Makinde ṣàbẹ̀wò sẹ́bí àwọn èèyàn tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso, ọkọ Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbé bú sẹ́kún

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti ṣàbẹ̀wò si ẹbi awọn olukọ àtàwọn akẹkọọ ti wọn ji gbe ni Esinele ati Yawota ni ìjọba ìbílẹ̀ Oriire l'Ogbomoso.

Gomina tun ṣeleri fun wọn pe gbogbo awọn ti wọn ji gbe yoo pada wale ni alaafia laipẹ.

Makinde sọ fún gbogbo eeyan to wa nibi ipade naa to waye ni Esinele pe kí wọn ma foya torí ìjọba n ṣiṣẹ takun takun lati ri pe won doola awon t'awọn jàndùkú agbébọn ji gbe lọ.

Gomina ipinle Oyo ni oun mọ pe ọrọ ẹnu lasan ko le da awọn ti wọn ji gbe pada wale, amọ, o ṣeleri pe ìjọba oun yóò sa gbogbo agbara rẹ lati doola awon eeyan to wa lakata awon ajinigbe naa.

O fikún ọ̀rọ̀ rẹ pe lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ loun ti n ṣepade lẹẹmeji lojumọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto aabo.

"A o lo gbogbo agbára ti a ni lati doola awọn ti wọn ji gbe lọ."

Gomina ipinle Oyo ṣàpèjúwe iwa ijinigbe gẹgẹ bí iwa to buru jai, eyi ti ko yẹ ọmọ eniyan.

''Igba ẹ̀ṣọ́ Amotekun ló ti kú lórí ọ̀rọ̀ ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ Oyo láti ìgbà tí a ti dá Amotekun sílẹ̀''

Makinde ko ṣai gboṣuba kare fawọn ẹṣọ eleto aabo fun iṣẹ ribi ribi ti wọn n ṣe papaa julọ awọn ẹṣọ Amotekun ti o sọ pe ko din ni igba ninu wọn táwọn ọdaran ti pa nipinlẹ Oyo.

Ẹwẹ, ọkọ ọga agba ile ẹkọ girama Esinele to wa lara awọn t'awọn agbébọn ji gbe, Ọjọgbọn Wole Alamu, ti rọ gomina lati ri pe awọn to wa lakata awon ajinigbe gba ominira.

Ọjọgbọn Alamu wa lori ìkúnlẹ̀ pẹlu omije loju nigba to n rawọ ẹbẹ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo.

Ọgbẹni Aliu Saidi toun naa jẹ ọkan lára àwọn ẹbí àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹkọọ to wa lakata awon ajinigbe bẹ ìjọba láti wa nnkan ṣe si ọrọ naa kiakia.

Lẹyin ti gomina ba gbogbo eeyan sọrọ tan ni gbangba ni o ṣe ipade idakọkọ pẹlu ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ láti ṣàlàyé ibi ti ọrọ naa dé duro fun wọn.

Ìṣẹlẹ ijinigbe yii ti da ìbẹrù bojo silẹ lagbegbe naa to fi dé ilu Ogbomosho.