Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà, gbajúmọ̀ akọ̀ròyìn yóò di ọba alayé ní Uganda

Edward Rukidi Kijanangoma wọ aṣọ funfun to to fi aṣọ olomi ọsan yii ka
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Odu ni Ọmọọba Edward Rukidi Kijanangoma Nyabongo II, to ti n gbaradi lati de ade ọba ilu Tooro nlorileede Uganda, kii ṣaimọ foloko.

Ọpọ awọn to mọ Edward Rukidi Kijanangoma, kii ṣe pẹ wọn mọ nitori wi pe oun ni ipo naa kan, bi ko ṣe pe wọn mọ-ọn gẹgẹ bii gbajugbaja sọrọsọrọ, to si ti lo ọpọlọpọ ọdun gẹgẹ bii agbohunsafẹfẹ nipinlẹ naa.

Ko si ọrọ meji ti awọn eeyan n mu sẹnu bayii, to kọja ti Kijanangoma, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, to si jẹ pe bi wọn ṣe n sọrọ rẹ lori ayelujara, ni wọn n sọ ọ lori awọn ẹrọ bii amohunmaworan, redio ati bẹẹbẹẹlọ.

Oniruuru ariyanjiyan lo ti n waye nipa bo ṣe jẹ pe ọkunrin na ani wọn yan fun ipo ọba ilu Tooro yii.

Bi wọn ṣe n sọ ọ lorileede Uganda, na ani wọn n sọrọ nipa rẹ kaakiri agbaye.

Ilu Tooro jẹ ọkan pataki lara awọn ilu mẹrin to ni itan iṣẹmbaye. Lati bi ọdun mọkandinlọgbọn sẹyin Ọba Oyo Nyimba Kabamba Iguru Rukidi IV to gbesẹ, ẹni ti wọn n pe ni "boy king" lo wa lori ipo naa.

Ọmọ ọdun mẹta ni ọba naa, nigba ti wọn yan an ni ibamu pẹlu aṣa ilẹ naa lọdun 1995. Yiyan rẹ lo waye lẹyin iku baba rẹ lọdun naa.

Oun ni ọba to kere julọ nigba naa, to si wa lori itẹ latigba naa titi t'ọlọjọ fi de loṣu Kẹjọ, ọdun yii. Aisan jẹjẹrẹ lo ṣeku pa a lẹni ọdun mẹrinlelọgbọn.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ayẹyẹ igbade naa yoo jẹ ọjọ ajọyọ, to nii ṣe pẹlu aṣa iṣẹmbaye ti yoo bẹrẹ laaarin oru. Lẹyin naa ni ọba tuntun yii yoo rin irin kilomita mẹrin lọ si aafin Karuziika, nibi ti yoo ti gba ade.

Lẹyin eyi ni ija ẹkẹ yoo waye, leyi to ṣafihan pe gbigba ipo ọba kii wa nirọwọ irọsẹ," minisita feto iroyin ilu Tooro, Charles Mwanguhya sọ fun BBC.

Yoo tun ṣe awọn ayẹyẹ miran lati ṣafihan eto gbigba ade rẹ gẹgẹbi ojulowo ọba ti yoo jokoo sori itẹ.

Yiyan Kijanangoma gẹgẹ bi ọba la gbọ pe ko ni kọlọfin ninu.

Gẹgẹ bi ilana wọn, ọmọọba to ba gbajumọ lo maa jẹ ọba lẹyin ipapoda ọba to wa nipo. Awọn to sunmọ idile ọba, jẹ ko di mimọ pe Oyo ti fi ọmọ ọkunrin silẹ, to si ti jẹ ko di mimọ pe ọba oun ni yoo jọba.

Ṣugbọn ṣa, wọn ko tii sọ idanimọ naa sita, bẹẹ si ni ko sẹni to mọ boya igbimọ Babiito ẹlẹni mọkanlelogun da a mọ, ko to di pe wọn yan Kijanangoma.

