Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn èèyàn kan wà tí wọn kò ní ilà ọwọ́? Ohun tó fà á ree

Ika ọwọ mẹjọ ati ọmọbinrin kan ti wọn aṣọ pupa ti o si fi ipele ofi kọrun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Nigba ti Hauwa Jidda Suleiman fẹ forukọ silẹ fun idanwo Jamb ni o kọkọ mọ pe oun ko ni ila ọwọ.

Lasiko naa ni ẹrọ to maa n ka ila ọwọ silẹ ko ri ila ọwọ Hauwa.

Lọrọ kan, nnkan ti wọn maa n pe ni adermatoglyphia ni Hauwa ni, eyi to tumọ si ki wọn bi eeyan lai ni ila yala lori ika ọwọ, ẹsẹ, atẹlẹwọ tabi ni atẹlẹsẹ.

Ọpọ ni kii saba sọ nipa ila ọwọ, amọ, nnkan to n kọ Hauwa lominu ni ọwọ yii tori nnkan ti o ṣalaini rẹ ni a n sọ nipa rẹ yii.

''Wọn maa n saba ro pe mi o fẹ tẹka ni''

Lara ipenija ti Hauwa n koju ni pe ọpọ ni ko mọ pe o ṣee ṣe ki wọn bi eeyan ki o si ma ni ila ika ọwọ.

''Ọpọ eeyan lo maa n da a si ibinu lẹyin ti wọn ba ri i pe ẹrọ ti wọn maa n fi tẹka ko ri ila ika ọwọ mi.

O maa n dabi ẹni pe emi ni mi o fẹ tẹka, amọ, kii ṣe ẹbi wọn ṣa.

Wọn ko tii ri iru eeyan bayẹn ri tẹlẹ ni.

Wọn maa n ya mi sọtọ lara awọn eeyan mii, mo le da jokoo sibi ti wọn ba fi mi si nigba mii fun ọpọ wakati.

Nigba mii, awọn to n ṣe idanwo ti le maa ba idanwo lọ ti emi si maa wa lori ijokoo,'' Hauwa lo sọ bẹẹ.

Hauwa ni idanwo Jamb kan tiẹ wa toun ko lanfaani lati kopa ninu rẹ rara.

Ki lo le mu ki eeyan ma ni ila ọwọ tabi tẹsẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aini ila ika ọwọ tabi tẹsẹ ti oloyinbo n pe ni adermatoglyphia jẹ nnkan to le ṣẹlẹ si ọwọ tabi ẹsẹ eeyan to jẹ nnkan ajẹbi, amọ, iru rẹ ko wọpọ rara.

Nigba ti wọn ba ti bi ọmọ ikoko lo ti maa n ni ila ika ọwọ tabi tẹsẹ to fi mọ atẹlẹsẹ.

Lati igba ti oyun ba ti wa ni oṣu mẹta lawọn ila yii ti maa n wa ni ọwọ ati ẹsẹ, ila yii ti maa n wa nibẹ daadaa ti oyun ba ti di oṣu mẹfa.

Awọn ila yii si maa n wa nibẹ titi laelae lati igba ti oyun ba ti pe oṣu mẹfa.

Awọn eeyan bi Hauwa ko ni ila ọwọ ati tẹsẹ yii rara ni, kii ṣe wi pe o parẹ.

Awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi nipa eto ilera fi idi rẹ mulẹ pe awọn ẹbi perete ni wọn maa n ni iru iṣoro yii lagbaaye.

Iwadii kan ti wọn ṣe lọdun 2011 fidi rẹ mulẹ pe ẹbi mẹrin lo fẹẹ ni iru iṣoro yii kaakiri agbaye.

Nitori bi ko ṣe wọpọ yii ni ko ṣe jẹ ki ọpọ eeyan ti ọrọ Hauwa maa n ya lẹnu tii gbọ nipa rẹ.

Nigba ti Hauwa naa sọ iriri rẹ lori itakun ayelujara ni o to mọ pe oun nikan kọ lo ni iru ipenija yii.

Hauwa sọ pe ''lẹyin ti mo fi ọrọ naa lede lori itakun ayelujara ni eeyan bii ọgọrun un sọ pe awọn naa n koju iru iṣoro yii.''

Akoba ti aini ila ọwọ le ṣe fun eeyan

Ọrọ Hauwa jade lẹyin ti BBC gbe iroyin kan jade nipa Ovey Friday, akẹkọọ kan to kudiẹ ko padanu ati wọle sile ẹkọ giga fasiti tori o fi ọwọ sẹṣe.

Friday ko lọwọ kan, o si tun fọwọ keji ṣeṣe lẹyin ti wọn fiya jẹ ẹ nigba to wa ni kekere.

Ẹrọ atẹka ko ri ọwọ rẹ nigba to fẹ forukọ silẹ fun idanwo Jamb atiwọle si fasiti.

Lẹyin o rẹyin ni wọn pada gba wi pe ki Friday lo ẹsẹ rẹ lati tẹka dipo ọwọ.

Iṣoro Hauwa ati Friday yatọ sira, Friday fọwọ ṣeṣe nigba to wa ni kekere, wọn ko tiẹ bi Hauwa mọ ika ọwọ rara ni.

Amọ, iru ipenija kan naa lawọn mejeji jọ ni nipa bi wọn ko ṣe lee tẹka fun iforukọsilẹ lati ṣe idanwo.

Njẹ eeyan le gba itọju lori aini ila ọwọ tabi tẹsẹ?

Fun awọn eeyan ti wọn bi lai ni ika ọwọ, ko tii si itọju tawọn eleto ilera le fun wọn bayii.

Idi ni wi pe lati igba ti eeyan ba ti wa ninu oyun ni o ti maa n ni ila ọwọ ati tẹsẹ yii.

Amọ, aisi itọju fun iṣoro yii ku tumọ si pe ko ni si ọna abayọ si iṣoro tawọn eeyan bi Hauwa n koju yii.

Hauwa n gbero lati ṣagbekalẹ ajọ kan ti yoo wa ọna eyi ti yoo maa fawọn eeyan bi tiẹ ni anfaani lati le maa tẹka ni ọna mii yatọ si ọna ti gbogbo eeyan n lo.

Bi Hauwa naa ṣe n wo ara rẹ tẹlẹ ti yatọ, lẹyin to ti ri awọn eeyan mii tawọn naa ko ni ila ọwọ bi tiẹ.

O maa n ro pe oun nikan loun ni iru iṣoro yii tẹlẹ ni.