'Ọ̀nà wà láti ìlú wa lọ sí ọ̀run, egúngún kò sì gbọdọ̀ wọ ìnú ìlú wa'- Èyí ni ìlú tí a kò tí gbọ́dọ̀ ṣe ògùn owó tàbí sun àgbàdo tà
Ilẹ Yoruba jẹ orilẹ kan pataki lagbaye pẹlu ọpọlọpọ awọn nnkan arameriiri. Lara awọn ara wọ̀nyi naa ni Egungun jẹ. Igbagbọ ilẹ Yoruba ni pe awọn ara ọrun lo maa n yirapada di Egungun wa sile aye lati wa ṣe ọmọ araye loore.
Amọṣa pẹlu gbogbo igbagbọ yii, ilu kan n bẹ ni ilẹ Yoruba ti Egungun ko gbọdọ wọ. Ilu Ọba Ile ni ipinlẹ Ondo ni. Kii kuku ṣe wi pe Egungun kii wọ ilu yii lati ipilẹ pẹpẹ, awọn iṣẹlẹ to gbomi loju ẹni kan lo ṣẹlẹ eleyii to mu ki o di eewọ fun Egungun lati tun da ẹsẹ tẹ ilu naa.
Yatọ si eyi ilu Ọba ile ni ọna kan ti wọn gbagbọ wi pe o lọ si ọrun ti wọn si n tori bẹẹ pe ọna naa ni ọna ọrun. Ẹnikẹni to ba gba ọna naa lọ to si pada wale ni wọn maa n pe ni ara ọrun.
Awọn eewọ pọ fun awọn ọmọ bibi tabi olugbe ilu Ọba ile. Lara wọn ni pe:
- Ọmọ ilu Ọba Ile kankan ko gbọdọ ṣe ogun owo.
- Ọmọ ilu Ọba ile kankan ko gbọdọ ṣe ẹgbẹ ogboni tabi ẹgbẹ awo kankan.
- Lati mọ sii nipa awọn eewọ miran to lagbara ni ilu Ọba ile, ẹ wo fọnran yii.



