Wo àwọn nǹkan tí o lè ṣe láti dáàbò bo ọkàn rẹ kó má baà kọṣẹ́ lójijì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn ẹya ara ẹda to ṣe pataki julọ ni ọkan, lọjọ ti ọkan ba ti da iṣẹ silẹ ni opin ẹda.
Gbogbo igba ati lojojumọ ni ọkan maa n ṣiṣẹ, kii sinmi, ọjọ iku si ni ọjọ isinmi fun ọkan.
Pupọ ẹya ara mii lo nilo ọkan lati ṣiṣẹ nitori oun lo maa n pin ẹjẹ kaakiri agọ ara.
Oniruru ẹya lo wa ninu ọkan, apakan lara ẹya naa maa n gba ẹjẹ wọle, bẹẹ ni awọn apakan maa n ti ẹjẹ sita.
O ni iye igba ti ọkan ẹda gbọdọ maa lu laarin iṣẹju kan, to ba kere ju iye igba naa lọ, ewu n bẹ, ti ọkan ba si lu pipi ju iye igba to yẹ lọ, ewu n bẹ pẹlu.
Iwọnyi lawọn nnkan to n ṣakoba fun ọkan Ẹjẹ riru
Awọn onimọ sọ pe nnkan bii biliọnu kan eeyan ni arun ẹjẹ riru n ba finra lagbaye.
Dokita kan to tun jẹ onimọ nipa ọkan ẹda, Egemba Chinonso Fidelis ti ọpọ mọ si Aproko Doctor sọ pe ẹjẹ riru maa n waye nigba ti iṣan to n gbe ẹjẹ ba ti fun ju tabi kere ju bo ṣe yẹ lọ to si ṣoro fun ẹjẹ lati gba inu rẹ kọja, to n tumọ si pe iṣẹ ti ọkan yoo ṣe yoo pọ ju bo ṣe yẹ lọ.
Pupọ awọn to ni aisan ẹjẹ riru ni ko mọ pe awọn ni aisan naa, eyiii ni wọn fi n pe e ni aisan aṣekupani jẹjẹ.
Ọra inu ẹjẹ
Ọra inu ẹjẹ yii ni awọn onimọ n pe ni 'cholesterol.' Aproko Doctor sọ pe ohun ti eeyan n jẹ lọpọ igba lo maa n jẹ ki ọra inu ẹjẹ yii pọ ju bo ṣe yẹ lọ.
Ọra inu ẹjẹ pin si meji, akọkọ ni Low-Density Lipoprotein (LDL) ti ekeji si jẹ High-Density Lipoprotein (HDL). Ti LDL yii ba ti pọ ju ninu ara, o lewu fun ọkan ẹda.
Ti LDL ba ti pọ ju ninu ara, o le maa korajọ sinu awọn iṣan to n gbe ẹjẹ eyii ti yoo di alafo to yẹ ki ẹjẹ maa gba kọja.
Itọ ṣuga
Aproko Doctor sọ pe itọ ṣuga maa n ṣakoba fun iṣan to n gbe ẹjẹ kaakiri inu agọ ara, lara iṣan naa ni eyii to n gbe ẹjẹ lọ sinu ọkan.
Ti irufẹ iṣan bẹẹ ba ti bajẹ, ewu n bẹ loko longẹ.
Awọn nnkan mii to maa n ṣakoba fun ọkan ni:
- Ara asanju
- Siga mimu
- Aikii ṣe ere idaraya dede
- Ẹni ti iasan aisan ọkan wa ninu idile rẹ tẹlẹ
Awọn ohun ti o le ṣe lati daabo bo ọkan rẹ
Aproko Doctor ṣe awọn alakalẹ ohun ti eeyan le ṣe lati daabo ọkan rẹ ko maa baa kọṣẹ lojiji.
Awọn nnkan naa niyi:
- Ṣiṣe ere idaraya loorekoore – gbiyanju lati gbe igbesẹ to le ni egbẹrun mẹwaa loojọ
- Ṣiwọ ṣiga mimu
- Dẹkun ọti mimu
- Ṣayẹwo iye ṣuga to wa ninu ẹjẹ rẹ
Awọn nnkan mii to ṣe pataki ti ọ gbọdọ mọ gẹgẹ bii ọrọ Aproko Doctor ni pe awọn ti ọjọ ori wọn ba ti le ni ọdun marundinlogoji le ni aisan ọkan.
Ekeji to mẹnuba ni pe awọn ọkunrin ni aisan naa ṣaba maa n kọlu julọ.
Ẹkẹta ni pe aisan naa wọnpọ laarin awọn eeyan alawọ dudu.
Aproko Doctor pari ọrọ rẹ pe o ṣe pataki lati maa lọ fun ayẹwo loorekoore nitori awọn akọṣemọṣe oniṣegun nikan lo le sọ ipo ti ilera eeyan wa fun.


























