Nàìjíríà kéde orúkọ àwọn ọmọ Naìjíríà mẹ́ta tí wọ́n tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣekúpa ní South Africa, pè fún ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orilẹede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu iku awọn ọmọ orilẹede Naijiria mẹta kan ni South Africa laarin ọjọ mẹrin, pẹlu bi ajọṣepọ laarin orilẹede mejeeji yii ṣe n mẹhẹ si i laarin igbogun ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni South Africa.
Ileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria ni ilu Johannesburg ṣalaye pe iku awọn ọmọ Naijiria mẹta naa laarin ọjọ kejidinlogun si ikọkanlelogun ti n mu ọpọlọpọ ariwisi dani lori ohun ti ọpọ n woye rẹ gẹgẹbi gbọnmọgbọnmọ ikọlu awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni orilẹede South Africa.
O ke si awọn alaṣẹ orilẹede South Africa lati ṣe iwadii awọn iṣẹlẹ naa ki wọn si fi awọn tọwọ ofin ba tẹ jofin.
Ijọba Naijiria kede orukọ awọn ti wọn tun ṣẹṣẹ ṣekupa ni South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria ṣalaye fun BBC lọjọ Iṣẹgun pe ni idajọ ododo loun n beere fun lorukọ awọn ọmọ Naijiria ti ọrọ naa kan.
Alukoro ileeṣẹ ọrọ ilẹ okeere, Femi Adeniyi pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to bani lọkan jẹ pupọ ju.
Ọkan lara awọn to ku naa, Kenechukwu Christopher Igwemmadu ku lasiko to fi fo bọ silẹ lati inu ile kan ni agbegbe Bloemfontein lasiko to n gbiyanju lati sa bọ lọwọ awọn ọlọpaa to n dukuku mọọ.
Ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Naijiria lorilẹede South Africa tun ṣalaye siwaju sii pe ọmọ Naijiria miran, Ọlaniyi Ọlalẹyẹ Ọlatunde ku lẹyin ti wọn yibọn fun un lasiko ti ariyanjiyan waye ni ile ijo kan ni Pretoria nibi to ti n ṣiṣẹ gẹgẹbi ẹṣọ alaabo. Wọn ni ẹni to yinbọn pa arakunrin naa ti kọkọ sare kuro lagbegbe naa ki o to di pe o tun pada wa halẹ mọ awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn pe bi wọn ba sọ ohunkohun fun awọn agbofinro.
Ẹnikẹta ti orukọ rẹ n jẹ Christian Hillary Nnaemeka ni wọn sọ pe o ku lẹyin ti o forigbori pẹlu ikọ kan ti oloṣelu kan lorilẹede naa ti orukọ rẹ n jẹ Xolani Khumalo. Wọn ni wọn fiyajẹ Nnaemeka ki o to di pe o daku nigba to n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi rẹ

























