MMM gbọ̀nà míì yọ ní Osogbo; iléeṣẹ́ kan fi àpò ìrẹsì, òróró àti sẹ̀mó lu aráàlú ní jìbìtì

Ṣọọnu ti apo irẹsi ati ẹwa wa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ eeyan ti ko sinu niluu Osogbo, nipinlẹ Osun lẹyin ti ileeṣẹ kan to ni oun n ta irẹsi, sẹmo ati ororo ni owo perete lu wọn ni jibiti.‎

Awọn eeyan naa ti sọ fun BBC pe ọwọngogo ounjẹ to gbode ati bi nnkan ṣe gbowo lori lo faa ti awọn fi ko sọwọ awọn onijibit naa.

BBC Yoruba lọ siluu Osogbo nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, ohun ti a gbọ ninu iwadi wa ni pe, ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Food Global Initiative to wọ ilu lọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an ọdun yii lo ṣọṣẹ naa.

‎A gbọ pe ileeṣẹ naa sọ fun awọn eeyan naa pe awọn wọ ilu lati ran wọn lọwọ lori ọrọ ounjẹ bii irẹsi, ororo, sẹmo ati bẹẹbẹẹ lọ.

Bo tilẹ jẹ pe gbogbo awọn ounjẹ naa lo ti wọn, Food Global Initiative sọ pe awọn yoo maa ta awọn ounjẹ ọhun fun awọn eeyan ni owo kereje.

‎Agbegbe Odi-Olowo niluu Osogbo ni wọn gba ọọfisi si ti wọn si bẹrẹ si n ja ìrẹsì, ororo, Sẹmo ati bẹbẹ lọ sinu ọọfisi wọn.

Ọpọ eeyan ti ra ìrẹsì, ororo ati sẹmo lọwọ ileeiṣẹ naa ni owo kekere ti ọpọ si ti gba ohun ti wọn san owo fun ko to di ọjọ Aje, ọjọ kejidinlogbon, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 yii ti ileeṣẹ naa gbe agadagodo si ẹnu ọna rẹ to si ko owo ọpọ eeyan lọ.

APo irẹsi ti wọn n ta ni ₦27,000 lo mu mi ko sọwọ wọn

Ọkan ninu awọn to padanu owo wọn sinu jibiti naa, Oni Babatunde, ẹni ti oun naa fara gba ninu iṣẹlẹ naa ṣalaye bi isu ṣe ku bi ọbẹ ṣe bẹ.

‎Babatunde sọ pe ileeṣẹ naa ni oun n ta apo ìrẹsì kan ni ₦27,000 ti galọọnu ororo kan si jẹ ₦30,000.

‎O ṣalaye pe eyii lọ mu ki oun lọ kowo le ti oun si kọkọ ra apo ìrẹsì kan ni ₦27,000.

Babatunde sọ pe oun tun gba owo gbọmu le lanta ati lọwọ ẹgbọn oun kan lati ra ọpọlọpọ ounjẹ naa sile.

‎Amọ iyalẹnu lo jẹ pe pe lojiji ni ileeṣẹ naa ko igba ati agbọ rẹ to si salọ pẹlu owo awọn to ti san owo fun ṣaaju.

Ọpọ ero to kowo sibẹ to n reti ounjẹ padanu owo wọn
Àkọlé àwòrán, Ọpọ ero to kowo sibẹ to n reti ounjẹ padanu owo wọn

"Owo ile ẹkọ awọn ọmọ mi, ati owo awọn ọrẹ mi ni mo ko lọ sibẹ"

Ẹlomii to padanu obititi owo sọwọ awọn eeyan naa, Mudeen Aminat sọ fun BBC pe to ba jẹ pe Naijiria ko ti bajẹ bayii ni ko si oun to fẹ mu oun lọ sibi sogundogoji ọhun rara.

‎Aminat ni "Otitọ ni pe mo gba apo ìrẹsì kan ti mo san owo fun nigb ti wọn kọkọ bẹrẹ.

‎"Eleyi lo mu mi lọ sọ fun awọn ọrẹ mi ti mo tun lọ fi gba owo ele ni ọdọ awọn ayanilowo lati ra ounjẹ pupọ sile.

‎"Ṣugbọn mi o mọ pe awọn alagbeda ni ileeṣẹ naa.

Wọn gba owo lọwọ mi, wọn tun ko owo t imo gba lọwọ awọn ọrẹ mi, eyii ti mo ko lọ sibẹ.

"‎Ọrọ yii ti da arin emi ati ọkọ mi ru bayii, nitori ọkọ mi ko fọwọsi ṣugbọn mo fẹ ṣe gẹgẹ bi oluranlọwọ fun ọkọ mi ni.

‎"Owo ile ẹkọ awọn ọmọ mi ta ko tii san mo ko lọ sibẹ pẹlu ero pe bi ebi ba kuro ninu isẹ, iṣẹ ti buṣe ni mo ṣe fẹ ṣe ọrọ naa lati fi ran ọkọ mi lọwọ."

Agadagodo niwaju ileeṣẹ naa
Àkọlé àwòrán, Agadagodo ti wọn fi ti ọọfisi ileeṣẹ naa

Ẹnikẹnikẹni ko fi ọrọ naa to wa leti - Ọlọpaa

‎‎Alukoro fun ile-iṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ọsun, Abiodun Ojelabi ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

‎Abiodun sọ pe awọn ko gbọ ohun kankan tẹlẹ ko to di pe ọrọ yii di wahala.

‎O ni kete ti awọn gbọ ni awọn ti da awọn Ọlọpaa sibi ti awọn ileeṣẹ naa gba ọfisi si ti awọn si ti ibẹ pa lati akoko ti awọn ti gbọ iṣẹlẹ naa.

‎Alukoro ọlọpaa naa ni awọn ti sọ fun awọn ti ọrọ naa kan pe ki wọn wa si agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn lati ṣalaye bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ, ṣugbọn titi di asiko yii awọn ko ti ri ẹnikankan ko yọjú si awọn.

‎Abiodun wa rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan lati fun ọlọpaa laye fun iwadii lori ọrọ naa ati pe awọn ko fẹ ki ẹnikẹni ṣe idajọ lọwọ ara rẹ nitori iwadi ti bẹrẹ ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun.