APC fagilé ẹjọ́ tí wọ́n pè tako èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ́ Osun tó gbé Adeleke wọlé fún sáà kejì

Ademola Adeleke wọ agbada funfun pẹlu fila, Bola Oyebamiji wọ buba funfun pẹlu fila pupa

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X/Bola Oyebamiji/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbẹjọro Seyi Oyagbile to pe ẹjọ tako esi idibo Gomina ipinle Osun eyi to gbe Ademola Adeleke wọlé fún sáà keji ti fagilé ẹjọ́ naa.

Amofin Oyagbile pe ẹjọ naa lọjọ kẹjọ oṣù Kẹsán an yii lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ati lorukọ oludije ẹgbẹ naa, Bola Oyebamiji.

Iwe ẹjọ naa ni a gbọ pé wọn lẹ mọ ara patako ni ọọfiisi igbimọ igbẹjọ to ba jẹyọ ninu eto idibo to wa niluu Osogbo, tii olu ilu ipinlẹ Osun.

Iwe ipẹjọ naa eyi ti akọwe igbimọ igbẹjọ, Belemo Diete-Spiff, buwọ́lù ni nọmba EPT/Osu/Gov/01/2026, ohun si ni ẹjọ ti Asiwaju Oyebamiji ati ẹgbẹ oṣelu APC pe Gómìnà Adeleke ti ẹgbẹ Accord àti àjọ eleto idibo INEC lori esi idibo Gomina ipinlẹ Osun to waye lọjọ kẹẹdogun oṣù kẹjọ to kọja.

Nọmba to wa lara iwe ipẹjọ keji ni EPT/Os/Gov/02/2026, eyi ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe tako esi idibo Gomina ipinlẹ Osun bakan naa.

Amọ, amofin to pe ẹjọ loruko APC ati oludije rẹ ti wogile ẹjọ naa bayii.

Ẹwẹ, amofin Oyagbile to pe ẹjọ naa sọ fún ìwé iroyin Punch wi pe lóòótọ́ loun ti fagilé ẹjọ́ ọhun.

Ti ẹ o bá gbagbe, igbimọ to n ri si ọrọ òfin ninu ẹgbẹ APC ti sọ ṣaaju tẹlẹ wi awọn o mọ ohun kohun nipa ẹjọ naa.

Amofin agba Adekunle Adegoke, SAN fidi rẹ múlẹ pe ko si ẹni to pe ẹjọ tako esi idibo Gomina ipinle Osun lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Adegoke ni igbimọ to n ri si ọrọ ofin ninu APC sepade pọ pẹlú Oyebamiji at'awọn àgbààgbà lẹyìn tí esi idibo naa jade.

Agbẹjọro naa ni ohun tawon fẹnu ko le lori ni wi pe APC ko ni pejọ tako esi idibo ọhun.

O ni ẹgbẹ oṣelu APC gbe ìgbésẹ yii ki alaafia ba le jọba ní ìpínlẹ̀ Osun latari gbogbo rogbodiyan to ti ṣẹlẹ ṣaaju eto idibo.