Wo Olamiju ọmọ Alao-Akala, Iyabo ọmọ Obasanjo, Adamu ọmọ Atiku, Yusuf ọmọ Buhari àtàwọn ọmọ gbajumọ olóṣèlú tó ń díje ibò ọdún 2027

Ọlamiju Ọmọ Alao Akala, Iyabọ ọmọ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ati Ọmọ Buhari
    • Author, Muslim Muhammad Yusuf
    • Reporting from, BBC Hausa
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Bi orilẹede Naijiria se n sun mọ eto idibo ọdun 2027, se ni awọn araalu n kọbi ara si awọn ọmọ agba oloselu se n du oniruuru ipo oselu.

Awọn ipo naa si le jẹ eyi tawọn baba wọn ti jẹ saaju tabi ki wọn bẹrẹ ni agbọn miran lati mu agbega ba agbara oselu to wa ninu idile wọn.

Lara wọn si la ti ri awọn ọmọ aarẹ to fi ori oye silẹ, awọn ọmọ gomina ati aarẹ ile asofin tẹlẹ, ti wọn ti gba tikẹti awọn ẹgbẹ oselu lati soju wọn nile asofin apapọ ilẹ wa.

Isẹlẹ naa si lo ti n fa awuyewuye bi ọpọ eeyan se n beere pe se ipo oselu ti n di oye ajẹwọ fawọn ẹbi kan ni?

Amọ ero awọn eeyan miran ni pe awọn ọmọ awọn oloselu yii naa ni anfaani lati dupo oselu gẹgẹ bi awọn ọmọ Naijiria yoku.

Amọ awọn onwoye lawujọ, lero tiwọn, sọ pe ipo agbara nilẹ Naijiria lo n sa ara jọ sọwọ awọn ẹbi kan.

Akọsilẹ ti ajọ eleto idibo, INEC gbe sita fihan pe awọn ọmọ oloselu, ti iye wọn to ogun, lo n gbe ipo oselu ninu idibo 2027 to n bọ yii.

Lara wọn ti gbegba ibo sẹyin, ti wọn si ti di ipo oselu mu nigba ti awọn miran ninu wọn sẹsẹ fẹ ti ẹsẹ bọ omi oselu ni.

Ninu wọn, marun lo fẹ dije lọ sile asofin agba, nigba tawọn mẹẹdogun yoku fẹ dije lọ sile asoju sofin nilu Abuja

Ta wa ni awọn ọmọ gbajumọ oloselu naa to fẹ tẹsiwaju nibi tawọn obi wọn fi adagba oselu rọ si?

Awọn ọmọ aarẹ tẹlẹ ti wọn n gbegba ibo:

Awọn oludije sipo oselu mẹta ni wọn jẹ awọn ọmọ aarẹ tabi igbakeji aarẹ tẹlẹ ninu awọn ogun eeyan to jẹ ọmọ gbajumọ oloselu to n dije.

Ọkan lara wọn n dije lọ sile asofin agba nigba ti awọn meji yoku n dije lọ sile asoju-sofin.

Iyabo Obasanjo – Ipinlẹ́ Ogun

Iyabo Obasanjo wọ asọ adirẹ iro ati buba, o si we gele rẹ, o fi ilẹkẹ nla meji sọrun

lyabo Obasanjo jẹ ọmọ aarẹ ana, Olusegun Obasanjo ana

O ti dije fun ipo oselu ri, to si soju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nile asofin agba,

Ninu ibo 2027, Iyabo tun fẹ lọ soju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Ogun nile asofin agba labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP.

O fidi rẹmi ninu ibo abẹnu fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ogun amọ o gba tikẹẹti lati dije sile asofin agba labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP.

Iyabo Obasanjo jawe olubori lẹyin ijagudu ogun oselu, tori bi ọpọ ọmọ ẹgbẹ rẹ atawọn alatako se kọwe ẹsun mọ lẹsẹ lọdọ awọn alasẹ, ki wọn le da duro ninu erongba rẹ lati dije dupo oselu naa.

Yusuf Buhari – Ipinlẹ Katsina

Yusuf Buhari

Yusuf Buhari jẹ ọmọ aarẹ ana, Muhammadu Buhari.

Baba rẹ lo dari orilẹede Naijiria laarin ọdun 2015 si 2023 labẹ asia ẹgbẹ oselu APC.

Yusuf lo n dije lọ sile asoju-sofin lati soju ẹkun idibo Daura, Sandamu ati Mai'adua nipinlẹ Katsina.

E go contest under APC.

Adamu Atiku – Ipinlẹ Adamawa

Adamu Atiku Abubakar

O jẹ ọmọ igbakeji aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar, ẹni to wa nipo naa lasiko isejọba aarẹ for Olusegun Obasanjo.

Baba rẹ wa lara awọn alagbara oselu nilẹ Naijiria, to si ti gbegba ibo aarẹ ni aimọye igba labẹ asia oniruuru ẹgbẹ oselu.

Lọwọ lọwọ bayii, baba rẹ n dije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oselu alatako ADC, ninu ibo ọdun 2027.

Adamu Atiku si lo n dije lọ sile asofin agba fun ẹkun guusu Adamawa labẹ asia ẹgbẹ oselu ADC.

Awọn ọmọ gomina tẹlẹ:

Ọpọ awọn oludije to jẹ ọmọ gomina tẹlẹ jẹ mẹjọ si mẹwa, ti wọn si tẹsẹ bọ bata tawọn baba wọn bọ silẹ lawọn ipinlẹ koowa wọn.

Lara wọn lo n dije fun ile asofin agba nigba ti awọn miran fẹ gbe igba ibo lọ sile asoju-sofin.

Bello El-Rufai – Ipinlẹ Kaduna

Bello El-Rufai
Àkọlé àwòrán, Bello El-Rufai daga hagu

Bello El-Rufai naa jẹ ọmọ gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Nasir El-Rufai.

Lọwọ lọwọ bayii, oun lo n soju ẹkun ariwa ipinlẹ Kaduna nile asoju-sofin lẹyin to fidi asofin to n soju ẹkun naa janlẹ.

Abẹ asia ẹgbẹ oselu APC si lo ti n gbegba ibo oselu naa.

Mustapha Sule Lamido - Ipinlẹ Jigawa

Mustapha Sule Lamido

Mustapha Sule Lamido jẹ ọmọ gomina ana nipinlẹ Jigawa, Sule Lamido, to tun ti se Minisita tẹlẹ nileesẹ to wa fun ọrọ ilẹ okeere.

Ọdun 2019 lo di oloselu lasiko to dije sile asofin agba lati soju ẹkun idibo aarin gbungbun Jigawa labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP.

Lasiko ibo ọdun 2023, Mustapha dije sipo gomina ipinlẹ Jigawa labẹ ẹgbẹ oselu PDP.

O si gbena woju alatako rẹ sipo gomina ;atinu ẹgbẹ oselu APC, Umar Namidi, ẹni to bori idibo naa.

Lọdun 2027, Mustapha tun ti n kopa lati dije du ipo gomina ipinlẹ Kaduna.

Losu Karun ọdun 2026, ẹgbẹ oselu PDP fontẹ lu gẹgẹ bi oludije sipo gomina ipinlẹ Jigawa lai si alatako.

Chinedum Orji – Ipinlẹ Abia

Chinedum Orji jẹ ọmọ gomina ana nipinlẹ Abia, Theodore Orji.

O si n dije du ipo sile asoju-sofin lati soju ẹkun idibo Ikwuano, Ariwa Umuahia ati guusu Umuahia.

Erhiatake Ibori-Suenu – Ipinlẹ Delta

Erhiatake lbori-Suenu jẹ ọmọbinrin fun gomina ana nipinlẹ Delta, James lbori.

O ti bori eto idibo tẹlẹ sile asoju sofin nibi to ti soju ẹkun idibo ila oorun ati iwọ oorun Ethiope.

O wa lara awọn to n dije fun ile asofin apapọ lọdun 2027.

Olumide Osoba – Ogun

Olumide Osoba jẹ ọmọ gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Oluṣẹgun Ọṣọba

O n ṣoju ẹkun Abeokuta North, Odeda ati Obafemi-Owode ni ile aṣojuṣofin.

O wa lara awọn ọmọ eekan oloṣelu to n dije si ipo aṣofin lọdun 2027.

Adegboyega Adefarati – Ondo

Adegboyega Adefarati ni ọmọ gomina ipinlẹ Ondo nigba kan ri, Adebayọ Adefarati.

Oun lo n ṣoju fun ẹkun Akoko South-East ati Akoko South-West ni ileegbimọ aṣofinṣoju, amọ o fẹ dije lẹẹkan sii lọdun 2027.

Olamiju Alao-Akala – Oyo

Ọlamiju Alao Akala

Olamiju Alao-Akala jẹ ọmọ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Adebayọ Alao Akala to ti di oloogbe bayii.

Adebayọ Alao Akala to jẹ baba Ọlamiju wa lara awọn oloṣelu to lamilaka julọ ni ipinlẹ Ọyọ nigba aye rẹ.

o n dije fun ijoko ile aṣojuṣofin lati ṣoju ẹkun Orire, Ogbomoso North ati Ogbomoso South.

Awọn ọmọ awọn eekan oloṣelu miran to n dije

Abba Dahiru Mangal ati Senator Natsha Akpoti ati Sadiq Ango Abdullahi
Àkọlé àwòrán, Abba Dahiru Mangal (lapa osi), Sanata Natsha Akpoti (aarin) and Sadiq Ango Abdullahi (apa ọtun)

Yatọ si awọn ẹbi awọn aarẹ ana, atawọn gomina, a ri awọn miran to wa lati awọn idile awọn oloṣelu miran ti wọn lamilaaka lagbo oṣelu ni Naijiria.

Lara wọn ni:

Natasha Akpoti-Uduaghan (Ipinẹ Kogi): Ọmọbinrin oloogbe Jimoh Abdul Akpoti, to figbakan ri jẹ aṣojuṣofin. Oun ni sẹnetọ to n ṣoju fun ẹkun aringbugbun Kogi, o si n dije fun saa keji.

Sadiq Ango Abdullahi (Ipinlẹ Kaduna): Ọmọ agba oṣelu, Ango Abdullahi. Lọwọ yii, o n ṣoju fun ẹkun Sabon Gari nile aṣojuṣofin fun saa keji.

Awọn ọmọ eekan ilu miran ti ko ri iwe idije gba lẹgbẹ oṣelu wọn

Bi awọn kan ṣe n dunnu pe awọn yoo le dije, awọn miran wa to jẹ ọmọ awọn eekan ilu lorilẹede Naijiria ti wọn lawọn miran fidijanlẹ.

Lara wọn niwọnyii:

Fahad Dankabo — Kano

Fahad Dankabo

Fahad Muhammad Adamu Dankabo wa lati idile baba olowo gọbọi, Oloogbe agba oniṣowo, Alhaji Dankabo, to da ileeṣẹ ọkọ irinna ofurufu Kabo Air silẹ.

Abdullahi Muazu Babangandu fidi rẹ janlẹ nibi idije fun tikẹẹti ẹkun Gwarzo/Kabo nile aṣofinṣoju.

Idris Isa Yuguda — Bauchi

ldris Isa Yuguda, jẹ ọmọ gomina ipinlẹ Bauchi tẹlẹ, Isa Yuguda gbiyanju lati gba tikẹti lati dije fun ile aṣojuṣofin ni Bauchi.

Rasheed Kashamu — Ogun

Rasheed Kashamu, ọmọ Sẹnetọ to ṣoju ipinlẹ Ogun nigba kan ri Senator Buruji Kashamu, naa damọran lati dije fun ijoko ile aṣoju ṣofin fun ọdun 2027, amọṣa Joseph Adegbẹsan fi idi rẹ janlẹ.