Ta ni Abdurasheed Maina, Alága tẹ́lẹ̀ lẹ́ka àjọ tó ń rí sí owó ìfẹ̀yìntì tí EFCC ń wá ?

Abdulrasheed Abdullahi Maina

Oríṣun àwòrán, EFCC

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n ri si ajẹbanu lorilẹede yii, EFCC, ti kede pe awọn n wa Abdulrasheed Abdullahi Maina, Alaga tẹlẹ fun ajọ to n ri si atunṣe owo ifẹyinti ni Naijiria.

Ọjọru, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii ni EFCC fi ikede naa sita, ẹsun ti wọn si fi kan Maina ni pe o tẹwọ gba awọn ẹru kan to jẹ ẹru ole.

Maina ki i ṣe aimọ nipa ẹsun to jẹ mọ ajẹbanu ni Naijiria, eyi si kọ ni igba akọkọ ti EFCC yoo kede pe awọn n wa a.

Tẹ o ba gbagbe, EFCC ti figba kan fẹsun ajẹbanu, lilo ayederu apo ikowosi, jibiti ati fifi eru boju ko owo jọ, kan Maina.

Ninu ikede ti EFCC fi sita lọtẹ yii, eyi ti wọn fi aworan Maina si ni wọn kọ ọ si pe:

"A n fi eyi to gbogbo eeyan leti, pe EFCC n wa ABDULRASHEED ABDULLAHI MAINA, ẹni ti aworan rẹ han loke yii fun ẹsun gbigba awọn dukia jẹ to ẹru ole."

EFCC rọ ẹnikẹni to ba ni ifitonileti nipa ibi ti Maina wa lati kan si eyikeyi ẹka ajọ naa lorilẹede yii.

Wọn ni eeyan le fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa nitosi leti pẹlu tabi awọn ajọ eleto aabo mi-in.

EFCC ko ṣai fi nọmba ẹrọ ibanisọrọ kan ti eeyan le fi kan si wọn sita, ati adirẹsi lẹta ori ayelujara ti a mọ si email.

Ta a ni Abdulrasheed Maina gan-an?

Ninu atẹjade ti EFCC fi kede pe awọn n wa Abdulrasheed Abdullahi Maina, eyi ti ọga ẹka iroyin wọn; Dele Oyewale fi sita ni wọn ti sọ pe ọmọ ilu Biu, nipinlẹ Borno ni Maina.

Ikede naa sọ pe ẹni ọdun mọkanlelọgọta (61) ni.

Maina di gbajumọ lasiko to n ṣe alaga ajọ ijọba apapọ to n ri si atunṣe owo ifẹyinti (Presidential Task Force on Pension Reforms),

Eyi jẹ labẹ iṣakoso aarẹ tẹlẹ, Goodluck Jonathan.

Iṣẹ ti wọn gbe fun Maina nigba naa ni lati mojuto kudiẹ-kudiẹ ati jibiti lẹka owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ.

Amọ awuyewuye lo gbẹyin iṣakoso rẹ naa pẹlu bi EFCC ṣe fẹsun jibiti kan Abdulrasheed Maina funra rẹ.

Awọn ẹsun ti EFCC fi kan Abdulrasheed Maina

EFCC pe Abdulrasheed Maina lẹjọ lori ẹsun kikowo jọ lọna eru, wọn ni o fi owo naa ṣe awọn nnkan ti yoo da bii pe owo ara rẹ lo fi ko wọn jọ (Money laundering).

Lori ẹsun naa, ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja paṣẹ pe ki Maina lọ ṣẹwọn ọdun mẹjọ, eyi waye loṣu Kọkanla ọdun 2022.

Kootu tun gbẹsẹle awọn dukia to fi ipo rẹ ko jọ.

Awọn dukia naa ni ile ẹjọ sọ pe wọn wa ni Kaduna, Borno, ipinlẹ Sokoto ati Abuja.

Maina pe ẹjọ Ko tẹmi lọrun nigba naa, amọ lọtẹ yii ti EFCC tun kede pe wọn n wa a yii, wọn ko sọ boya lori ẹjọ atijọ naa ni, wọn ko si mẹnuba awọn dukia ẹru ole ti wọn fẹsun rẹ kan an bayii.