Ijó tí mò ń jó kò dí iṣẹ́ mi lọ́wọ́, àsìkò ijó wà, bẹ́ẹ̀ ni àsìkò iṣẹ́ wà – Adeleke

Adeleke nibi eto ilu kan

Oríṣun àwòrán, Adelemola Adeleke

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Osun, to tun n dije du ipo fun saa keji, Ademola Adeleke ti sọ pe ijo ti oun maa n jo ko di iṣẹ oun lọwọ lati sin araalu gẹgẹ bii gomina.

O ni awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to maa n bu oun pe ijo nikan loun mọ n jowu oun nitori wọn ke le jo ni ati pe ti wọn ba fẹ ki oun kọ wọn ni ijo, oun yoo kọ wọn.

Adeleke lo sọrọ naa lasiko ipade ita gbangba rẹ pẹlu araalu, eyii ti ileeṣẹ iroyin Arise ṣe onigbọwọ rẹ niluu Osogbo.

Gomina naa ni ijo jẹ nnkan ti oun fẹran pupọ, ijo naa ko si di iṣẹ oun lọwọ nitori oun ko ki n fi iṣẹ ṣere.

O ni "Mo maa n jo nitori ni idile mi, alayọ ni gbogb wa. Bi mo ṣe n jo naa ni mo n ṣiṣẹ. Asiko wa fun gbogbo nnkan.

"Asiko ijo wa, bẹẹ naa ni asiko iṣẹ. Ijo jijo ko di iṣẹ mi lọwọ. Gbogbo ọna ni mo ti ṣiṣẹ fun araalu."

Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti gomina ipinlẹ Edo, Monday Okpebholo pe e ni gomina onijo.

Adeleke sọ pe ki gbogbo awọn ti ijo oun ba n bi ninu lọ kọ ijo dipo ki wọn maa sọrọ kobakungbe nipa ijo pun.

APC lo pin ẹgbẹ oṣelu PDP

Nigba to n dahun ibere nipa eredi to fi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord, Adeleke ni ẹgbẹ daadaa ni ẹgbẹ oṣelu PDP ki APC to tu ẹgbẹ naa ka.

O ni lẹyin ti oun ri pe o ṣeeṣe ki oun ma ri ẹgbẹ oṣelu lati dije fun saa keji loun fi lọ darapọ mọ ẹgbẹ Accord.

Gomina ọhun sọ siwaju si pe to be ṣeeṣe ki oun dije lai si ninu ẹgbẹ oṣelu kankan ni, oun yoo ṣe bẹẹ, oun yoo si wọle.

O pari ipade naa pẹlu arọwa si awọn eeyan ipinlẹ Osun pe ki wọn ma naani ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ alatako n sọ amọ ki wọn fi ibo wọn gbe oun wọle fun saa keji.