Àwọn agbébọn wo làwọn ọmọ ogun ń bá ṣèpàdé nínú igbó ní Kwara?

Awọn ọmọ ogun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria ti sọrọ lori fidio to n kaakiri ori ayelujara, eyi to ṣafihan ibi ti awọn ọmọ ogun ti n ṣe ipade papọ pẹlu awọna furasi agbebọn ninu igbo.

Latigba ti fidio mejeeji naa ti wọ ori ayelujara, ni oniruuru ijiroro ti n waye, paapaa lori awọn ikanni ayelujara.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe nnkan ti awọn ọmọ naa ṣe ku diẹ kaato, awọn miran n sọ pe ọna lati koju ogun ni.

Ṣugbọn ṣa, eyi lo jẹ ki ileeṣẹ ologun Naijiria sọrọ lori fidio naa, lati le jẹ ki gbogbo araalu mọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.

Kí ló wà níní fídí

Ninu fidio oniṣeju kan naa ti wọn ya ninu igbo, ni a ti ri awọn ọmọ ogun to n rin ninu igbo kijikiji, nibi ti ipade naa ti waye.

Kete ti wọn ti de ibi ipade naa, ni a ti ri awọn oṣiṣẹ eleto aabo lati ileeṣẹ ologun ati ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn gbe ibọn dani, ti awọn agbebọn naa si gbe ibọn tiwọn naa dani.

Awọn igun mejeeji ni wọn n ki ara wọn pade ara wọn ninu igbo, ti wọn si n sọrọ lori ibọn ti onikaluku wọn gbe dani.

A gbọ ohun kan ninu fidio naa, to sọ pe, "Ẹ jẹ ka daabo bo ara wa, nipa Ọlọrun, Oun ni arakunrin wa."

A tun ri ọkunrin kan to wọ aṣọ ibilẹ, to si dabi ọmọọba.

Oniruuru ọrọ ijiroro lo lọ laaarin igun mejeeji, leyi ti ọkan lara wọn sọ pe, "Ẹ dan an wo ki ẹ si ri, ni kete ti ẹ ba dan an wo, wọn yoo mọ pe awọn ọjọọla ologun ṣi wa."

Báwo ni fídíò náà ṣe di awuyewuye?

Latigba ti fidio naa ti jade sori ayelujara, ni oniruuru ibeere ti n jẹyọ nipa idi ti awọn ọmọ ogun ṣe lọ sinu igbo lati ṣepade naa, ati paapaa ohun ti wọn ba awọn agbebọn sọ.

Awọn kan tilẹ fẹsun kan awọn ọmọ ogun naa wi pe wọn mọ ibi ti awọn agbebọn naa wa, ṣugbọn ti wọn kọ lati ṣekupa gbogbo wọn.

Ọpọ ijiroro lo ti waye nipa fidio ọhun.

Awọn kan tun sọ pe awọn ọmọ ogun mọ nipa awọn agbebọn to doju eto aabo orileede Naijiria bolẹ fun ọpọlọpọ ọdun.

Kí ni iléeṣẹ́ ológun sọ?

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ologun, ẹka ti OPERATION SAVANNAH SHIELD (JTF OPSS) fi sita, wọn lawọn ọmọ ogun naa lọ sinu igbo lati ni ajọsọ pẹlu awọn agbebọn ati awọn to n gbogun ti eto aabo nipinlẹ Kwara.

Atẹjade ọhun ti adele alakoso lẹka eto iroyin, Ibrahim Shittu buwọ lu, o ni ipade to waye laaarin awọn ọmọ ogun ati agbebọn ni lati gba alaafia laaye lagbegbe naa.

"Ileeṣẹ JTF OPSS fẹẹ dahun si oniruuru ibeere ati awuyewuye to n lọ, nipa fidio ti wọn ri, eyi to ṣafihan awọn ọmọ ogun ati awọn agbebọn ti wọn n fẹ juwọ awọn nnkan ija ogun wọn silẹ, ati iranlọwọ lati fi awọn to wa nigbesi silẹ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Atẹjade ọhun fi kun un pe, nibi ipade naa, awọn ọmọ ogungba ibọn AK-47 mejila lọwọ awọn agbebọn naa, ti wọn si tun gba awọn mẹwaa to wa nigbekun silẹ.

"Idagbasoke naa jẹ aṣeyọri to ni ipa ninu igbeleke eto ọrọ aje, ati ọna lati wa iyanju si iṣoro to n koju eto aabo, lai lo ọna ija," atẹjade ọhun sọ siwaju.

Kí ló yẹ kí o mọ̀?

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn ọmọ ogun yoo maa ṣepade pẹlu awọn agbebọn.

Ni nnkan bi oṣu meloo sẹyin, fidio kan jade nipinlẹ Katsina, eyi to ṣafihan awọn ọlọpaa to n lewaju awọn ẹgbẹ kan to n ko ohun ija oloro pẹlu ọkada, nibi ti awọn ọlọpaa ti gbegi dina.

Ninu fidio naa, ni a ti ri awọn ọlọpaa ti wọn n juwọ si awọn agbebọn naa, eyi to di awuyewuye nigba naa, ṣugbọn lẹyin rẹ ni ọlọpaa sọ pe awọn eeyan naa ṣẹṣẹ jọwọ nnkan ogun ija wọn ni.

Iṣoro ibọn jẹ ọkan gboogi to n koju eto aabo nilẹ Naijiria.

Awọn agbebọn ti ṣe ikọlu si ọpọ ilu, abule ati igberiko, ti wọn si tun ti gbegi dina lati ji awọn eeyan gbe fun owo.

Awọn iṣoro wọnyi ti awọn eeyan lero wi pe ẹkun Ariwa Naijiria nikan lo ti n ṣẹlẹ, lo ti wa tan de awọn ẹkun bii aarin gbungbun ati Ariwa, paapaa awọn ipinlẹ bii Kwara, Kogi ati Niger.