Ṣé lóòótọ́ ní Jackie Chan ti kú àbí ó ṣì wà láàyè bí wọn ṣe ń pín ìkéde ikú rẹ̀ kiri orí ayélujára?

Oríṣun àwòrán, instagram/ jackiechan
Se ni ori ayelujara n gbona jainjain lori iroyin kan to gbalẹ kan pe gbajumọ osere tiata lede oyinbo, to jẹ ọmọ ilẹ Hing Kong, Jackie Chan, ti jade laye.
Oun si ni amuludun miran ti wọn yoo maa polowo iku rẹ lori ayelujara lai se iwadi kikun nipa iku rẹ.
Ikede iku Chan yii lo waye nigba ti ẹnikan lori ayelujara gbe soju opo rẹ lori ayelujara pe agba osere ati onijakadi naa ti silẹ bora.
Ikede naa to yẹ ko jẹ awada lasan lawọn ololufẹ Jackie Chan gba mọra, ti wọn si n se idaro rẹ.
Ikede naa si lo tumọ si pe gbajumọ ajakọnfu naa, tii se ẹni ọdun mejilelaadọrin ti silẹ bora.
Gẹgẹ bi ikede naa se wi, Jackie Chan ti le ni ẹni ọdun mọkanlelaadọrin amọ to ti di ẹni ọdun mejilelaadọrin bayii.
Laarin wakati mẹrinlelogun, se ni iroyin iku Chan naa gbalẹ, to si fọn kaakiri agbaye.
O si le ni eeyan milliọnu mẹta ati ẹgbẹrin to ti se alabapin iroyin naa laarin wakati marun eyi ti ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan yika agbaye ri.
Aaye ni Jackie Chan wa o, ofege lasan ni ikede iku rẹ to lu ori ayelujara yika agbaye kan
Jackie Chan, ẹni ti orukọ rẹ gangan n jẹ Fang Shilong, ni iroyin miran ti fidi rẹ mulẹ pe o wa laaye, to si ni ilera to peye.
Ikede naa, ti wọn fi aworan Chan si lo ni awọ dudu ati funfun, ti wọn si kọ ọdun "1954 si 2026" si lara.
Amọ ko si aridaju iroyin kankan pe Chan ti jade laye tori agba osere naa si wa laaye, to si n jade sita fun araye ri.
Bakan naa lo tun n ba isẹ lọ lori awọn sinima to n sisẹ le lori eyi ti yoo jade laipẹ.

Oríṣun àwòrán, @kayoflagos001
Bi irọ amọmọọpa nipa iku Jackie Chan naa se tan kalẹ lori ayelujara
Irọ amọọmọpa nipa iku Chan naa lo bẹrẹ pẹlu bi wọn se n pin aworan rẹ eyi ti wọn tẹ orukọ rẹ si lara kiri.
Labẹ aworan naa ni wọn tẹ ọdun ti wọn bi ajakọnfu naa si ati ọdun ti wọn kede pe o jade laye.
Iru irọ amọọmọpa nipa iku yii ni wọn saba maa n se fawọn eeyan to jẹ gbajumọ ati amuludun kaakiri agbaye.
Irufẹ awọn ikede ofege yii si ni wọn saba maa n se lori ayelujara, ti wọn yoo lo aworan gbajumọ naa lai fi idi ibi ti wọn ti ri mulẹ.
Jackie Chan si ni wọn lo jade sita lọjọ Keje osu Keje ọdun 2026 yii nilu Singapore nigba to se abẹwo ayanilẹnu sile ẹkọ ijọba ti wọn n pe ni Pei Chun Public School.
Chan ni wọn lo se abẹwo sile ẹkọ naa gẹgẹ bii ara eto kan ti ajọ ẹdawo iranwọ ẹbi Lim se, to si fara kinra pẹlu awọn akẹkọ to le ni ẹẹdẹgbẹrun.
Awọn aworan lati ibi abẹwo naa se afihan gbajumọ osere naa to n kọrin, rẹ ti wọn pe ni O nira lati sọ pe o dabọ, "Hard to Say Goodbye" bakan naa lo si bawọn olukọ ati akẹkọ sọrọ nile ẹkọ naa.
Ijade sita Chan yii si lo fidi rẹ mulẹ pe Chan wa laaye, ti ko si ku gẹgẹ bi wọn se n se idaro rẹ lori ayelujara.
Chan, gẹgẹ bi ọkan lara awọn gbajumọ to gbajumọ yika agbaye, lo ti n kopa ninu awọn ere sinima lati bii ọgọta ọdun sẹyin.
Lara awọn sinima to si ti kopa ninu rẹ ni "Rush Hour", "Police Story" ati "Drunken Master".
Gbajumọ osere naa si lo ti n se gudu-gudu meje ati yaya mẹfa lagbo amuludun, nigba ti awọn eeyan kan si n pin iku rẹ, tii se amọọmọpa irọ kiri yika ori ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ta ni Jackie Chan?
Nigba ti Jackie Chan dagba, to si mọ iru ẹni ti baba rẹ jẹ, ni oun naa ba yi orukọ rẹ pada si Fang Shilong gẹgẹ bii orukọ ọmọ China laarọn ọdun 1990.
Chan lo igba ewe rẹ ni Victoria Peak, British Hong Kong, nibi ti baba rẹ ti n sisẹ Kuku
O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ Nah-Hwa ni Hong Kong Island.
O fidi rẹmi ni ọdun akọkọ ti awọn obi rẹ si mu kuro nile ẹkọ.
Lọdun 1960 ni baba rẹ morile ilẹ Canberra nilẹ Australia, to si di olori Kuku fun ileesẹ asoju ijọba Amẹrika nibẹ.
Ọmọ ọdun marun ni Chan bẹrẹ si ni kopa ninu sinima, nigba to sig be ọdun mẹjọ, o kopa ninu sinima Little Fortunes.
Lati igba naa si lo ti n kopa ninu ọpọ ere sinima.
Jackie Chan tun maa n kọrin, ti wọn si fi oye Ọmọwe meji da lọla nile ẹkọ fasiti onitẹbọmi Hong Kong ati fasiti Cambodia.
Lọdun 1981 ni Jackie Chan pade osere tiata lati ilẹ Taiwan, Joan Lin, ti wọn si se igbeyawo losu kejila ọdun 1982 nilu Los Angeles nilẹ Amẹrika.




























