Àṣírí ibi tí wọ́n ti n ṣe ayédèrú owó Euro tú n'ibadan, àwọn afurasí há

Ayederu owo, foonu, kaadi idanimọ ati awọn irinṣẹ ti wọn fi n ṣe ayederu owo jae, eyi ti ọlọpaa gba lo wa lori tabili, to fi mọ awọn tọwọ tẹ layika

Oríṣun àwòrán, Ayanlade Olayinka Ppro Oyo State Police Command/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe awọn ti ṣawari ibudo kan ti wọn ti n ṣe ayederu owo ile okeere ti a mọ si Euro.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni ọlọpaa sọ pe ọwọ tẹ awọn afurasi mẹta lori ọkada, lagbegbe Labo-Wesley niluu Ibadan.

Ẹgbẹrun mẹjọ ati ẹẹdẹgbẹrun owo Euro ti gbogbo rẹ ayederu ni ọlọpaa sọ pe awọn gba lọwọ awọn afurasi naa.

"Ayẹwo ti wọn ṣe lo tu aṣiri bi wọn ṣe ri ayederu owo mọkandinlaadọrun to jẹ ọgọrun kọọkan 'Euro', ti apapọ rẹ si jẹ Ẹgbẹrun mẹjọ ati ẹẹdẹgbẹrun Euro"

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, Olayinka Ayanlade fi sita fawọn akọroyin, o ni nnkan bi agogo meje aabọ irọlẹ ọjọ naa lọwọ palaba wọn segi.

"Lọjọ kinni, oṣi Kẹsan, ọdun 2026, ni nnkan bi agogo meje aabọ irọlẹ, awọn agbofinro ti wọn n ṣiṣẹ aabo kọja lọ lagbegbe Labo-Wesley da awọn ọkunrin mẹta kan to n rin irin-ajo lori ọkada duro," Ayalade sọ bẹẹ ninu atẹjade.

O sọ pe, "Ayẹwo ti wọn ṣe fun awọn wọnyi lo tu aṣiri bi wọn ṣe ri ayederu owo mọkandinlaadọrun ti jẹ ọgọrun kọọkan owo ilẹ okeere 'Euro', ti apapọ rẹ si jẹ Ẹgbẹrun mẹjọ ati ẹẹdẹgbẹrun owo Euro."

Hammed Karemu, ẹni ọdun marundinlọgbọn to jẹ ọlọkada; Tijani Saheed, ẹni aadọta ọdun to gbe owo naa dani, ati Adebayo Saheed, ẹni ọdun mejilelaadọta toun naa wa lori ọkada pẹlu ni awọn mẹẹta ti ọwọ tẹ, gẹgẹ bi agbẹnusọ ṣe ṣalaye.

Ayanlade sọ siwaju pe iwadii ati ọrọ ti wọn fi wa awọn afurasi naa lẹnu wo, lo jẹ ki wọn jẹwọ pe Oni Oladapo, ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin lo n tẹ owo naa jade fun wọn.

O ni ifọrọwerọ ti wọn ṣe fun awọn afurasi naa lo sọ iru iwadii ti ọlọpaa ṣe, ko to di pe ọwọ tẹ awọn yooku, leyi to fi jẹ pe afurasi mẹfa lọwọ tẹ.

Ayanlade sọ pe awọn afurasi naa jẹwọ fun ọlọpaa, ko to di pe wọn lewaju wọn lọ sibi ti ọwọ ti tẹ awọn afurasi yooku, to fi mọ awọn irinṣẹ ti wọn n lo.

"Gbogbo àwọn afurasí ni yóò fojú ba ilé-ẹjọ́"

Siwaju sii lo sọ pe gbogbo awọn afurasi mẹfa ọhun lo ti wa lahaamọ awọn bayii, nibi ti wọn ti n ṣe iwadii wọn siwaju sii, ko to di pe wọn foju wọn bai le-ẹjọ labẹ ofin.

O fi kun ọrọ rẹ pe, ko si nnkan ti yoo sọ pe ki waọn afurasi naa ma lọ kawọ pọyin rojọ niwaju ile-ẹjọ, nigba ti iwadii ba tubọ pari.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Abimbola Ayodeji Olugbenga ti wag be oṣuba kare fun iṣẹ ti awọn ọlọpaa naa ṣe lati rii pe awọn afurasi ọhun ha.

Olugbenga fi ọkan awọn araalu balẹ wi pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa gbogun ti awọn ọdaran laaarin ilu, lojuna lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan, ati ilọsiwaju eto ọrọ aje.