Ipa tí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lítà bẹntiróòlù tíjọba ní káwọn alágbàtà epo mẹ́fà kó wọlé yóò ní lórí ọmọ Naijiria

Obinrin kan n ta epo sinu ọkọ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti fun ileeṣẹ epo rọbi mẹfa laṣẹ lati ko ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lita epo wọle lati ilẹ okeere fun oṣu mẹrin to kẹyin ọdun 2026 yii.

Igbesẹ ajọ NMDPRA to n mojuto ẹka epo rọbi ni Naijiria yii fi han pe orilẹede Naijiria yoo si maa lo epo ti wọn n fọ lorilẹede yii ati nilẹ okeere ti ọdun yii yoo fi pari.

Awọn ileeṣẹ alagbata epo ti ijọba fun laṣẹ naa ni Matrix Energy, AA Rano, AYM Shafa, NIPCO, Pinnacle Oil ati Bono Energy.

Awọn mẹfa yii naa ni wọn ti n jẹ anfaani kiko epo bẹntiroolu wọle lati ilẹ okeere lati ibẹrẹ ọdun yii titi di akoko yii.

Ti ẹ o ba gbagbe, ijọba fawọn alagbata epo yii laṣẹ lati ko epo 180,000 ''tonnes'' wọle laarin oṣu mẹta akọkọ ninu ọdun 2026 ti a wa yii.

Bakan naa ni wọn tun ko epo 720,000 ''tonnes'' wọle laarin oṣu Kẹrin si oṣu Kẹfa.

Awọn ileeṣẹ alagbata epo mẹfa yii tun wa lara awọn ileeṣẹ to tun ko epo wọle si Naijiria laarin oṣu Keje si oṣu Kẹsan an ti a wa yii.

Ni bayii, awọn ileeṣẹ alagbata epo mẹfa yii naa tun ni ijọba ti fun laṣẹ bayii lati ko epo 830,000MT wọle lati asiko yii ti yoo fi di asiko ọdun Keresimesi.

Igbesẹ yii waye pẹlu bi ileeṣẹ ifọpo rọbi Dangote ti gbooro si i lati maa pese epo fawọn ọmọ Naijiria.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ifọporọbi Dangote ti gbe ajọ NMDPRA lọ si ile ẹjọ giga apapọ lori bi o ṣe n fawọn alagbata epo laṣẹ lati maa ko epo wọle lati ilẹ okeere nigba ti ileeṣẹ ifọpo Dangote lagbara lati pese epo tawọn ọmọ Naijiria nilo.

Ọjọ keje oṣu Kẹwaa to n bọ ni ile ẹjọ yoo bẹrẹ igbẹjọ lori ẹjọ ọhun.

Ni bayii, iwọn epo tawọn alagbata naa fẹ ko wọle bayii pọ ju eyi ti wọn ti ko wọle lọ tẹlẹ.

Ohun ti eyi tumọ si ni pe epo yoo to lati ra fun araalu papaa julọ lasiko ọdun ninu oṣu Kejila.

Amọ, Dangote duro lori ẹsẹ rẹ pe ileeṣẹ ifọpo oun lagbara lati pese epo ti gbogbo ọmọ Naijiria nilo.