You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ikọ̀ ọmọ ogun Isreali ṣekúpa olórí Hamas, Abu Karim
Ikọ ologun ilẹ Isreali, 'Israel Defence Forces' (IDF), ti kede pe oun ti ṣekupa Sakr Abu Karim, olori ikọ ogun Hamas kan, ninu ikọlu to waye laipẹ yii.
Ọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu Kẹfa ọdun 2026 ni ikọ ologun Israeli sọ eyi di mimọ loju opo X wọn ti wọn ti kede.
Ikọ ologun IDF ninu atẹjade naa, ṣalaye pe Abu Karim tawọn ṣẹṣẹ pa yii, wa lara awọn aṣiwaju to dọgbọn wọ agbegbe Kisufim, lasiko ikọlu ti wọn ṣe si Israel lọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023.
Wọn fi kun un pe bi ogun naa ṣe n lọ lọwọ, Abu Karim ṣe ikọlu si ikọ ologun Israeli.
Alaye Israeli lori iku Abu Karim
Gẹgẹ bi ikọ ologun IDF ṣe ṣalaye, wọn ni laipẹ yii ni Abu Karim tun ba wọn lọwọ si igbedide ikọ ologun Hamas, ati pe awọn gbọ pe o n ba wọn tọju nnkan ija rẹpẹtẹ si ibugbe rẹ.
Yatọ si eyi, ikọ ologun Israeli tun sọ pe awọn pa oṣiṣẹ Hamas miran, ẹni to n ṣe bii ogbufọ fun wọn.
"Ni gbogbo igba ogun naa, Abu Karim lewaju ikọlu si IDF. "Laipẹ yii lo tako igbiyanju eto jogunomi, pẹlu bo ṣe fẹẹ gbe Hamas dide pada.
"Yatọ si eyi, o tun n ko obitibiti nnkan ija ogun pamọ sile rẹ.
"Bakan naa la tun pa agbesunmọmi kan to maa n ri si ibaraẹnisọrọ fun wọn ninu ikọlu yii."
Bẹẹ ni ikọ ologun Israeli, IDF, kọ ọ soju opo X wọn.
Lasiko ti a pari iroyin yii, Hamas ko ti I fesi si iṣẹlẹ to pa Abu Karim naa.