Làásìgbò tún bẹ́ sílẹ̀ ní gáráàjì Ile Ife, èèyàn kan jáde láyé, Gómìnà Adeleke ní kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Olamilekan Ajagungbade wa ni apa osi, gomina Adeleke wa ni apa ọtun

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti rọ Kọmiṣanna ipinlẹ naa, Ibrahim Zungura lati tete bẹrẹ iwadii, ki wọn si pampẹ ofin gbe awọn to ba lọwọ ninu iku ọmọ ẹgbe oṣelu Accord kan ti orukọ rẹ n jẹ Olamilekan Ajagungbade, ẹni ti ọpọ mọ si Emir.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, ni garaaji Mayfair to wa ni ilu Ile Ife ni awọn kan ti yinbọn pa Ajagungbade nibi ija to bẹ silẹ laaarin awọn to n ja lori akoso garaaaji naa.

Iroyin ni Ajagungbade atawọn eeyan ti wọn jọ wa ni garaaji ni ija bẹ silẹ laaarin wọn, ti wọn yinbọn fun-un ṣugbọn ti idi ti wọn fi yinbọn pa ko i tii ye ẹnikẹni titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Fidio kan to gba ori ayelujara ṣafihan ọkunrin naa to doju bolẹ ninu agbara ẹjẹ.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lasiko ti laasigbo n waye lori awọn to n ṣe akoso garaaji ni agbegbe naa.

Wọn ni Ajagungbade lo ti wa ni akọọlẹ eeyan tawọn ọlọpaa n wa ko to di pe o jade laye.

Ajagungbade ni wọn sọ pe o n ṣe ipade pelu awọn awakọ kan ni garaaji naa ki wọn to ṣe ikọlu sii ti wọn yinbọn pa a.

Igbesẹ ni wọn ni o ti ṣokunfa ikọlu laaarin awọn ọmọ onimọto ati garaaji kaakiri ilu Ile Ife eyi to mu ki ọpọ eeyan maa wa ninu inu fu aya fu.

Gomina Adeleke paṣe ki ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lẹyẹ o sọka

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina Adeleke ti wa dari Kọmiṣanna ọlọpaa pe ki wọn ri daju pe wọn tete nawọ gan awọn oniṣẹ ibi to huwa naa, ki wọn si ri daju pe alaafia pada sipo ni agbegbe naa.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ Gomina Adeleke, Olawale Rasheed fi lede tun paṣẹ pe ki gbogbo awọn to n lo garaaji ọhun kuro nibẹ lẹyẹ o sọka.

Gomina Adeleke sọ pe ki gbogbo awọn to n ṣakoso garaaji naa ko yẹba ni kiakia ati pe awọn maa gbe eto nipa imojuto awọn garaaji ati paaki ọkọ sita laipẹ.

Nigba to n rọ awọn araalu lati wa ni pẹlẹ kutu, o ke pe awọn ẹṣọ aabo lati ri pe alaafia pada sipo ni gbogbo awọn garaaji, ki wọn si ri daju pe awọn eeyan n tẹle ofin bo ti tọ ati bo ṣe yẹ.

Bakan naa lo tun ṣeleri lati gbe ofin dide lori idasilẹ awọn ti yoo maa ṣakoso awọn garaaji ọkọ lojuna ati ri daju pe awọn eeyan n tẹle ofin ati ilana to gbe awọn paaki r oni gbogbo tibu toro ipinlẹ Osun.

"A ti n gbe igbesẹ lati gbe aṣẹ kalẹ lati fi da ilana garaaji silẹ. Mo maa gbe ilana ati ofin kalẹ fun awọn alaṣẹ garaaji tuntun lori ọna ti wọn maa ma gba lati fi ṣe amojuto garaaji wọn.

Gomina Adeleke fi kun pe gbogbo awọn ti ade iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori ni wọn gbọdọ foju wina ofin nitori awọn ko ni fi aaye gba ẹnikeni lati jẹgaba ltabi lo ipo lati fi maa huwa ibajẹ.

O tun jẹjẹẹ pe ijọba ko ni fi ọwọ bo ẹnikẹni to ba lọwọ ninu ipaniyan naa lai fi ipo wọn ṣe nitori ofin gbọdọ fẹsẹ mulẹ gidi.

Ẹ o ranti pe ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni Gomina Ademola Adeleke gbe aṣẹ tuntun jade lori idasilẹ igbimọ oluwadii kan to gbe dide lati ṣewadii awọn ipaniyan ati iwa ipa to waye ni orita Naira ati Kobo, garaaji ọkọ ni ilu Ikire, ijọba ibilẹ Irewole ni ọjọ Kerinlelogun, oṣu Kẹjọ.

Aṣẹ naa fun igbimọ oluwadii ọhun ti adajọ Majisireeti Ayokunle Shiyanbola ko sodi lagbara lati ṣewadii ohun to ṣokunfa ikọlu naa, ṣe agbejade iye ati orukọ awọn to fori sọta iṣẹlẹ naa, ṣewadii ohun to fa ikọlu ọhun ati boya o ni nnkan ṣe pẹlu iku to waye nibẹ.