Ko sẹni to mọ igba ti Ọba Oyo to waja fẹ iyawo, bẹẹ ni ko sẹni to mọ iyawo tabi ọmọ rẹ.

Sibẹsibẹ, iya ọba naa, Olori Best Kemigisa, ti sọ pe ki wọn tẹle aṣa ati ilana ti ọmọ oun fi silẹ ko too ku.

Ṣugbọn awọn igbimọ afọbajẹ naa ko gbọ ohun to n sọ, wọn ni awọn tẹle ilana aṣa ati iṣẹṣe ilu Tooro.

Eyi lo fa a, to fi jẹ pe ariyanjiyan ati awuyewuye waye nipa yiyan ọba tuntun, leyi ti ko tẹ Kemigisa ati awọn eeyan rẹ lọrun nipa abajade.

Best Kemigisa wọ aṣọ dudu, to fi lo iborun dudu, lasiko to n fi ẹdun ọkan rẹ han.
Àkọlé àwòrán, Iya Ọba Oyo ana to waja, lasiko to n banujẹ lori awuyewuye ti yiyan ọba tuntun.

Ohun ti Kemigisa n sọ bayii nipa bi wọn ṣe yan Kijanangoma ni wi pe awọn afọbajẹ ko tẹle aṣa ọmọ oun, ỌBa Oyo, lẹyin ti wọn ka ogun rẹ sita fun gbogbo ẹbi.

"Gẹgẹ bi iya, ohun to dun mi gidi ni," o sọ bẹẹ, to si ṣapejuwe pe ibi ti wọn ti fẹẹ ṣe ayẹyẹ yiyan ọba tuntun ko jinna si ibi ti wọn sin ọmọ oun si.

Olori naa sọ pe ọmọ Oyo to wa nilẹ Amẹrika ti yẹ lati pada sile, ṣugbọn ti ko le pada bayii, nitori awọn awuyewuye to n lọ kaakiri igboro.

Ṣugbọn gẹgẹ bi minisita feto iroyin ilẹ Tooro ṣe sọ, o ni ọmọ ti wọn n sọ yii, ko sẹni to mọ ọn, bẹẹ si ni wọn ko figba kankan sọrọ nipa rẹ ri, nigba ti baba rẹ wa laye, leyi to tunmọ si wi pe ọba Oyo ko fi ọmọ kankan silẹ ko too ku.

O sọ pe nigba ti Ọba Oyo gba ipo naa lọwọ baba rẹ, Mwanguhya sọ fun BBC, ati pe "ade naa ti lọ sinu agboole miran."

Gẹgẹ bi awọn to sunmọ aafin naa ṣe sọ, ọba gbọdọ wa lati inu iran Babiito, paapaa julọ iran, Ọba George David Matthew Kamurasi Rukidi III.

Ibatan ni Kijanangoma ati Ọba Oyo to gbesẹ jẹ. Ọmọọmọ ni wọn jẹ si Rukidi III, ẹni to jẹ ọba kọkanla, to jẹ laaarin ọdun 1928 si 1965.

Kijanangoma wa lara awọn eeyan ti wọn n foju sọna fun lati gori itẹ naa, to fi mọ Ọmọọba George Desmond Kamurasi, ẹni to gba bọolu fun ẹgbẹ agbabọọlu kan nilẹ Gẹẹsi.

Aarẹ Ugandan, Yoweri Museveni lo n wọ aṣọ ibilẹ Tooro, oun pẹlu Ọba Oyo lọdun 2010.
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Museveni (osi), to da iṣakoso ipo ọba pada lọdun 1990, pẹlu Ọba Oyo (Ọtun) l]ọdun 2010.

Yiyan ọba nilẹ Uganda ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ọrọ oṣelu, bi ko sẹ pe wọn duro lori aṣa ati iṣẹṣe, leyi to jẹ ki ipo naa jẹ gboogi.

