You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
''Tí ìjọba bá lè gba ọmọ Yoruba láyè láti lo ìlànà ti ìbílẹ̀, ilẹ̀ wa yóò bọ́ lọ́wọ́ agbéṣùnmọ̀mí''
Awọn ọmọ Idi-Apẹ lati iran Afọnja ni Ilorin ni Ipinlẹ Kwara ti sọ wi pe ti ijọba ba le faye gba lilo nnkan ti awọn jogunba, ilẹ Yoruba yoo bori ogun agbesumọmi to n ba a finra.
Wọn sọ eyi dì mimọ lanaa ọgbọnjọ osu Karun un ọdun ti a wa yii, nibi ayẹyẹ ayajọ ọdun Afọnja to waye ni Idi-Apẹ, niluu Ilorin.
Wọn ni ogun ti Yoruba n koju lọwọ yii kọja Bibeli ati Kurani, pe o si se pataki ki Yoruba ronu, ki wọn si pada si bi awọn isaaju ṣe se e nigba iwasẹ.
Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Obarisa Ilorin Afonja, Oba Omobolaji Adifakawo Agbomola, sọ pe awọn agbara ti Afọnja fi jagun si wa sibẹ, awọn si le lo o lati sẹgun ijinigbe ati ipaniyan ti ijọba ba gba awọn laye.
''Ilẹ Yoruba pọnbele ni Ilorin, igba ti Afọnja si n jagun nigba aye rẹ, ko le Bibeli ko si lo Kurani, awọn agbara Yoruba lo fi jagun.
"Awọn nnkan Yoruba ti Afọnja lo si n bẹ titi di akoko yii.
Fun idi eyi, ti ijọba ba gba ọmọ Yoruba laye lati lo ọgbọn ati imọ awọn baba wa, o da mi loju pe ilẹ Yoruba yoo bọ lọwọ ogun agbesumọmi.
"Nigba iwasẹ, ọpọlọpọ nnkan ni Eleduwa fun awọn baba wa lati maa fi doola ẹmi ara wọn.
Akọkọ nínu awọn nnkan wọn yi ni etutu, leleyi ti wọn yoo wọn ilẹ fun idaabobo.
"Ni aye awọn Afọnja, wọn maa n wọn omi silẹ lati fi pẹrọ sinu ilu, bi eegun ba jo ni igba naa, o ni ohun ti o tumọ si.
"Ati eegun, ati gbogbo rẹ lo n jo ni Ilorin yii tẹlẹ, leyi ti ko ruju.
Eegun maa n jo nile Ọba temi naa si gbọnju baa bẹẹ.
"Sango n wa, Igunnu n wa, gbogbo ọja yii tẹlẹ ni eegun, Sango ati Igunnu ti maa n rin, o si ni nnkan to tumọ si.
*Bi ogun ba fẹ wọ ilu, o ni ohun ti awọn baba wa maa n se lati le awọn ẹni ibi pada,'' Obarisa Ilorin Afonja ṣalaye.
Gbọ́mọgbọ́mọ ti wà tipẹ́, ogun Fulani náà sì ti wà tipẹ́
Obarisa fikun ọrọ rẹ pe ''gbọmọgbọmọ o sẹsẹ bẹrẹ, ogun Fulani naa ko si sẹsẹ bẹrẹ si n ja, ewe ati egbo ni awọn baba wa fi sẹgun wọn nigba naa.
Sugbọn lode oni, awọn oloselu wa ti fi ẹṣin aseju ba gbogbo nnkan jẹ, awọn nnkan to yẹ ki wọn pe onisẹse tabi onibilẹ si, wọn o fẹ ki a da si i mọ.
Amọ inu mi dun pe oju gbogbo wa ti ja bayii, Kurani ati Bibeli ti a n pariwo, a o le ko wọn lọ oju ogun, awọn agbesumọmi ti wọn n pa wa gan-an, oogun to wa lara wọn ju ti Yoruba lọ.
Sugbọn awa ti a ni nnkan, a ti da gbogbo rẹ nu, ohun to n seku pa wa ni yẹn.
Ọmọ to ba si sọ ile nu, o so apo iya kọ ni.
Amọ ti ijọba ba le gba awa onisẹse laaye, ti wọn faaye gba ẹgbẹ agbẹkọya, OPC, paapa julọ Iru Ẹkun ti baba wa Sunday Igboho sẹsẹ da silẹ, o da mi loju pe a o sẹgun agbesumọmi ati ogun Fulani.''
Kò sí ìran tí kò ní onísẹ̀se
Obarisa Ilorin Afonja tẹsiwaju pe ko si iran ti ko ni onisẹse wi pe orilẹ-ede Saudi Arabia ti wọn gbe Islam wa gan-an n se isẹse ni wọn ṣe n se ọdun Halloween.
"Orilẹ-ede Iran gan-an o ko Kurani lọ oju ogun sugbọn ọgbọn atinuda ado oloro ati ibọn ti Ọlọrun fun wọn ni wọn fi n jagun.
"Fun idi eyi, ti ijọba ba gba Iru Ẹkun ati awọn ẹgbẹ Yoruba mii laaye ni Kwara, awa naa yoo sẹgun awọn ti wọn n yọ wa lẹnu.''
O wa sọrọ lori Afọnja ati ọdun ti wọn n se wi pe, Afọnja se bẹbẹ pupọ ni ilu Ilorin "nitori oun lo gba Ilorin fun wa, ọdun ti a si n se lonii mu inu mi dun gidigidi, inu gbogbo iran Afọnja kaakiri agbaye si dun pẹlu.''
Olori iran Afọnja ni tile toko, Kolawole Abdullahi salaye pe pataki Afọnja ni Ilorin ni wi pe, o jẹ akọni, o si se ohun pataki lati ilẹ to bẹẹ ti ilu Ilorin fi kun.
O salaye pe Idi-Apẹ ni orisun Ilorin, ọdun Afọnja si se pataki fun gbogbo ọmọ Ilorin, papaa julọ ọmọ Yoruba.
Bakan naa, Umar Arẹ Baba Oniso to jẹ ọkan gboogi ni Idi-Apẹ fi kun un pe pataki Afọnja ni Ilorin ni wi pe, "o mu wa kuro labẹ ijọba Oyo, oun lo mu Ilorin duro ti a o fi si labẹ Ọyọ mọ.
"Ekeji ni pe Afọnja faye gba tẹru tọmọ, o se Ilorin lọkan, Afọnja lo mu idagbasoke ba Islam ni Ilorin nitori pe, o pe ọpọlọpọ awọn Alfa wọle lati Oyo.
"Pataki ọdun Afọnja ti a n se yii ni pe, a o fẹ ki orukọ Afọnja parun, a si n se e ni iranti rẹ lati ko gbodo ọmọ bibi Afọnja ni tile toko jọ.''