijibiti kan gboogi ni ẹni ti oun n bọ wa ba.
Nọmba idanimọ ori foonu rẹ ṣafihan pe Naijiria lo ti n fi awọn atẹjiṣẹ ranṣẹ sori foonu iya Carlos lodi si Syria to ni oun wa gẹgẹ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika to ni oun jẹ.
Amọ dipo ko sawari ọdaran kan gboogi, Carlos ba ara rẹ lẹni to n lo ọdun mẹrin lati fi mọ bi awọn ọmọkunrin to n ṣe "Yahoo" ni Naijiria ṣe n ṣọṣẹ.
Awọn ọdọmọkunrun ti ko ni ẹkọ imọ iwe to bẹẹ, ti ko fi bẹẹ si owo lọwọ wọn, ti wọn n lu jibiti lori ayelujara.
Iriri naa mu ki Carlos yi ipinnu rẹ pada lori ero rẹ nipa to n gbero lati lu iya rẹ ni jibiti, to si tun wo ipa ti adawa n ni lori awọn eeyan lode oni.
Pipade Brian

Oríṣun àwòrán, Carlos Barragán
Carlos juwe iya rẹ bi ẹni to le, obinrin to ta tan lọwọ ara rẹ. Onimọ nipa eyi to ni ile iwosan ara rẹ, ko jọ ẹni ti wọn kan le lu ni jibiti. Eyi lo mu ki Carlos atawọn ọmọ iya rẹ ji giri nigba ti wọn bẹrẹ si ni funra pe wọn ti n lu iya awọn ni jibiti.
Akọranṣẹ kan to kọ ranṣẹ si ololufẹ rẹ lori ayelujara ti orukọ rẹ n jẹ Brian ṣafihan ohun to le mu ko bọ sọwọ awọn onijibiti.
"Mo ṣe itọju iya mi, lẹyin naa aburo mi obinrin, mo tọju ọkọ mi atawọn ọmọ. Emi ni mo maaa n ṣetọju awọn eeyan, ni bayii mo fẹ ki eeyan tọju emi naa."
Ṣaaju ni Carlos gba iya rẹ, ẹni to ti kọ baba wọn silẹ, nimọran lati darapọ mọ ikanni ayelujara kan, Tinder nigba to kiyesi pe iya oun n dawa pupọ.
Nibẹ lo ti pade Brian to pe ara rẹ ni ọmọ ilẹ Amẹrika ti ọjọ ori re ti le ni aadọta, to si ni Syria ni oun ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọmọ ogun ilẹ Amẹrika.
Ara fun ẹgbọn Carlos to jẹ Ologun to si sọ fun iya wọn pe o ṣeeṣe ki ẹni naa je onijibiti.
Lati igba naa ni iya ko ti fi ọrọ ọkunrin naa lọ ẹgbọn Carlos mọ amọ to maa n fi awọn atẹjiṣẹ ti Brian ba fi ranṣẹ sii han Carlos.
Ọrọ ifẹ wọn n dun ti Brian si ti bẹrẹ si ni sọrọ bi o ṣe maa ko lọ si Spain ki awọn jọ le tete wa papọ, ohun to ya iya Carlos gan lẹnu.
"Mo ro pe oun gan n fura," Carlos sọ.
Ariyanjiyan waye laaarin ẹbi wọn nigba ti iya fi oruka meji han Carlos pe oun ati ololufẹ oun ko ni pẹ maa gbe papọ mọ eyi lo si mu ki Carlos bẹrẹ iwadii Brian.
Iyalẹnu lo jẹ fun iya rẹ nigba to fi ẹri han-an pe lati ipinlẹ Eko ni wọn ti n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sii lodi si Syria to ti gbagbọ tẹlẹ ti eyi si ba a ninu jẹ.
Eyi lo mu Carlos lati ṣe irinajo lọ si ipinlẹ Eko lati ṣawari ẹni to fẹ lu iya rẹ ni jibiti naa.
Biggie, Ikotun atawọn ọmọ Yahoo

Oríṣun àwòrán, Carlos Barragán
Carlos beere fun iranwọ ẹni ti oun naa n lu jibiti ori ayelujara, Biggie, to si gba lati mu mọ awọn ọrẹ rẹ kan, to si tun mu kaakiri gbogbo Ikotun. Ikotun jẹ agbegbe kan ni ipinlẹ Eko nibi ti ọpọ awọn ọdọ ti n sare ati la.
Ẹni to ti le ni ogun ọdun ni biggie bii ti Carlos. O jẹ ẹni to maa n ṣawada to si ja fafa.
Awọn mejeeji jọ n gbe pọ, ti Carlos si ni oun ti bẹrẹ si ni fẹran rẹ.
O ni oun maa n ro o pe bawo ni eeyan bii tirẹ ṣe le maa lu jibiti lori ayelujara, ti yoo maa fi gbogbo oru ba ajoji sọrọ lori ayelujara.
Nigba to bẹrẹ si ni ba ọpọ araalu sọrọ lo ri pe ọpọ awọn eeyan lo n lu jibiti lori ayelujara ti wọn n pe ni "Yahoo Boys".
Lẹyin naa lo han sii pe o ṣeeṣe ki oun ma rii ẹni to fẹ lu iya oun ni jibiti ninu ọpọ eeyan to kun orilẹ ede Naijiria.
Kaka bẹẹ niṣe lo bẹrẹ si ni kọ nipa bi awọn ọdọkunrin to n lu jibiti ori ayelujara ṣe n gbe aye wọn.

