Ẹ yàgò fún òṣèlú kí epo má baà ta sí àlà yín, Makinde kìlọ̀ fún àwọn Ọba Oyo

Gomina Seyi Makinde mu gbohungbohun lọwọ, o wọ aṣọ ofi ati fila

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kilọ fun awọn ori ade ni ipinlẹ naa ki wọn ṣọra fun ọrọ oṣelu, bi bẹẹ kọ, ijọba oun yo fi ọwọ oloṣelu mu wọn.

Makinde lo ṣekilọ yii lasiko to n sọrọ ni aafin tuntun ti Eleruwa ti ilu Eruwa, Ọba Samuel Adegbola ti wọn ṣẹṣẹ ṣi.

Asiko ti wọn n ṣi aafin tuntun naa lo tun jẹ ayẹyẹ ọdun kan Kabiesi lori oye.

Gomina ọhun rọ awọn ọba ki wọn dẹkun ati maa da si ọrọ oṣelu, ki wọn ma gbe sẹyin oloṣelu kankan ki wọn ma si ta oloṣelu kankan nu.

O ni "Ipo ẹlẹgẹ ni awọn ọba alaye di mu lawujọ ko si yẹ ki wọn wọ ipo naa sinu ọrọ oṣelu.

"Niṣe lo yẹ ki awọn ọba alaye jẹ baba fun gbogbo oloṣelu to wa lagbegbe wọn lai wo inu ẹgbẹ ti irufẹ oloṣelu bẹẹ wa.

"Eyikeyi ori ade to ba yan lati maa kopa ninu oṣelu gbọdọ ṣetan lati jẹ ki a fi ọwọ oloṣelu mu oun. Ti ẹ ba fẹ jẹ ori ade, ẹ yago fun oṣelu."

Makinde sọ siwaju si pe ijọba ko fi ọwọ kekere mu awọn ọba alade, oun ko si ni dẹkun atilẹyin oun fun awọn ori ade naa kaakiri ipinlẹ Oyo.

O kilọ pe ki awọn oriade ma ri atilẹyhin ijọba gẹgẹ bii ipe lati maa kopa ninu oṣelu.

Gomina naa tun ke si awọn ori ade ki wọn tẹsiwaju lati maa gbe ni alaafia pẹlu awọn ti wọn jẹ ọba le lori.

O rọ wọn ki wọn maṣe jẹ ki ọrọ oṣelu ba orukọ wọn jẹ gẹgẹ bii ori ade ti awọn araalu n bu iyi fun.

Lara awọn to wa nibi eto naa ni awọn ọba alade, agbagba oloṣelu nipinlẹ Oyo, awọn lọgalọga nileeṣẹ ijọba atawọn eekan ọmọ Naijiria mii to wa ba Eleruwa ṣe ayẹyẹ ọdun kan rẹ naa lori oye.