Àlàyé lórí bí ọkọ obìnrin kan ṣe kùn ún lóorun tí awọn ọkùnrin míì sì ba lòpọ̀ fún ọdún mẹ́tàlá gbáko

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Beth Cruse
- Role, West of England
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Nigba ti Joanne Young ji to si ri pe wọn ti so oun mọ ori ibunsun, ko mọ irufẹ aburu to ti ṣẹlẹ lasiko ti oun n sun fọnfọn.
Nigba to gbọ ti ọkọ rẹ Philip Young n pe ẹnikan pe ki ẹni naa ṣokalẹ lo to mọ pe ẹlomii wa ninu yara kan naa pẹlu wọn.
Ko mọ pe ọkọ rẹ ti ṣe ipolongo lori ayelujara pe ki awọn ọkunrin mii wa fi ipa ba oun lopọ.
Ọkunrin naa fi oogu kun un loorun, o si ke si awọn ọkunrin mii lati maa wa ba lopọ.
Fun odidi ọdun mẹtala gbako ni iwa laabi naa fi waye.
Wayi o, ọkunrun mẹrin ti jẹbi ẹsun fifi ipa ba a lopọ, nigba ti ọkọ rẹ atijọ, Young, ti sọ fun ile ẹjọ pe lootọ loun jẹbi oniruru ẹsun ifipabanilopọ.

Oríṣun àwòrán, Swindon Advertiser
Young ṣe ipolongo iyawo rẹ loju opo Craigslist ati Grindr pẹlu akọle "cuckolding".
James Foster, to jẹ agbẹjẹro fun ajọ Crown Prosecution Service (CPS), sọ pe Young yoo ka fidio bo ṣe n fi ipa ba iyawo rẹ lopọ yatọ si pe o n pe awọn ọkunrin mii lati ṣe bẹẹ pẹlu.
Lara awọn ọkunrin to ba obinrin naa lopọ ni Dean Hamilton to sọ fun ile ẹjọ pe ọdun 2015 loun ba a lopọ lọna ti ko ba ofin mu.
Awọn ọkunrin mii ti wọn jẹbi ibalopọ pẹlu ipa pẹlu Joanne ni Connor Sanderson-Doyle, Richard Wilkins, Norman Macksoni, ati Mohammed Hassan.
Wọn sọ fun ile ẹjọ pe awọn gbagbọ pe adehun tọkọtaya naa ni pe ki awọn naa ṣe nibẹ, ati pe awọn ri pe ni ṣe ni Joanne dibọn bii ẹni to n sun – amọ oorun bii iku lo kun obinrin ọhun.
Foster ni ko si igba kankan lasiko ti ibalopọ naa n lọ lọwọ ti wọn bere lọwọ obinrin ọhun pe ṣe nnkan ti wọn n ṣe tẹ lọrun.

Oríṣun àwòrán, Wiltshire Police
Ofin sọ pe ibalopọ kankan ko le waye ayafi ti ẹni ti wọn n ba lopọ ba gba lati ṣe bẹẹ, ati pe ẹni naa gbọdọ wa ni ipo to le gba tabi kọ ibalopọ naa.
Wọn sọ fun awọn oluwadii pe ki wọn ṣewadii lati mọ boya awọn afurasi naa gbaṣẹ lọwọ obinrin ọhun ki wọn to gun ori rẹ.

Oríṣun àwòrán, Wiltshire Police
Ọjọgbọn Marianne Hester ni fasiti Bristol sọ pe Joanne ko si ni ipo to le sọ pe oun ko gba nitori "obinrin ko lagbara ati gba ibalopọ to ba wa loju orun."
Bakan naa lo ni "ti wọn ba kun wọn loorun, wọn ko le gbe igbesẹ lati gba ibalopọ laaye."
Hester, to jẹ oluwadii nipa iwa ipa si obinrin fun ọpọ ọdun sọ pe awọn nnkan wọnyii n tọka si iwa awọn kan si awọn obinrin ati ibalopọ.
Ọjọgbọn naa sọ siwaju si pe "A gbọdọ bere awọn ibere kan lọwọ awọn ọkunrin, wọn ro pe o tọ ki awọn kan ni ibalopọ… a n ri iwa ipa ibalopọ gẹgẹ bii ohun ti ko buru, eyii si lewu gigi.
"Fun idi eyii, mo gbagbọ pe irufẹ nnkan bayii ṣi maa ṣẹlẹ si lọwọ iwaju."

Oríṣun àwòrán, Manon Cruz/REUTERS
Ọrọ yii ti mu ọpọ maa woye ipa ti awọn oju opo ayelujara n ko lati ran iwa ipa si obinrin lọwọ.
Lisa Sugiura, to jẹ ọjọgbọn iwa ọdaran ori ayelujara ati obinrin ni fasiti Portsmouth sọ pe ojuṣe awọn oju opo ayelujara ni lati gbogun ti iwa ipa loju opo wọn.
"Bawo lawọn oju opo yii ṣe maa ṣe ohun to wu wọn lai si idiwọ tabi ijiya kankan fun wọn?"
"O yẹ ka kọkọ bere awọn ibeere wọnyii ki a to maa sọrọ nipa ọkunrin to ni oun le gba ẹnu iyawo oun sọrọ lori boya o fẹ ni ibalopọ tabi bẹẹ kọ."

Iwadii fi han pe oniruru iwa yii ni wọn n ṣe iwadii lori rẹ lọwọ bayii kaakiri ilẹ Gẹẹsi.
Ajọ National Crime Agency sọ pe ijọba gbọdọ bojuto irufẹ iwa ọdaran bẹẹ lai fi akoko ṣofo.
Iwadii NCA fidi rẹ mulẹ pe eeyan 270 lo n lo oniruru oju opo ayelujara nibi ti irufẹ iwa yii ti n waye lọwọ.
Awọn oluwadii sọ pe o ṣoro lati ṣewadii irufẹ awọn iwa ọdaran bayii.
Wọn ni iwa ọdaran naa jẹ tuntun, o si fẹ ẹ jẹ iru eyii ti awọn ko gbọ ri
Amọ Sugiura ko gba bẹẹ, o ni kii ṣe ohun tuntun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, imọ ẹrọ ti mu ko rorun lati maa wu irufẹ iwa ọdaran bẹẹ ni idakọnkọ.
O ni imọ ẹrọ ti mu ko rọrun lati wu iwa ọdaran to ti n waye fun ọpọ ọdun ti ẹnikẹni ko mọ si.
O pari ọrọ rẹ pẹlu igbagbọ pe awọn kan ṣi n wu iwa ọdaran naa lọwọ bayii amọ ti akara wọn ko tii tu sepo.
























