Wo àwọn ààrẹ Naijiria tí wọ́n lọ sílẹ̀ òkèèrè fún ìsinmi tàbí ìtọ́jú ara wọn fún ọjọ́ pípẹ́ lásìkò tí wọ́n wà lórí oyè

Bola Tinubu, Muhammadu Buhari ati Umaru Musa Yar'Adua wọ agbada

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu, Muhammadu Buhari and Umaru Musa Yar'Adua

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awuyewuye si n lọ lori bi Ààrẹ Bola Tinubu ti pẹ ni irinajo to lọ papaa julọ lai gbe ìjọba fún Igbakeji Ààrẹ Kashim Shettima wi pe ko maa ba iṣẹ lọ.

Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako wa lara awọn to koro oju si ìgbésẹ Ààrẹ Tinubu ọhun.

Olùdíje sipo aarẹ f'ẹgbẹ oselu ADC, Atiku Abubakar àti oludijẹ ẹgbẹ AAC, Omoyele Sowore, sọ pe bi Tinubu se lọ sajo fun igba pipẹ lodin sofin Naijiria.

Sowore tiẹ sọ pé Tinubu ti lo ju iye ọjọ ti ofin la kalẹ pe o le lo ni irinajo lọ.

Amọ, kii ṣe igba akọkọ ree ti aarẹ to wa lori oye ni Naijiria yóò lọ si Irinajo fun igba pipẹ lati ọdún 1999 ti Naijiria ti pada si ijọba awaarawa.

Wọnyi ni awọn aarẹ to ti lọ sajo fun igba pipẹ yala fun ìsinmi tabi fún itọju ara wọn lasiko ti won wa ni ipò

Umaru Musa Yar'adua

Ọjọ kẹtalelogun oṣù Kokanla ọdún 2009 ni Ààrẹ Umaru Musa Yar'adua gunle irinajo lọ sí Saudi Arabia fun itọju aisan ọkàn ati kíndìnrín to n ṣe é nigba to wa nipo.

Yar'adua wa lajo lasiko naa fun ọjọ mejilelaadọrun ùn tii se oṣù mẹta gbako.

Aarẹ Yar'adua ko gbe ijoba fún igbakeji rẹ, Goodluck Jonathan fun oṣù mẹta to fi wa l'ajo yii.

Eyi lo fa awuyewuye lori ọfiisi aarẹ to ṣofo nigba naa.

Nigba to ya nile aṣòfin àgbà l'Abuja pada sọ Jonathan di aarẹ.

Ninu oṣù Kejì ọdún 2010 ni Yar'adua pada si Naijiria, amọ, ko le ṣe nnkan kan mọ titi to fi jade laye lọjọ karun un osu Karun un ọdun naa.

Muhammadu Buhari

Lẹyìn tí Ààrẹ Muhammadu Buhari lo bi ọsẹ meji tan niluu London nibi ti o lọ fún ìsinmi ni o sọ asiko isinmi ọhun dì ọsẹ meje lati le tọju ara rẹ fún aisan kan ti ko sọ sita.

Ni ọdún 2017 ni Buhari pẹ lajo ju lẹyìn tí o lo ọjọ mẹtalelọgọrun un niluu London nibi ti o ti n gba itoju.

Amọ, Igbakeji Ààrẹ Yemi Osinbajo ṣiṣẹ gẹgẹ bí adele aarẹ to fi di oṣù Kàrún un odun 2021.

Bola Tinubu

Lati igba ti Ààrẹ Bola Tinubu ti de ipò aarẹ ni ọpọ eeyan ti n kọminu lori bi o ṣe n lọ fún ìsinmi ọlọjọ pipẹ nilẹ okeere.

Ọpọ lo bu ẹnu ẹtẹ lu bi Tinubu ṣe lọ fun ìsinmi nílẹ okeere lọdun 2024, 2025 ati 2026 ti a wa yii fun ọjọ mọkanlelogun ti o si tun n ṣe àfikún ọjọ to n lo nibẹ.

Tinubu si wa nilẹ okeere lasiko ti a kọ iroyin yìí lẹyìn tó ṣe afikun iye ọjọ́ to fẹ lo lásìkò ìsinmi rẹ nilẹ okeere.

Tinubu ni ààrẹ Naijiria akọkọ ti ko ni kopa nínú ipade awọn olori orile-ede ti àjọ iṣọkan agbaye UNO niluu New York l'Amẹrika eyi ti wọn n pe ni UNGA.

Igbákejì ààrẹ Shettima lo lọ ṣoju Tinubu nibi ìpàdé náà.

Ki ni ofin sọ?

Igbesẹ ọhun bi ofin ṣe wi ni pe Aarẹ yoo kọ iwe si olori ile igbimọ Aṣofin Agba ati Abẹnugan ile igbimọ aṣoju, ti yoo fi kede ai le ṣiṣẹ to gba lasiko naa fun wọn.

Lẹyin eyi ni Igbakeji Aarẹ yoo si bẹrẹ iṣẹ naa gẹgẹ bii ẹni to n delé de Aarẹ titi ti yoo fi pada si ẹnu iṣẹ rẹ.

Abala naa tẹsiwaju, pe bi Aarẹ ko ba fi iru iwe bẹẹ ṣọwọ titi ti ọjọ mọkanlelogun fi pe, ile igbimọ aṣofin agba yoo gbe iṣẹ naa le Igbakeji aarẹ lọwọ lati maa ṣe e lọ.

Amọ ni ti Aarẹ Bola Tinubu to rin irinajo yii, ohun ti awọn alẹnulọrọ n sọ ni pe Aarẹ ko fi iwe kankan silẹ bi ofin ṣe wi.

Bakan naa ni wọn si n sọ pe ile igbimọ mejeeji paapaa ko gbe igbesẹ to yẹ nipa fifa iṣẹ Aarẹ le Igbakeji rẹ lọwọ bo ṣe yẹ.

Tẹ o ba gbagbe, Aarẹ Tinubu kuro ni Naijiria lọgbọnjọ oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, ileeṣẹ rẹ si tun kede lọjọ Aje pe afikun ti ba iye ọjọ ti Aarẹ yoo lo lajo, wọn lo di opin ọsẹ ko too de si Naijiria bayii