Àlàyé lórí ìdí tí ìjọba àpapọ̀ ṣe fún Wole Olanipekun ní GCON, oyè kejì tó ga jùlọ ní Naijiria

Wole Olanipekun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti fi oye keji to ga julọ ni Naijiria, Grand Commander of the Order of the Niger (GCON), da agba agbẹjọro nni, Oloye Wole Olanipekun, SAN, lọla.

Idalọla yii lo n waye lati mọ riri ipa ribiribi ti Olanipekun ti ko ni ẹka ato idajọ ati idagbasoke Naijiria.

Ikede oye yii lo waye nibi ti wọn ti ko iwe kan jade lati ṣe ayẹsi ọdun marundinlọgọrin agbẹjọro naa loke eepẹ, fun lilo aadọta ọdun gẹgẹ bii amofin ni Naijiria ati ọdun marundinlọgbọn nipo amofin agba, Senior Advocate of Nigeria.

Oye GCON yii ti wọn gbe kalẹ labẹ ofin National Honours Act lo jẹ oye keji to ga julọ ni Naijiria lẹyin to tẹle oye Grand Commander of the Order of the Federal Republic (GCFR).

Wọn maa n fi oye ọhun da awọn to ti ṣiṣẹ ribiribi ni Naijiria lọla lati mọ riri akitiyan wọn lori ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Ọdun 1976 ni Olanipekun di agbẹjọro ni Naijiria ko to de ipo agbẹjọro lọdun 1991, oun si ni Aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro, Nigerian Bar Association laarin ọdun 2002 si 2004.

Gẹgẹ bii ohun ti Aarẹ Tinubu sọ, wọn fi oye naa da a lọla latari ohun to ti ṣe ni ẹka eto idajọ Naijiria, bo ṣe n ko awọn ọjẹ wẹwẹ agbẹjọrọ mọra to si n wọn di ogbontarigi, bo ṣe n fun awọn eeyan ni ẹkọ ọfẹ, idagbasoke awujọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Aarẹ tun sọ pe Olanipekun ti ṣe agbẹjọro awọn eeyan jankanjankan lawujọ, bẹẹ lo tun ti gba ẹjọ ro fun awọn Aarẹ Naijiria lori ọrọ eto idibo lati ọdun 2007.

Taa ni Wole Olanipekun SAN?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1951 ni wọn bi Olanipekun, OFR, CFR, SAN, GCON.

Agbẹjọro ni, oun lo da ileeṣẹ agbẹjọro Wole Olanipekun & Co, silẹ, o tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan ati oloju aanu ni.

Oun ni Aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, NBA, laarin ọdun 2002 si 2004 ati alaga igbimọ alaṣẹ fasiti ijọba apapọ ilu Eko, UNILAG.

Iwadii wa fi ha ọmọ Ikere-Ekiti, nipinlẹ ni amọ awọn iroyin kan sọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Osun ni.

Awọn ile ẹkọ to lọ ni Amoye Grammar School, Ilesa Grammar School, ati University of Lagos ko to di agbẹjọro.

Ọdun 1980 lo da ileeṣẹ agbẹjọro Wole Olanipekun & Co silẹ, ileeṣẹ naa si ni ọọfisi niluu Eko ati Abuja.

Laarin ọdun 1991 si ọdun 1993, oun ni agbẹjọrọ agba ati kọmiṣọna eto idajọ fun ijọba ipinlẹ Ondo.

Lọdun 2012, o gba oye Officer of the Order of the Federal Republic (OFR), nigba to di ọdun 2022 lo gba oye Commander of the Order of the Federal Republic (nidi iṣ), yatọ si awọn oniruru oye mii nidi iṣẹ amofin to yan laayo.

Iwọnyii lawọn to ti gba oye GCON ni Naijiria ṣaaju Olanipekun

Wayi o, kii ṣe Olanipekun nikan lo tii gba oye yii ni Naiijiria, awọn eeyan jankanjankan mii ti gba a ṣaaju rẹ, yatọ si awọn oloṣelu bii igbakeji Aarẹ.

Awọn mii ti wọn tun ti gba oye GCON gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin Punch ṣe jabọ ree

  • Emeka Anyaoku - Akọwe agba ajọ Commonwealth nigba kan ri
  • Aliko Dangote - Agba oniṣowo ati baba olowo
  • Ngozi Okonjo – Adari ajọ WTO
  • Kudirat Kekere-Ekun - Adajọ agba Naijiria
  • Gilbert Chagoury – Onisowo ati ẹleyinju aanu