Ilu nla pataki mẹrin ọtọọtọ lo di orileede Uganda mu; eyi to tobi ju nibẹ ni Buganda ti olu-ilu Uganda, iyẹn Kampala ti jade.

Ọdun 1967 ni wọn doju ilu naa bolẹ, ṣugbọn ti ijọba Aarẹ Yoweri Museveni tun daa pada lọdun 1990.

Ijọba sọ pe awọn ni lati gbe aṣa ati iṣọkan apapọ larugẹ, ṣugbọn igbesẹ naa ni wọn tun ti tunmọ rẹ si wi pe wọn n wa ọna lati fa oju awọn ara agbegbe naa mọra, fun ọrọ oṣelu.

Pẹlu gbogbo oniruuru awuyewuye to n lọ, ijọba ti ṣatilẹyin fun agboole Babiito fun yiyan Kijanangoma.

Adajọ agba ilẹ naa, Sam Mayanja ti sọ fun aafin ilu Tooro wi pe ki wọn maa ba eto iwuye lọ, nitori pe ko sẹni to tii mu ẹsun kankan wa.

Ijọba ti kede ọjọ iwuye naa, ati pe Museveni yoo wa nibẹ.

Ọmọ Aarẹ, ati olori ologun, Muhoozi Kainerugaba, tun ti ṣatilẹyin ita gbangba fun Kijanangoma. "Ki ijọba rẹ pẹ," o kọ ọ soju opo X rẹ.

Baba rẹ to jẹ Kijanangoma akọkọ, ni wọn bi ninu ọdun ti Ọba Rukidi kẹta dori aleefa. Ọba naa lo fun un lorukọ, eyi to tunmọ si "ẹni to wa pẹlu ilu ori ade".

Ilu ori ade ti wọn sọ asọtẹlẹ rẹ ni iran meji sẹyin ti wa n pada ṣafihan ara rẹ bayii.

Ọdun 1970 ni wọn bi Kijanangoma, ti wọn si tọ ọ dagba ni abule Kidukuru to wa ni Fort Portal, eyi to to kilomita ọọdunrun si Kampala.

O fi ilu naa silẹ lati tẹsiwaju eto ẹkọ rẹ, to si kẹkọọ gboye ninu imọ ikansira-ẹni ati igbohunsafẹfẹ ni fasiti Makerere ti Ugandan lọdun 1999.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbohunsafẹfẹ fun ogun ọdun le diẹ, to si ṣiṣẹ kaakiri lawọn orileede bii Rwanda ko to tun pada si ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ orileede Uganda, iyẹn UBC.

Edward Rukidi Kijanangoma wọ aṣo suutu, o si n rẹrin musẹ
Àkọlé àwòrán, Kijanangoma ti fi ọpọ igbe aye rẹ ṣiṣẹ akọroyin

Ọpọ ọdun to ti lo lagboole igbohunsafẹfẹ ati biba awọn eeyan sọrọ nita gbangba ti fun un ni anfaani si ipo adari, yoo si fun ni anfaani lati ṣe ojuṣe rẹ lori itẹ to ṣẹṣẹ gun.

Lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹbi ọba, Kijanangoma sọ pe oun yoo lọ awọn akitiyan ati ibaṣepọ toun ti ni lati bi ọdun mọkanlelogun gẹgẹ bi akọroyin, lati jẹ ki awọn eeyan "lanfaani si awọn ohun rere".

Mama rẹ, Assimwe Yusta Kijanangoma, sọ pe ọmọ oun jinlẹ gidi ninu aṣa ati iṣẹṣe ilẹ naa.

"Mo tọ ọ dagba pẹlu ẹkọ to ye kooro. Mo n rẹrin pẹlu rẹ, nigba miran, mo maa n fun ni ibawi," obinrin naa sọ fun BBC.

O wa sọ pe inu oun dun wi pe ọba oun yoo de ade ọba.