Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mo lò nínú ìgbéyàwó mi àkọ́kọ́ tí ń kò sì rí ọmọ bí níbẹ̀-Toyosi Adesanya
Nigba mi-in, ki ọrọ ẹda too di ayọ, oju yoo ti ri ọpọ nnkan ti ọkan ko fẹ, bẹẹ ni asiko ibanujẹ ọhun le ma mọ niwọn, o le pẹ jọjọ ki ohun ti eeyan n fẹ too wa si imuṣẹ.
Bẹẹ lo ṣe ri fun gbajumọ oṣerebirin tiata, Toyosi Adesanya, ẹni to sọ pe oju oun ri to ki Ọlọrun to sọ oun di ọlọmọ laye.
Obinrin to ṣẹṣẹ bimọ loṣu Kẹta ọdun 2026 yii, nigba to ti n gbe ẹnu le aadọta ọdun, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ọdun mẹẹẹdogun (15) loun fi wa ọmọ ninu igbeyawo oun akọkọ amọ ti oun ko rọmọ bi nibẹ.
Ọpọ eeyan ni ko si tilẹ mọ pe oṣere naa ko ti i bimọ tẹlẹ, bẹẹ ni awọn to mọ pe o ti pẹ nile ọkọ kan lai bimọ ko too kuro nibẹ ko to nnkan.
Ninu alaye ti Toyosi Adesanya to jẹ ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oṣere TAMPAN lapapọ ṣe fun BBC News Yoruba lo ti sọ pe:
''Ọdun mẹẹdogun ni mo lo ninu igbeyawo mi akọkọ ti n ko si ri ọmọ bi nibẹ.
Ọkọ mi ti Ọlọrun pada jogun ọmọ fun mi lati ọdọ rẹ yii naa ti bi akọ, wọn si ti bi abo ka to pade.
Ọkọ mi yii si ba mi rinrin ajo naa gan an, laarin ọdun mẹfa ti emi ati Ajibola Oyin-Adejobi fi rinrin ajo wiwa ọmọ yii; ko si ọkunrin to ba mi rin iru irinajo yẹn ri.
Wọn ni ki ọkọ mi wọ aṣọ kan naa fun ọjọ mẹsan an tori ki n le bimọ, wọn si ṣe bẹẹ nitori mi.
Mo loyun nigba yẹn loootọ, amọ, awọn nnkankan tun ṣẹlẹ, lẹyin naa ni mo tun ṣiṣẹ abẹ.''
Adesanya ni agbo oṣere mi titi nigba toun pada bimọ, iyalẹnu lo si jẹ foun gan an.
O ni awọn kan tiẹ sọ pe oju oun ko jọ oju ẹni to n woju Ọlọrun fun ọmọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi lasiko ifọrọwerọ pẹlu BBC:
''Ẹẹmarun-un ni mo ṣiṣẹ abẹ lọdun 2022 nitori mo n wa ọmọ. Nigba to de asiko kan, dokita gan an sọ fun mi pe o to gẹẹ.''
Toyosi ni wiwa ọmọ ati riri ọmọ wa lọwọ Ọlọrun.
O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba pe gbogbo ọna ti eeyan maa fi n wa ọmọ ni oun gba fi wa ọmọ.
Toyosi ni loootọ loun ko jọ iṣoro airọmọbi toun la kọja, nitori oun ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo sọ oun di ọlọmọ lọjọ kan.
Gbajumọ oṣere naa ni ''Mo gbagbọ pe ayọ gbogbo awọn to n woju Ọlọrun fun ọmọ naa yoo de bi ayọ temi naa ṣe de.''



























