Àlàyé rèé lórí bí a ṣe ṣàwárí, dóòlà àwọn tí ajínigbé gbé ní Oriire, ọ̀nà táwọn èèyàn mẹ́sàn-án gbà kú àti ọ̀pọ̀ òfegè ìròyìn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà - Ọ̀gá DSS

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS nigba to n sọrọ pẹlu ẹrọ gbohungbohun igbalode to gbe kọ ori rẹ, ati awọn ti awọn ajinigbe jigbe nipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Akinteye Babatunde/Facebook Bayo Onanuga/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọga agba pata fun ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lorileede Naijiria, Adeola Oluwatosin Ajayi ti sọ pe awọn ti ko din ni mẹsan ni wọn padanu ẹmi wọn lasiko igbiyanju lati doola awọn ti wọn jigbe nipinlẹ Oyo.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2026 ni awọn janduku agbebọn ṣe ikọlu si awọn ile-ẹkọ mẹta to wa niluu Ahoro-Esinele, ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo, pẹlu awọn nnkan ija oloro.

Awọn ti ko din ni mẹrindinlaadọta, olukọ meje ati akẹkọọ mọkandinlogoji ni awọn janduku agbebọn naa jigbe wọnu igbo lọ.

"Ọlọ́dẹ kan àti ọlọ́pàá kan kú"

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, Ajayi fidi rẹ mulẹ pe gbara ti awọn ti gbọ nipa ijinigbe ọhun, ni ileeṣẹ wọn ti bẹrẹ iṣẹ ofintoto lati mọ ibi ti awọn ajinigbe naa wa.

O ni o ṣeni laanu wi pe ọlọdẹ kan ati ọlọpaa kan ku soju ogun, lasiko ijakadi lati gba awọn akẹkọọ ati olukọ to wa lahaamọ silẹ.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, yatọ si awọn to ku, ọpọ awọn oṣiṣẹ aabo ati araalu lo farapa lasiko ijakadi ọhun lati koju awọn ajinigbe naa.

"Ni kete ti iṣẹlẹ naa waye, lori olobo to tẹ wa lọwọ, awọn ọmọ ogun dide lati tẹlẹ wọn loju ẹsẹ, o si ṣeni laanu pe wọn pa fijilante kan ati ọlọpaa kan," Ajayi kọminu.

O tẹsiwaju pe, "Nigba ti awọn yoo pada lọ lẹẹkeji, ọpọ eeyan ni wọn tun pa, to si jẹ awọn mẹsan ni wọn ba iṣẹlẹ ọhun lọ, araalu mẹrin ati eleto aabo marun-un."

"Ọmọ ọdún méjì ààbọ̀ tí kò lè sáré wà níbẹ̀"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọga DSS naa ṣapejuwe igbiyanju lati doola awọn ti wọn jigbe naa jẹ eyi to gba ọgbọn gidi, nitori pe awọn ti wọn jigbe naa, to fi mọ ọmọ ọdun meji aabọ ti ko le sare du ẹmi ara rẹ wa nibẹ.

"Iṣẹ ti a ṣe gba ọgbọn ati ifarabalẹ, nitori pe ọmọ ọdun meji aabọ ti ko le sare pupọ wa nibẹ, ti a ba pinnu lati kọlu wọn lojiji," o ṣalaye.

Ajayi wa kọminu lori awọn iroyin ẹlẹjẹ ati agbelẹrọ to ti n lọ kaakiri ori ayelujara lasiko ti awọn n ṣiṣẹ itusilẹ naa.

O ni awọn fọnran agbelẹrọ kan to ṣafihan ibi ti wọn ti n lu awọn ọmọde lasiko naa, jẹ eyi to ṣẹlẹ lorileede kan lọdun to ti pẹ sẹyin, ti ko si ni ohunkohun lati ṣe pẹlu iṣẹ wọn nipinlẹ Oyo.

"Gẹgẹ bi awa naa ti ṣe n reti, isẹ wa nipa gbigba awọn eeyaan naa silẹ lo jẹ eyi ti wọn n gbe oniruuru ayederu iroyin kaakiri ori ayelujara. A ni lati fi awọn iroyin kan pamọ nibẹ," alakoso DSS fidi rẹ mulẹ.

O wa fi kun ọrọ rẹ pe, "Nigba ti awọn n ṣiṣẹ lọwọ, ọpọlọpọ fọnran agbelẹrọ nibi ti wọn ti n lu awọn ọmọde pẹlu awọn apa lara wọn ni wọn n gbe kiri ori ayelujara.

"Eyi lo si jẹ pe orileede kan lo ti ṣẹlẹ, nibi ti wọn ti fẹsun ajẹ ati oṣo kan wọn, ti iṣẹlẹ naa si ti pẹ."

O wa rọ awọn ileeṣẹ iroyin lati maa wa okodoro ko to di pe wọn gbe iroyin wọn jade sita, paapaa lasiko ti ipenija ba n wa niluu, lati le jẹ ki araalu mọ otitọ.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Awọn agbebọn ti kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn naa pa olukọ kan, ji olori ile ẹkọ pẹlu awọn akẹkọọ ti ẹnikẹni ko ti i le fi iye wọn mulẹ lọ nibi ikọlu naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti naa, o ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ yii ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ.

Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de bo ṣe wi.

Bi wọn ṣe de ni wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.

Ninu ikọlu naa ni wọn ti yinbọn fun olukọ kan, ẹni ti iroyin sọ pe o ti jade laye, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ko fidi eyi mulẹ.

"Awọn agbebọn ti wọ agbegbe Ahoro-Esinele, nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo. Wọn gbe ọga ile ẹkọ ati awọn akẹkọọ ti a ko mọ iye won lọ"

Bẹẹ ni atẹjade ọlọpaa wi.

Lasiko naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo sọ pe oun ti ri awọn fidio kan to ṣafihan awọn eeyan kan to wa lara awọn tawọn janduku agbebọn ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire niluu Ogbomoso lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fi sita ni o ti ṣalaye wi pe, ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri pe awọn doola gbogbo awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ ile ẹkọ ti wọn ji gbe lọ ni Esinele ati Yawota ni ijọba ibilẹ Oriire.

Olayinka sọ pe gbogbo awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa ni yoo foju wina ofin.

O tun fi da gbogbo ẹbi awọn eeyan to wa lakata awọn ajinigbe wi pe gbogbo wọn ni yoo pada wale lọ ba ẹbi wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati ma foya, amọ, ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu ọlọpaa bi akitiyan ṣe n lọ lọwọ lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ naa.

Olayinka tun rọ awọn araalu to ba mọ ohunkohun nipa ibi tawon ajinigbe ko awọn eeyan naa si wi pe ki wọn fi to ọlọpaa leti.

Bakan naa tun ni ileeṣẹ ọlọpaa tun rọ araalu wi pe ki wọn ye gbe iroyin ti ko ba lẹsẹ nlẹ eyi to le da ibẹru bojo silẹ.

Amọ idunnu subu lu ayọ lọjọ Kẹwaa osu Keje ọdun 2026 nigba ti iroyin gbalẹ kan pe awọn eeyan mẹrinlelogoji ninu awọn ti ajinigbe ko ni Oriire ti gba idande.

Ọjọ mẹrindinlọgọta si ni wọn lo ninu igbo Old Oyo National Park ki idande to de ba wọn.