"O ti tẹ́ lálẹ́ yìí, màá tọrọ ìdáríjì tó bá yá!" Ṣé lóòótọ́ ni olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun ń gbé aráàlú kan ṣépè lóríi fóònù?

Aworan olori ile aṣofin ipinlẹ Ọṣun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹnu ti bẹrẹ si n kun agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Osun, Adewale Egbedun, bayii lẹyin ohun rẹ to lu jade lori ayleujara nibi to ti n ṣe epe rabata fun ọkunrin kan ti a gbọ pe o jẹ ọkan lara awọn olugbe ilu Odo-Otin.

Ninu ohun naa ti wọn ka silẹ laarin agbẹnusọ ọhun ati ọkunrun ti a gbọ pe orukẹ rẹ n jẹ Taofeek ni Egbedun ti n wọn epe fun ọkunrin naa.

Egbedun fẹsun kan ọkunrin naa pe o n dunkoko mọ oun lẹyin to fi atẹjiṣẹ kan ṣọwọ si lori awọn iwa kan to n wu.

Lasiko to n sọrọ nipa ohun ti ọkunron naa ṣe, Egbedun ka diẹ lara atẹjiṣẹ ti Taofeek fi ṣọwọ si, eyii ti ko tẹ lọrun.

Lori ipe naa to tẹ BBC Yoruba lọwọ ni a ti gbọ ohun ọkunrin mii to wa pẹlu Egbedun to si n fi ata ati iyọ si ọrọ naa amọ a ko le sọ irufẹ ẹni ti ọkunrin keji yii jẹ.

KI ni Taofek sọ si Egbedun to da gbas-gbos naa silẹ?

Bo tilẹ jẹ pe a ko le sọ ni pato awọn ohun to ti waye ṣaaju laarin awọn mejeji, ohun ti Taofeek fi ranṣẹ si Egbedun gẹgẹ bi oun funra rẹ ṣe sọ ree.

"Ẹ kaalẹ o, agbẹnusọ, lakọkọ, o le ya yin lẹnu pe mo fi ọrọ ranṣẹ si yin, amọ awọn nnkankan wa ti mọ fẹ sọ fun yin.

"Ni ikorita ti a wa yii, ko yẹ ki ẹ maa fun wa laaye lati maa wọ yin nilẹ tututu, nitori ọpọ eeyan lo wa lẹyin yin. Gẹgẹ bii ero temi."

Ki ni esi Egbedun si atẹjiṣẹ naa?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba ti Egbedun yoo fesi, niṣe lo tu itọ soke to si fi oju gba a toun ti epe.

O ni "Taofeek, ṣe iwọ lo send DM si mi ti o n dunkoko mọ mi?

"Ah, emi lo pe! Emi lo n fi ọrọ ranṣẹ si pe o fẹ wọ mi nilẹ turutu. O o ni ṣe oriire mọ laye, o o ni ri alaanu mọ laye.

"Waa maa ba araye fọwọ tii ni, ti o ba tun ṣe oriire, pe Egbedun ni ọmọ ale, wo o, mo maa dunkoko mọ ẹ to jẹ pe oo tun ṣe oriire mọ.

"Jẹ ki n kilọ fun ẹ, mi o fẹ ri ẹ ni Odo-Otun mọ... ti mo ba ti ri ẹ, waa mọ ẹni ti wọn n pe ni Egbedun, eyii ti o ti ṣe lalẹ yii o ti ṣe ori buruku.

"Oriire ti mo ti ṣe laye yii, iran yin kankan o ṣe e ri. Darukọ iran ẹ kankan to lorukọ ri."

Egbedun sọ oniruru ọrọ aiọkunrin naa, koda , o tun mẹnuba ẹnikan to n jẹ Alasi to sọ pe oun ti da seria fun ṣaaju, ti oun yoo tun ṣe irufẹ nnnkan bẹẹ fun Taofeek naa.

Lẹyin naa lo sọ fun Taofeek ọhun pe oun ko kọ to ba gbe ọrọ oun lọ sori Facebook, oun ko kọ ki Taofeek ọhun lọ maa sọrọ fun gbogbo agbaye lori ayelujara.

Wayi o, BBC Yoruba ti kan si Egbedun lori ọrọ naa ati oniruru ọrọ kobakungbe to sọ si ọgbẹni Taofeek lori aago amọ o kọ lati fesi si wa, bẹẹ naa ni ko sọ nnkankan nipa ọrọ ọhun loju opo ayelujara rẹ.

Ẹwẹ, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede nipa ọrọ naa, paapaa ọrọ ti Egbedun sọ si ọkunrin naa.

Ẹni ogoji ọdun ni Egbedun, ọdun 2023 lo si wọle sile aṣofin ipinlẹ Osun.