Kí ló dé tí iléeṣẹ́ ọmọogun fi gbé adarí ikọ̀ tó ń gbógun ti Boko Haram àtàwọn agbébọn kúrò pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun 15 míràn? Ohun tí a mọ̀ rèé

Ọmọ ogun Naijiria lori ọkọ ti wọn gbe ibọn le lori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun oriilẹ ni Naijiria, Ọgagun Waidi Shaibu ti buwọlu gbigbe awọn olori mẹrindinlogun ni oniruru ẹka ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria lati ibikan lọ si ibomii.

Awọn ti ọrọ naa kan lawọn ọgagun ti wọn wa nipo ọgagun onirawọ meji (Major General) ati ọgagun onirawọ kan (Brigadier General).

Lagbẹ igbesẹ tuntun yii, wọn ti kede ọgagun IA Ajose gẹgẹ bii adari ikọ Joint Task Force (JTF), iyẹn Operation HADIN KAI (OPHK) to n koju awọn Boko Haram ni ariwa Naijiria.

Ileeṣẹ ọmọ ogun sọ pe igbesẹ naa n waye lọna ati ro awọn ọmọ ogun lagbara ni Naijiria.

Ọgagun AE Abubakar, to n ṣiṣẹ ni OPHK ni wọn ti gbe lọ si ile ẹkọ Nigerian Army Heritage and Future Centre (NAHFC) gẹgẹ bii ọkan lara awọn adari ile ẹkọ naa.

Wọn ti gbe ọgagun AM Alechenu kuro ni olu ileeṣẹ ọmọ ogun DHQ, lọ si NAHFC, nigba ti ọgagun RT Utasaha ti lọ si ibomii.

Lati ọọfisi olubadamọran si Aarẹ lori eto aabo ni wọn ti gbe ọgagun GS Muhammed lọ si ọọfisi to n ri si eto iṣuna ileeṣẹ ọmọ ogun, iyẹn Nigerian Army Finance Corporation (NAFIC), gẹgẹ bii oluṣakoso rẹ.

Ki ni eredi igbesẹ yii?

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria gbe jade, eyi ti agbẹnusọ rẹ, Apollonia Anele fi lede, o ni igbesẹ ọhun waye lati mu ki iṣẹ awọn ologun gbooro si.

O ṣalaye pe igbesẹ naa yoo jẹ ki wọn fi awọn to yẹ fun ẹka kọọkan o le wa lawọn aye to yẹ ki wọn wa kaakiri ẹka ileeṣẹ ọmọogun Naijiria.

Anele sọ siwaju sii pe, yoo tun ran ajọṣepọ laarin oniruru awọn olori ati ẹka ileeṣẹ naa lọwọ lati ṣiṣẹ papọ.

Ọga agba ileeṣẹ ọhun wa rọ gbogbo awọn ti wọn ṣẹṣe pin kaakiri ki wọn maṣẹ ja ileeṣẹ ọhun kulẹ ni gbogbo ẹka tuntun ti wọn gbe wọn lọ.

O fi kun pe ki wọn maṣe sọ afojusun wọn nu ki wọn si tẹle ofin ninu igbiyanju wọn lati daabo bo Naijiria, eyii to jẹ ojuṣe wọn.

Ileeṣẹ ọmọ ougun ni oun ko ni yẹsẹ ninu afojusun oun lati ri daju pe awọn to dantọ lo wa ni oniruru ẹka ileeṣẹ naa fun anfani ati aabo gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ.