Ẹ lo agbára àwọn alálẹ̀ láti ṣẹ́gun ìgbéṣùmọ̀mí - Ooni

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi ọrọ ba kọ òkè to kọ ilẹ̀, o nibi kan àá gbe e si ni Yoruba wi.

Ọrọ ijinigbe, igbesunmọmi ati aisi aabo to gbilẹ kaakiri Naijiria bayii ni Ooni Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi ti n bẹ awọn ọba ẹgbẹ rẹ nilẹẹ Yoruba lati ji giri si bayii.

Atẹjade kan ti Ooni fi sita lọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, latọwọ Akọwe iroyin rẹ, Moses Olafare, lo ti ni kawọn ọba alade lo agbara awọn alalẹ lati koju iṣoro ai si aabo yii, paapaa fun ilẹ Yoruba.

"A gbọdọ mu agbara iṣẹdalẹ wa lo, ka tun sowọpọ pẹlu ijọba"

Ninu alaye rẹ, Ooni Ogunwusi sọ pe o di dandan fun awọn ọba alaye kaakiri ilẹ Yoruba lati mu agbara iṣẹdalẹ lo.

O ni wọn ni lati sowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo lati ṣẹgun awọn ẹni ibi to n ṣọṣẹ lagbegbe wọn.

"A gbọdọ mu agbara ibilẹ wa papọ, pẹlu awọn ajogunba agbara, ati ẹkọ ajọṣepọ ta a ni, lati le awọn agbesunmọmi, ajinigbe atawọn ọdaran gbogbo kuro nilẹẹ Yoruba ati ni Naijiria lapapọ.

"Awọn babanla wa duro fun idajọ ododo ati alaafia awujọ, a si gbọdọ lo awọn nnkan naa bayii. O to gẹẹ!

Ooni tẹsiwaju pe igbesi aye alaafia lo yẹ kawọn eeyan ilẹ wa maa gbe, ki wọn si le rin bo ṣe wu wọn lai si ibẹru lọkan wọn.

"Awọn ọba gbọdọ ṣe ojuṣe wọn fun aabo ilu wọn, bi wọn ṣe n ṣe bẹẹ naa ni wọn yoo si maa ti ijọba lẹyin pẹlu awọn ẹṣọ alaabo."

Ooni sọ pe ijọba apapọ lo ni ojuṣe aabo ẹmi ati dukia ju, o ni ṣugbọn wọn ko le da a ṣe lai si ifọwọsowọpọ awọn ẹka bii lọbalọba, olori ẹsin, awọn alẹnulọrọ ati araalu.

Eyi naa lo si fi gboriyin fun Aarẹ Bola Tinubu, fun igbiyanju rẹ lati ṣẹgun iṣoro aisi aibo ni Naijiria.

O bu ẹnu atẹ lu ijinigbe to waye l'Ogbomoso ati Borno, o si sure pe awọn to wa nigbekun yoo wale layọ, awọn ẹbi wọn yoo si gba itura ọkan.