Ẹgbẹ́ olùkọ́ bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì l'Oyo lórí àwọn tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso, Tinubu kéde ìgbésẹ láti gba aṣógbó 1,000 síṣẹ́

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ olukọ NUT ẹka ipinlẹ Oyo tu yaya jade loni ọjọ Aje ọjọ kinni oṣu Kẹfa lati ṣe ifẹhoinuhan lori awọn akẹkọọ atawọn olukọ tawọn janduku agbebọn ji gbe nile ẹkọ ni Ahoro Esinele ati Yawota ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo.

Ṣaaju ni ẹgbẹ NUT ti sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Oyo wi pe ki wọn ṣe ifẹhonuhan lati beere fun itusilẹ awọn tawọn janduku agbebọn ji gbe.

Aarẹ ẹgbẹ NUT ni Naijiria, Ọmọwe Audu Titus Amba ati akọwe agba ẹgbẹ naa, Ọmọwe Clinton J. Ikpitibo, sọ pe iriri to buru jai lawọn olukọ atawọn akẹkọọ ti wọn ji gbe lọjọ kẹẹdogun oṣu Karun un ni wọn ti ni ninu igbo ti wọn ti wa lati igba naa.

Ẹgbẹ naa sọ pe iyalẹnu lo jẹ wi pe awọn naa si wa lakata awọn ajinigbe titi di akoko yii, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo ti rawọ ẹbẹ si ijọba lati doola wọn.

Ẹgbẹ NUT sọ ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ominu n kọ awọn lori iroyin kan to sọ pe awọn janduku agbebọn naa ti ṣekupa lara awọn eeyan ti wọn ji gbe.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun sọ pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ wi pe awọn olukọ atawọn akẹkọọ naa si tun wa lakata ajinigbe, lẹyin ti ọga ile ẹkọ Arabinrin Alamu to wa lara awọn ti wọn ji gbe ti ṣe oniruuru fidio lati kepe ijọba iranwọ.

Ẹgbẹ naa wa sọ wi pe bawọn olukọ atawọn akẹkọọ naa ṣe wa ni akata awọn ajinigbe lai mọ igba ti wọn maa jade lo jẹ kawọn gunlẹ iyanṣẹlọdi nipinlẹ Oyo.

Ẹgbẹ NUT ni iyanṣẹlodi yii yoo tẹsiwaju titi tawọn to wa lakata ajinigbe naa yoo fi gba ominira.

Tinubu kede igbesẹ lati gba aṣọgbo 1,000 ṣiṣẹ lẹyin iṣẹlẹ ijinigbe l'Ogbomoso

Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti kede igbesẹ ijọba rẹ rẹ lati gba ẹgbẹrun kannẹṣọ aṣogbo lẹyin iṣẹlẹ ijinigbe to waye nijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso nipinlẹ Oyo.

Ileeṣẹ aarẹ ṣalaye pe eyi ṣe pataki lati wa ojutuu si eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria.

Ileeṣẹ aarẹ sọ pe ijọba ipinlẹ Oyo yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba apapọ lori ẹgbẹrun un kan aṣọgbo ti Tinubu kede lati gba siṣẹ.

Ileeṣẹ aarẹ tun sọ pe ijọba yoo ṣe agbeyẹwo ẹbẹ awọn aṣofin atawọn adari niluu Ogbomoso ti wọn n beere fun idasilẹ ibudo ọmogun lagbegbe ti igbo ọba wa nipinlẹ Oyo.