Ṣé lóòótọ́ ni Najeem Salam, olùdíje ADC l'Osun fẹ́ ju ọwọ́ sílẹ̀ fún olùdíje míràn fún ipò gómìnà?

Oríṣun àwòrán, osun defender
Ọkan lara awọn oludije fun ipo gomina ninu idibo si ipo gomina ti yoo waye lopin ọsẹ yii ni ipinlẹ Ọṣun ni Ọmọwe Najeem Salam, ti ọpọ mọ si 'Iwaloye' jẹ. Amọṣa, iroyin to n kaakiri lati nnkan bii ọjọ diẹ sẹyin ni pe o ti gba lati ju ọwọ silẹ ko sigbaruku ti oludije miran fun ipo naa.
Ninu ọrọ to ba awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu naa sọ nilu Ejigbo, gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Rauf Arẹgbẹṣọla ṣalaye pe irọ lasan ni ahesọ ọrọ naa ati pe Najeem Salam ṣi ni oludije ẹgbẹ naa fun eto idibo ọhun, bẹẹni ko ṣiṣẹ pọ pẹlu oludije tabi ẹgbẹ oṣelu kankan.

Oríṣun àwòrán, osun defender
Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla to jẹ akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu ADC lorilẹede Naijiria ṣalaye pe awọn ọgbọn ẹwẹ ti awọn ẹgbẹ alatako n da ni ahesọ naa lọna ati le da omi tutu si ọkan awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu ADC ati Najeem.
"Kii ṣe ifẹ owo lo sun wa de idi oṣelu. Ohun to jẹ ilepa wa naa ni bi ọlọrun yoo ṣe lo wa lati fi tan iṣoro awọn araalu, fun itusilẹ wọn kuro ninu igbekun."























