Sunday Igboho sọ̀rọ̀, orí ayélujára tún gbóná jain-jain, áláyé rèé

Sunday Igbohun wọ aṣọ dudu, o mu gbohungbohun dani, o n rẹrin-in. Awọn ẹṣọ aabo iru ẹkun wa lẹyin rẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ẹni to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation to tun jẹ oludasilẹ ẹṣọ aabo Iru Ekun ti jẹjẹẹ lati mu alekun ba igbaiyanju ẹṣọ aabo rẹ lati gba ilẹ Yoruba kuro lọwọ awọn agbebọn.

Igboho sọ eyi lasiko to n ṣe ifilọlẹ Iru Ekun ni ilu Akure, olu ilu ipinlẹ Ondo nibi to ti jẹjẹẹ pe ẹṣọ aabo Iru Ekun yoo maa tẹsiwaju lati ṣiṣẹ ninu awọn igbo to wa nilẹ Yoruba lati gba awọn agbẹ lọwọ ikọlu awọn agbebọn.

Ninu fidio kan to gba ori ayelujara ni Igboho ti n sọ fun awọn ẹṣọ aabo naa pe agbebọn ti wọn ba ti ba ibọn lọwọ rẹ ninu igbo ni ki wọn pa lẹyẹ o sọka.

O sọ pe gbogbo awọn ti wọn ba ba pẹlu awọn agbebọn naa yala o jẹ Yoruba tabi Igbo ni ki wọn pa papọ amọ ki wọn ri daju pe awọn ko ẹtọ awọn eeyan ti ko mọwọ mẹsẹ loju mọlẹ.

"Ohun to le tan iṣoro awọn agbebọn ni Naijiria ni pipa enikẹni ti wọn ba ti ba ibọn lọwọ rẹ"

"Ti ẹ ba wa ninu igbo, ti ẹ ba gburoo pe awọn agbebọn wọ ibikan, agbebọn ti ẹ ba ba ibọn lọwọ ẹ, ẹ pa.

"Ti ẹ ba ri ọmọ Yoruba pẹlu ẹ ti wọn jọ n ṣe e pọ, ẹ pa pọ. To ba jẹ Igbo lẹ ri to n ji eeyan gbe, ẹ pa danu.

Igboho ṣekilọ fawọn ẹṣọ aabo naa pe wọn ko gbọdọ funa tabi ba awọn Hausa tabi Fulani to b awa laaarin igboro ilu, to n ta ọja rẹ ja nitori ọmọ Naijiria kan naa ni gbogbo wa.

Ṣugbọn o ni ẹnikẹni to ba jẹ pe iṣẹ ajinigbe tabi ipaniyan lo bay an laayo, to n dena awọn agbẹ lati lọ soko, ti wọn n fi ibọn ṣọṣẹ yala ninu igbo tabi igboro ni ki awọn ẹṣọ aabo naa pa lẹsẹkẹsẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O woye pe ti wọn ba mu awọn afurasi ọdaran bẹẹ, ti wọn ṣẹṣẹ n gbe wọn lọ sọdọ awọn ọlọpaa, o ṣeeṣe ki ilana awọn ọlọpaa ma ya ni kiakia ati pe ti wọn ba ti tu awọn afurasi bẹẹ silẹ ni wọn tun maa n pada sidii iṣẹ ibi wọn.

O woye pe ohun to le tan iṣoro awọn agbebọn ni Naijiria ni pipa enikẹni ti wọn ba ti ba ibọn lọwọ ọ rẹ yala laaarin adugbo tabi inu igbo ti wọn si le fidi rẹ mulẹ ni tootọ pe agbebọn ni lẹsẹkẹsẹ.

"Nnkan ti a n sọ yii, ohun to le mu alaafia wa niyẹn. Ti ẹ ba gbọ pe awọn agbebọn di ọna lọna Ondo si Ilesa, Ondo si Osun, Ondo si Ekiti, Ondo si Abuja, ti ẹ ba ti gbọ ọ, ẹ ọ fun ọga ọlọpaa to ba wa ni agbegbe naa pe ẹ n lọ sibẹ.

"Ti ẹ ba ti ba awọn agbebọn naa ni ẹsẹ titi, ẹ pawọn danu, ẹ ma fi akoko ṣofo rara."

Igba akọkọ kọ niyi ti Oloye Sunday yoo maa sọ fun awọn eeyan rẹ lati pa awọn agbebọn ti wọn ba ti ba ninu igbo.

O sọ eyi nigba to ṣe abẹwo si ilu rẹ, Igboho nib ii oṣu meji sẹyin lẹyin ti awọn agbebọn ṣọṣẹ ni ilu naa leralera ti wọn si pa alaboyun kan, ji ọpọ eeyan gbe.

"Eto aabo kii ṣe ohun to yẹ lati tọwọ oṣelu, ọrọ ẹsin tabi ẹlẹyamẹya bọ"

Ṣaaju ni Igboho ti woye pe adinku ti n ba ijinigbe, ikọlu awọn agbebọn, ikọlu awọn agbẹ atawọn darandaran atawọn iwa ọdaran mii nilẹ Yoruba eyi to fori rẹ sọ akitiyan awọn ọlọpaa pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ Ologun, awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ atawọn ẹṣọ aabo mii.

O juwe eto aabo bii ojuṣe ti kọja ohun to yẹ lati fi oṣelu mu tabi fi ṣe ẹlẹyamẹya, to si fi kun pe idi Pataki ti oun fi gbe ẹṣọ aabo naa kalẹ ni lati mu kawọn eeyan ni igboya ninu akitiyab ijọba lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan.

O wa rọ awọn ẹṣọ aabo naa lati ri daju pe wọn ko kaaarẹ ọkan ninu ojuṣe wọn, ki wọn ri daju pe wọn n tẹsiwaju lati maa mu igbe aye nira fawọn ọdaran titi ti gbogbo awọn ọdaran naa fi maa fi ilẹ Yoruba silẹ patapata.

O tun tẹsiwaju lati pe fun ajọṣepọ to danmọran laaarin awọn ọlọpaa awọn ẹṣọ aabo abẹnu nitori aabo to peye ni ọpakutẹlẹ idagbasoke eto ọrọ aje ati awujọ to duro ire.

Bakan naa lo rọ Aarẹ Bola Tinubu lati ṣatilẹyin fun ẹṣọ aabo Iru Ekun bo ṣe ni awọn da ẹṣọ aabo naa silẹ lati lati mu igbega ba ẹkun guusu iwọ oorun Naijiria ni.

Igboho ṣekilọ fawọn ẹṣọ aabo naa lati ri daju pe wọn tẹlẹ ilana ati gbogbo ofin to gbe ẹṣọ aabo naa duro, ki wọn si ma fi ẹmi ara wọn wewu ki wọn ma ba a fi ẹmi wọn ṣofo nibi ti wọn ba ti n gbiyan ju lati da aabo bo ilu.