Wo nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Obi Davies-Ekwenna, dókítà tó fi rọ́bọ́ọ̀tì ṣiṣẹ́ abẹ àkọ́kọ́ ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, Obi Davies-Ekwenna
Ọjọgbọn Obi Davies-Ekwenna, to jẹ adari ileeṣẹ Robo Mecis ati oludasilẹ ileeṣẹ RoboMed Global Inc. lo dari ikọ to ṣiṣẹ abẹ pẹlu ẹrọ rọbọti lori ayelujara fun igba akọkọ ni Naijiria.
Iṣẹ abẹ naa ni wọn ṣe fun alaisan kan to wa niluu Abuja nigba ti Ọjọgbọn ati ikọ alabaṣiṣẹ rẹ wa nile iwosan niluu Mowe, nipinlẹ Ogun.
Ọjọgbọn naa jẹ ogbontarigi nipa iṣẹ abẹ ṣiṣe pẹlu imọ ẹrọ igbalode.
Iṣẹ rẹ to ṣẹṣe ṣe, eyii to milẹ titi yii lo waye lọjọ Abamẹta to kọja lati yọ ẹdọforo kan ti kokoro jẹjẹrẹ n ba finra.
Inu ọgba Redeemer's Health Village ni Davies-Ekwenna wa to si ṣiṣẹ abẹ naa fun ẹni to wa nile iwosan Nisa Premier Hospital niluu Abuja.
Ẹrọ ayelujara ni wọn fi so irinṣẹ to wa nile iwosan Abuja pọ mọ awọn ẹrọ mii ti dokita naa lo nile iwosan to wa ni Mowe.
Iṣẹ abẹ naa ṣaṣeyọri bo tilẹ jẹ pe alafo to wa laarin ilu Mowe ati Abuja fẹ ẹ le ni 500 kilomita sira wọn.
Iwọnyii lawọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa Ọjọgbọn Davies-Ekwenna

Oríṣun àwòrán, Obi Davies-Ekwenna
Davies-Ekwenna jẹ Ọjọgbọn nipa imọ Urology ati Transplant Surgery, o si jẹ oniṣẹ abẹ to maa n fi ẹrọ rọbọọti ṣiṣẹ abẹ naa.
O tun jẹ Ọjọgbọn ati igabkeji ni ẹka imọ Urology ni fasiti Toledo, to wa niluu Ohio, nilẹ Amẹrika, nibi to tun ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii olukọ imọ Urology ati Transplantation.
Ọkunrin naa ti kopa ninu awọn iṣẹ abẹ ti wọn fi rọbọọti ṣe ṣaaju ni Naijiria atawọn orilẹede kan ni iwọ oorun ilẹ Afrika.
Lara awọn iwe ẹri to wa lọwọ Ọjọgbọn naa ni ti American College of Surgeons, o tun gba oye Diploma ni American Board of Urology.























