Àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn lórí ìpànìyàn lemọ́lemọ́ tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Osun

Awọn ọdọ ni ipinlẹ ti ṣe iwọde ifẹhonuhan lati fi itara han lori ipaniyan to n waye ni ipinlẹ naa.
Iwọde yii lo n waye lẹyin iku Olalekan Oyeyemi ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Emir Ajagungbade ni garaaji Mayfair ni ilu Ile-Ife, ipinlẹ Osun ni ọjọ Aiku ọjọ Kẹtala Oṣu Kẹsan-an ọdun yii ni.
Yatọ si Ajagungbade, awọn ọlọpaa tun kede pe awọn ṣawari oku ọkunrin mii ninu garaaji naa ni ọjọ keji, ti wọn si fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan lo tun farapa nibi ikọlu to waye ọhun.
Ohun ti wọn ni o fa ikọlu naa da lori gbigba akoso garaaji naa eyi ti wọn lo ṣokunfa ifanfa laaarin awọn igun to n ṣakoso garaaji.
Ṣaaju eto idibo sipo gomina ni ipaniyan waye lọkan-o-jọkan eyi to mu ọpọ ẹmi awọn ọdọ lọ, ti gomina Ademola Adeleke si ke gbajare sawọn ọlọpaa lati ji giri si ojuṣe wọn, ki wọn fopin si ipenija aabo to n waye naa.
Ohun ti ọpọ eeyan ro ni pe gbogbo ipaniyan yii maa di ohun igbagbe nigba ti eto idibo ba pari ṣugbọn kaka ki o dẹ lati lara ọmọ iya ajẹ o n fi ojoojumọ peleke si ni.
Eyi lo mu ki awọn ọdọ jade lati fi ẹhonu wọn han lori ipenija yii.
Nigba to n ba BBC sọrọ, ọkan lara awọn oluwọde ti wọn ṣe iwọde naa ni ilu Ilesa sọ pe o jọ pe aṣiri awọn oloṣelu to n ṣe agbatẹru awọn janduku lati maa da ilu ru ti n foju han bayii.
Destiny woye pe awọn ipaniyan to waye ṣaaju idibo lo mu ki awọn eeyan kan maa pariwo pe opin gbọdọ deba ipenija naa.
O ni idi tawọn ṣe n ṣe iwọde naa ko ju wi pe awọn n fẹ ki opin de ba ipaniyan, tawọn ko si fẹ kawọn oloṣelu maa lo awọn janduku lati fi maa gbẹmi awọn eeyan ni ipinlẹ Osun.

O wa rọ ijọba apapọ atawọn agbofinro lati tete ji giri si ojuṣe wọn nitori inu fu aya fu ni ọpọ awọn olugbe ipinlẹ Osun fi n gbe bayii, ti wọn ko le sun di oju mejeeji mọ.
Bakan naa lo rọ awọn agbofinro ṣawari awọn to lọwọ ninu iku Emir Ajagungbade to waye ni Ilu Ile-ife lọjọ Aiku.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi ti wa rọ awọn eeyan ipinlẹ lati ṣe suuru fun wọn ki wọn fi le ṣe iṣẹ wọn bo ṣe to ati bo ṣe yẹ.
Ojelabi rọ gbogbo awọn eeyan lati maa wa ni oju ni alakan fi sọri ni gbogbo igba, ki wọn si maa fi awọn iṣẹlẹ to mu ifura dani ni agbegbe wọn to awọn agbofinro leti lẹyẹ o sọka.
Wo ohun tó fa làásìgbò tó bẹ́ sílẹ̀ ní gáráàjì Mayfair tó ṣokùnfà ikú Ajagungbade àti ẹlòmíì ni Ile Ifẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọ pe awọn tun ti ṣawari oku miran ni agbegbe garaaji Mayfair to wa niluu Ile-Ife, nibi ti ikọlu ibọn ti waye.
Ọlọpaa sọ pe oku ti awọn ti ṣawari ni garaaji naa lo ti di meji bayii, iyẹn nibi ti ikọlu ti waye lọjọ Aiku, ọsẹ yii.
Nibi ikọlu to waye ni garaaji Mayfair naa ni wọn ti yinbọn pa ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ naa, Olalekan Oyeymi, ẹni tọpọ mọ si Emir Ajagungbade.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, aawọ kan lo waye laaarin Emir Ajagungbade ati awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ NURTW, igun miran ni garaaji ọhun, to fi di pe ọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna.
Nibi ti wọn ti n jijakadi la gbọ awọn igun keji ti wọn ni ẹni to n jẹ Sibi ni olori wọn fa ibọn yọ lojiji, ti wọn si bẹrẹ sii yin in.
Ibọn ọhun lo pada ba Emir Ajagungbade, to si gbabẹ ku loju ẹsẹ.
Ninu fọnran ibi iṣẹlẹ naa to n kaakiri ori ayelujara, ni a ti ri Emir Ajagungbade to doju bolẹ ninu agbara ẹjẹ.
Ọjọ Aje, ana ni wọn sinku Emir Ajagungbade ni ilana ibilẹ ni ile rẹ to wa ladugbo Agunbẹlewo niluu Osogbo.
Atẹjade ti Gomina Ademola Adeleke fidi rẹ mulẹ, to si ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun, iyẹn ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed fi sita.
Ninu atẹjade naa ni gomina ti rọ Kọmiṣana ọlọpaa, Ibrahim Zungura lati bẹrẹ iwadii, ki wọn si rọwọ to gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu ọhun.
Bi wọn ṣe pa Emir ni wọn sọ pe ko ṣẹyin bi wọn ṣe sọ pe awọn kan n gbe igbesẹ lati yan an gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awakọ NURTW nipinlẹ Osun.
Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, agbẹnusọ ọlọpaa, Abiodun Ojelabi sọ pe awọn ti ju agadagodo sẹnu ọna garaaji naa, ti gbogbo iṣẹ si ti duro nibẹ, fun igba diẹ.
Ojelabi sọ pe awọn gbe igbesẹ naa lẹyn aṣẹ ti gomina pa wi pe ki iṣẹ duro ni garaaji ọhun.
"Gomina ti pinnu pe iṣẹ kankan ko gbọdọ lọ mọ ninu garaaji yii. Ko si iṣẹ to n lọ lọwọ mọ. Ọlọpaa tun ti ṣawari oku miran, a si ti gbe e lọ si mọṣuari," Ojelabi sọ bẹẹ.
O sọ siwaju pe, awọn ti "gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n ri si iwadii ọran, SCID fun iwadii kikun. Gbogbo awọn ti wọn darukọ patapata lori iṣẹlẹ ọhun ni ki wọn lọ jọwọ ara wọn ni ẹk ileeṣẹ ọlọpaa to ba sunmọ wọn, dipo ki wọn lọ sori ayelujara lati gbe ara wọn nija.
"Ọga ọlọpaa ti ṣeleri wi pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu yii ni ọwọ yoo tẹ, ti wọn yoo si foju winna ofin, lai nii ṣe pẹlu iru ẹni ti wọn ba jẹ."



























