A máa ri pé iná ìjọba dúró dédé ju ti àtẹ̀yìnwá lọ tí a bá wọlé sáà kejì – Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ Tinubu fa ọwọ gbogbo awọn oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC soke nibi ipolongo ibo Aarẹ fun saa keji to waye niluu Ibadan.
Nigba ti Aarẹ Tinubu n sọrọ nibi ipolongo naa to waye ni gbọngan Mapo niluu Ibadan, o ni "Awọn gomina ti ẹ maa dibo fun ree, emi yoo fi wọn han yin."
Lẹyin naa lo gbe ọwọ Sẹnetọ Sharafadeen Alli, oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣlu APC nipinlẹ Ọyọ soke.
Tinubu tun fa ọwọ Sẹnato Solomon Olamilekan Adeola, ti ọpọ eniyan n pe ni Yayi, oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, ati Obafemi Hamzat to n dije du ipo gomina nipinlẹ Eko.
Nigba to n sọrọ, Aarẹ Tinubu ni ki gbogbo awọn ero to wa gbadege Mapo ti ipolongo naa ti n waye duro isẹju kan fun gbogbo awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ori omi to danu ni ipinlẹ Bayesa.
Lẹyin naa lo ba mọlẹbi gbogbo awọn awọn ti iṣẹlẹ naa kan kẹdun.
O fi kun pe oun maa tẹsiwaju lati ri pe ina mọnamọna duro dede ni Naijiria ju ti atẹyinwa lọ nitori minisita to n ri si ọrọ ina mọnamọna lọwọ, Oloye Tegbe n gbiyanju agbara rẹ.
Leyin naa ni Aarẹ ṣeleri atilẹyin fun gbogbo awọn oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC fun atilẹyin, o tun ni gbogbo ọmọ Naijiria gbọdọ dibo fun ẹgbẹ oṣelu APC lati oke titi de isalẹ.
Lara awọn peju sibi eto naa ni aya gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, iyaafin Florence Ajimobi, sẹnetọ Fatai Burahi, Adebajo Adeola, Olasunkanmi Tegbe, Opeyemi Bamidele, Ademola Adeleke, ogagun Olonisakin, Adams Oshiomole ati bẹẹ bẹẹ lọ.

























