Àwọn olólùfẹ́ Kola Oyewo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́yìn ìsìnkú rẹ̀

Àkọlé fídíò, Àwọn olólùfẹ́ Kola Oyewo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́yìn ìsìnkú rẹ̀
Àwọn olólùfẹ́ Kola Oyewo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́yìn ìsìnkú rẹ̀
Published

Wọn ti sin oku gbajumọ agba oṣere nni, Oloogbe Gabriel Adekola Benedict Oyewo.

Ọjọ Ẹti, ọjọ keje oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni wọn sin oku naa siluu rẹ niluu Oba Ile, ipinlẹ Osun.

Tẹ o ba gbagbe, Oloye Oyewo jade laye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii lẹni ọgọrin ọdun.

Awọn oṣere tiata ko wa sibi isinku naa

Ohun kan ti BBC News Yoruba ri òye rẹ nibi eto isinku naa ni pe awọn oṣere tiata ti wọn jẹ akẹgbẹ Oloogbe Kola Oyewo ko si nibẹ.

Oṣere kan ṣoṣo ti a ri nibi ayẹyẹ naa ni Abilekọ Toyin Adegbola (Ajoke Asewo to re Meka.)

Nigba to n sọrọ nipa Oloogbe Kola Oyewo, Ajoke sọ pe oun ti mọ Oloogbe naa bayii o ti pe ogoji ọdun, ati pe baba naa ṣe pupọ ninu aye oun.

"Nipasẹ Kola Oyewo ni mo fi di gbajumọ oṣere loni, imọran ati itọsọna wọn ran mi lọwọ pupọ ninu irin ajo aye mi."

O fi kun un pe Oloogbe Kola Oyewo jẹ Baba rere ati ololufẹ gbogbo eeyan patapata, ti ko si yọ ẹnikẹni silẹ rara.

Baba mi jẹ ọrẹ mi, abiyamọ rere ni-Adetoyese Oyewo

Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Kola Oyewo, Adetoyese Oyewo, ninu ọrọ rẹ ṣapejuwe iru ẹni ti baba rẹ jẹ nigba aye rẹ.

Adetoyese ni:

"Baba mi jẹ ọrẹ mi, ololufẹ ati adari rere fun mi ati fun gbogbo awa ọmọ rẹ patapata.

"Baba mi ki i ṣe bi baba si awa ọmọ rẹ, o rẹ ara rẹ nilẹ o si ṣe wa bii ọrẹ rẹ ni.

"Baba mi ko le jẹun ko ma ṣẹku fawa ọmọ rẹ, wọn si ni aṣa kan, fifi oju ba ọmọ sọrọ ni, ko le ye alejo, awa ọmọ rẹ nikan lo ye."

Adetoyese Oyewo tẹsiwaju pe Baba oun jẹ ẹni to ko ẹbi ati gbogbo ilu Oba-ile mọra, adari rere si ni pẹlu.

O ni iku baba naa dun oun pupọ, amọ ko si ohun toun le ṣe si i.