Oríṣun àwòrán, Carlos Barragán
Gẹgẹ bi ọmọ ilẹ yuroopu alawọfunfun, Carlos n da yatọ ni gbogbo ibi ti wọn ba lọ. O ni ọpọ lo maa n ro o pe ọlọpaa ọtẹlẹmuye ni oun tabi pe oun jẹ oniṣowo lati ilẹ China.
Wọn maa n pe e ni "Maga", orukọ ti wọn maa n fun eni ti wọn ba le tete lu ni jibiti.
Pẹlu iranlọwọ Biggie, o ni anfaani lati ba aadọta awọn ọmọ yahoo sọrọ ti ọkan lara si jẹ ẹni to n lo aworan agba onijakadi ilẹ Amẹrika, Cody Rhodes, to si tan obinrin kan lati san owo ọkọ baalu eeyan mẹẹdọgbọn ti ẹnikẹni ko lo.
Owo ti obinrin naa kọkọ fun-un jẹ ọọdunrun Euro, owo to ju owo oṣu mejidinlogun lọ ni ileeṣẹ to ti n ṣiṣẹ.
Ṣugbọn kii ṣe bẹẹ naa ni wọn maa n sare ri owo gba, wọn maa n ba ọpọlọpọ eeyan sọrọ ki w.on to ri eeyan to maa fun wọn lowo.
Carlos tun sunmọ ọmọ yahoo mii ti orukọ rẹ n jẹ Azeez, ẹni to bẹrẹ jibiti ori ayelujara nigba to wa lọmọ ọdun mẹrinla.
Azeez maa n pe ara rẹ fun awọn ọkunrin Amẹrika ni Vanessa pẹlu lilo aworan obinrin ilẹ okeere kan.
Ni ibẹrẹ, ko ri ọwọ mu nitori ko gbọ ede Gẹẹsi to bẹẹ, bẹẹ naa si ni ko ni ọrẹbinrin ri tabi de ilẹ Amẹrika ri.
"Awọn ọmọde ti ko nimọ nipa bi nnkan ṣe ri nilẹ okeere ni a n sọrọ wọn," Carlos sọ.
Owo ti o kọkọ gba jẹ dọla marun-un, to sin a lati fi jẹ ẹran adiẹ nile ounjẹ.
Nigba ti iya ati iyaiya Azeez mọ nipa iṣẹ yii, wọn fun ni gbedeke pe ko fi iṣẹ jibiti silẹ tabi ki awọn kọ ọ lọmọ, lati igba naa ni ko si ti lu jibiti mọ.

Oríṣun àwòrán, Carlos Barragán
Carlos ni oun balẹ si Naijiria pẹlu igbagbọ pe awọn onijibiti wa lara awọn ọdaran to nimọ ni Naijiria ni ṣugbọn ibaṣepọ rẹ pelu Azeez yi erongba yii pada.
O ni o rọrun lati gbagbọ pe awọn alagbara kan lo n lu awọn ni jibiti lati ẹkun iwọ oorun Africa ju nnkan ti oun ri pẹlu awọn ọmọkunrin to mu foonu yii lọwọ.
Ibeere kan to gba ọkan rẹ ni pe bawo ni awọn ọdọmọkunrin, ti ọpọ wọn ko i tii pari ẹkọ wọn ṣe n ri awọn iya wọn ba sọrọ lati fi ọkan tan wọn.
O ni wọn sọ fun oun pe awọn maa n pese ohun ti ọpọ eeyan ko ni: ibaṣepọ.
"Wọn sọ fun mi pe ohun kan ti awon maa n fun awọn eeyan naa ni asiko, bibeere nipa igbeaye wọn, ohun ti wọn, bi wọn ṣe wa."
Carlos sọ pe inilo fun ibaṣepọ, ti didawa maa n fa fun eeyan wa lara ohun to jẹyọ lọpo igba nigba ti oun ba awọn eeyan to ko sọwọ awọn onijibiti yii.
Carlos ti kọ iwe nipa iriri pẹlu awọn onijibiti yii, The Yahoo Boys.
Iroyin yii jẹ ọkan lara awọn iṣẹ Outlook ti BBC World Service ti Vibeke Venema ati Julian Siddle jẹ ollotu rẹ.
Becca Johns ati Global Journalism lo kọ akọọlẹ yii.
























