Àwọn afurasí adigunjalè ṣèkọlù sí Segun Odegbami nílé rẹ̀ l'Abeokuta, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command
Awọn afurasi adigunjale ṣekọlu si Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, Green Eagles, tẹlẹ ri, Oloye Segun Odegbami, nile rẹ niluu Abeokuta.
Alokoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Oluseyi Babaseyi, lo fọrọ yii lede ninu atẹjade to fi sita loju opo X ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wi pe loru ọjọ Ẹti ogunjọ oṣu Kọnkanla yii ni awọn adigunjale ya wọ ile Oloye Odegbami.
Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Babaseyi, fidi rẹ mulẹ pe Odegbami ti kuro nile iwosan lẹyin to gba itọju tan latari iṣẹlẹ naa.
''Ọlọpaa yoo ṣawari awọn to ṣekọlu si Segun Odegbami nile rẹ''
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Bode Ojajuni, ti ṣeleri wi pe ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ idigunjale to waye nile Odegbami.
Kọmiṣọna ọlọpaa ni gbogbo nnkan to ba gba lawọn yoo fun un lati fọwọ ofin mawọn kọlọnrọsi ẹda to ṣiṣẹ laabi ọhun.
CP Ojajuni to ṣabẹwo si Odegbami nile rẹ, sọ pe iwadii ti n lọ lati fọwọ ofin mawọn to ṣekọlu sile Odegbami lagbegbe Ibara niluu Abeokuta.
Kọmiṣọna ọlọpaa kẹdun pẹlu agbabọọlu Naijiria tẹlẹ naa, o si tun fi dawọn araalu loju pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaarẹ lati pese aabo to peye fawọn eeyan ipinlẹ Ogun.
Ojajuni tun fi da Odegbami loju wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni fọwọ rirọ mu ọrọ naa.
Kọmiṣọna ọlọpaa wa rọ araalu wi pe ki wọn ma foya, ṣugbọn ki wọn ran ọlọpaa lọwọ pẹlu ohunkohun ti wọn ba mọ lati le fọwọ ofin mawọn afurasi adigunjale naa.
Ohun ti a gbọ ni pe afurasi adigunjale mẹta lo ṣekọlu sile Odegbami ni ago meji aabọ loru.
Iroyin kan fi idi rẹ mulẹ wi pe awakọ Odegbami ati oṣiṣẹ ile rẹ kan lawọn adigunjale ọhun kọkọ mu kuro lọna, ki wọn to wọ yara Odegbami.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

























