Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì kọlu Columbia, èèyàn 132 jáde láyé, ọ̀pọ̀ há sábẹ́ àwọn ilé tó dàwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, eeyan 132 lo ti jade laye, ti ijọba si ti kede ilu o fararọ ni Columbia lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riri to waye nibẹ.
A gbọ pe o ṣeeṣe ki iye awọn to ti ku nibẹ tunbọ pọ si latari ọpọ eeyan ti wọn ha sabẹ awọn ile to dawo.
Iroyin ni iṣẹlẹ naa ni iru rẹ to buru julọ laarin ọdun diẹ si asiko yii.
Ilẹ riru ọhun ti iwọn rẹ to '7.4 magnitude' waye ni nnkan bii aago meje abọ, o si jin to iwọn 103km lagbegbe Chocó.
Ijọba orilẹede naa sọ pe ilẹ mi titi fun ọpọ kilomita lati agbege ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye de awọn ibomii.
Pupọ awọn ti wọn ku lo wa lagbegbe Pereira, to jẹ agbegbe ti wọn ti n gbin coffee, nigba ti awọn agbegbe mii to yi ka bii Valle de Cauca naa fara gba nibẹ.
Aarin ibi gan ti iṣẹlẹ ọhun ti buru julọ ni San José del Palmar, ni Chocó, amọ iyalẹnu lo jẹ pe awọn eeyan ko farapa tabi ku nibẹ, gẹgẹ bii adari agbegbe ọhun, León Fabio Marín Moncada ṣe sọ.
Ajọ Association of Capital Cities sọ ninu atẹjade kan pe o le ni eeyan 480 to farapa ninu iṣẹlẹ ọhun bayii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yatọ si aaringbungbun iṣẹlẹ ọhun, awọn ilẹ tun ya ni nnkan bii kilomita marundinlọgọta si agbegbe naa.
Ile marunlelọgọta da wo laarin ilu ọhun nigba ti eeyan ogoji jade laye, pẹlu igbagbọ gbe awọn eeyan ṣi ha sinu ile marundinlogun to dawo.
Ijọba ti kede konile-o-gbele lawọn agbegbe kan nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Niluu Cali to wa ni kilomita 160 si Pereira, ile mejilelọgbọn lo wo lulẹ nibẹ.
Ọkunrin kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Dan Cutler to wa lati London sọ fun BBC pe iṣẹlẹ naa lo ji oun lori ibusun, bẹẹ ni oun ko ri iru rẹ ri lati ọdun mọkandinlọgbọn ti oun ti dele aye.
Wayi o, ko si iroyin ilu kankan lagbegbe Manizales, Quibdó ati Medellín.




























