Ọlọ́run kò ní gba ẹ̀sìn yín tí ẹ bá fi owó ìlú tí ẹ jí kó rán àwọn èèyàn lọ sí Hajj tàbí Jerusalem - Sultan Sokoto

Sultan ilu Sokoto, Alhaji Saad Abubakar we lawani funfun, o n woke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Sultan ilu Sokoto, Alhaji Abubakar Kẹta ti ṣekilọ fawọn oloṣelu atawọn to di ipo oṣelu mu lati ye fi owo ilu ran awọn eeyan lọ si Mecca tabi Jerusalem pẹlu owo ilu ti wọn ji ko, ki wọn maa reti iyọnu Ọlọrun.

Abubakar sọ pe Ọlọrun kii gba ọọrẹ to kun fun iwa aitọ ati ajẹbanu.

Sultan ṣekilọ yii nibi ipade ajọ to n ri si ọpọ ẹsin to wa ni Naijiria iyẹn Nigeria Inter-Religious Council, NIREC to waye ni ilu Abuja, lọjọru.

O tẹmpẹlẹmọ pe awọn olori ẹsin ni Naijiria gbọdọ fimọ ṣọkan, ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu ajọ to n gbogunti iwa ajẹbanu lojuna ati fopin si iwa ibajẹ ni Naijiria.

"Gbogbo wa, gẹgẹ bi olori ẹsin gbọdọ gbogunti iwa ibajẹ nitori Ọlọrun funra rẹ ko fẹran iwa ajẹbanu.

"Eeyan ko le ji owo ilu ko lati fi ran awọn eeyan lọ si Jerusalem tabi Mecca ko maa reti pe Ọlọrun maa gba a gẹgẹ bi iwa rere lọwọ oun.

Bakan naa lo rọ ajọ to n gbogunti iwa ajẹbanu ni Naijiria, iyẹn Economic and Financial Crime Commission, EFCC lati fiya ẹnikẹni ti iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori lai fi ẹsin tabi ipo oṣelu wọn ṣe.

Sultan tun rọ EFCC lati maa ṣe iṣẹ wọn bo ṣe tọ lai tọwọ oṣelu tabi ẹsin bọ ọ, ki wọn si ma gba oloṣelu kankan laye lati toju bọ iṣẹ wọn.

O fi kun pe ṣiṣe ipade awọn olori ẹsin bayii ṣe Pataki fun alaafia ati iṣọkan laaarin awọn musulumi ati ọmọlẹyin Kristi.

O wa ṣekilọ fawọn olori ẹsin lati mọ ohun ti wọn yoo maa sọ nigba ti wọn ba n ṣe waasii tabi iwaaasu lori pẹpẹ paapaa lasiko oṣelu, to si parọwa si wọn lati maa gbadura fawọn olori orilẹ ede dipo lilo aaye lati fi sọrọ to le da ilu ru.

Ẹ yé da owó ọọrẹ, zakat pọ̀ mọ́ owó o yín - Alága EFCC

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ rẹ, alaga ajọ EFCC, Olanipekun Olukoyede ṣekilọ fawọn olori ẹsin lati ye sọ owo ijọ, owo ọrẹ ati ati saka ti awọn eeyan n da di owo ara wọn tabi fi ṣowo ti wọn.

Olukoyede ni iwa ọdaran ni iwa bẹẹ to ni ijiya labẹ ofin, to si rọ awọn ile ijọsin to fi mọ mọṣalaṣi ati ṣọọṣi lati gbe ilana to maa dena awọn eeyan lati maa ko owo ijọ si apo ara wọn.

O woye pe niṣe lo yẹ kawọn olori ẹsin jẹ awokọṣe fun awọn ti wọn n dari wọn, to si yẹ ki wọn maa lewaju ninu gbigbogunti iwa ajẹbanu.

Alaga EFCC naa ṣalaye pe niṣe ni wọn maa n fi orukọ ijọ ẹsin silẹ bii ajọ ti kii jẹ ere, to si ni gbogbo owo to ba n wọle si apo ijọ bẹẹ lo yẹ ko maa wa ninu akoto owo ti wọn ba ṣi fun-un, ki wọn si maa lo o fun ohun ti wọn ba tori rẹ da a.

"Ẹ ye da owo ijọ papọ mọ owo yin, ko si ohun to buru ti ẹ ba n ṣe owo mii yatọ si jijẹ olori ẹsin ṣugbọn ẹ ma da owo ijọ papọ, ohun ti ko dara ni."

O tun gba awọn olori ẹsin to ba ni owo ti wọn n ṣe laye ọtọ lati ṣi akoto owo fun okoowo wọn lọtọ yatọ si ti mọṣalaṣi tabi ti ile ijọsin wọn.

O fi kun pe ọpọ iwadii awọn lo fidi rẹ mulẹ pe niṣe ni awọn olori ẹsin to wa ni ajọ to n ri si eto irinna lọ si ilẹ mimọ ninu ẹsin mejeeji n ko ọpọlọpọ owo to wa fun ajọ naa jẹ.

O tẹsiwaju pe bi o tilẹ jẹ pe EFCC le ṣewadii, ki wọn si fiya jẹ ẹnikeni to ba n huwa ajẹbanu, o ni awọn olori ẹsin ni anfaani lati jẹ ki awọn eeyan awujọ hu iwa to tọ nipa iwaasu ati iṣe wọn.

O ni oun nigbagbọ pe awọn olori ẹsin le kopa to loorin lori igbogunti iwa ajẹbanu ti Naijiria gunle nipasẹ gbigbe igbe aye ododo, ki wọn si maa ṣekilọ lori kiko ọrọ jọ lai ni iṣẹ gid ikan pato lọwọ.