Kí ló mú kí géèmù GTA 6 máa tà wàràwàrà láàárín ọjọ́ díẹ̀ tó jáde?

Awọn aworan inu rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ Grand Theft Auto 6 ni wọn ti lo di ileeṣẹ to fi itan tuntun balẹ pẹlu bi ikanni ere idaraya wọn ṣe jade sita l'Ọjọbọ, lẹyin ọdun mẹtala.

Ikanni ere idaraya igbalode ti ọpọ ti n reti naa ni wọn lo pa miliọnu mẹrinlelogun ataabo, iyẹn awọn wo o, eyi to le diẹ ni biliọnu meji ($2.36bn) owo dọla, gẹgẹ bi agbeyẹwo ikanni Sensor Tower ṣe sọ.

Lati ṣagbeyẹwo si fọnran to to o, sinima Spider-Man: Brand New Day, lo pa biliọnu meji ataabọ ni gbogbo asiko to fi lọ sinima.

Awọn ileeṣẹ to ṣe akojọ GTA 6 naa, Rockstar ati Take-Two ko tii sọ iye ti ikanni ere idaraya naa ti pa, ṣugbọn bi awọn eeyan ṣe n beere fun un kọja afẹnusọ.

BBC ti wa kan si awọn alakoso lati sọrọ lori ohun to n lọ nigboro lori ikanni ere idara GTA 6 ọhun.

Ikanni ere idaraya naa lo jẹ tuntun ti awọn eeyan ti n reti, lo jẹ iṣẹlẹ iwa ọdaran to ṣẹlẹ lati bi ọgbọn ọdun sẹyin, to si jẹ ọkan gboogi lati ohun afiṣere ninu itan.

GTA 6 di ìtẹ́wọ́gbà

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila ni wọn fi balẹ

Agbekalẹ yii lo balẹ pẹlu afojusun ilẹ Amẹrika, lori bo ṣe jẹ ki gbogbo awọn ololufẹ rẹ ni imọlara to fun wọn ni iwuri lati maa lo o loorekoore.

Agbekalẹ tuntun yii lo ni obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Lucia ati ẹnikeni rẹ, Jason ninu, ti wọn ṣajọ pin iwa ọdaran.

Owo ti ko din ni biliọnu kan dọla la gbọ pe wọn fi ṣagbekalẹ rẹ, leyi ti yoo jẹ ko jẹ ere idaraya oni-fọnran to gbowo lori julọ lagbaye ninu itan.

Ileeṣẹ Sensor Tower sọ pe GTA 6 yoo gbajumọ lagbaye, leyi ti yoo jẹ ki awọn to ba fẹẹ fi ṣere fi awọn eyi ti wọn ti n lo tẹlẹ silẹ ni ida mẹwaa.

Iyẹni ni pe geemu ti wọn fi n ṣere tẹlẹ, wọn ko ni maa raaye rẹ mọ bii ti tẹlẹ.

Wọn ni agbeyẹwo awọn to nii ṣe pẹlu oniruuru atẹjiṣẹ ti wọn ti gba lati ọdọ awọn eeyan kaakiri agbaye, ati bi awọn eeyan ṣe n wọnu rẹ si lojumọ.

Bakan naa ni wọn tun ṣe agbeyẹwo bi awọn eeyan ṣe n wọnu ikanni awọn ere bii PlayStation ati Xbox, pẹlu bi GTA 6 ṣe tun ti de.