Ní ti owó, mi ò lówó lọ́wọ́ rárá, mo fúyẹ́ lóòótọ́, ṣùgbọ́n… - Oriyomi Hamzat

Oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Oriyomi Hamzat ti sọ pe loootọ loun ko ni owo lọwọ bi awọn gbajumọ oloṣelu nilẹ Naijiria, ṣugbọn sibẹ, o loun nigbagbọ wi pe oun yoo bori idibo gomina to n bọ lọdun 2027.
Hamzat to jẹ gbajugbaja sọrọsọrọ ati oludasilẹ ileeṣẹ redi agidigbo niluu Ibadan lo sọ bẹẹ fun BBC News Yoruba, nibi ifọrọwerọ to ṣe laipẹ yii.
Agba sọrọsọrọ naa sọ pe bi awọn araalu ba ṣetan lati yan oun si ipo, ko sẹni to le da oun duro.
O sọ siwaju pe oun nigbagbọ ninu iwa ọmọluabi toun ni, eyi si loun ro pe o jẹ ki awọn araalu nifẹ oun, lati pe oun fun ipo gomina.
Ọkunrin naa fidi rẹ mulẹ pe awọn ara ati olugbe ipinlẹ Oyo ni wọn ranṣẹ pe oun lati du ipo gomina, kii ṣe erongba oun, to si ni gbogbo awọn to n sọ pe Oyo n tan oun, ni wọn n tan ara wọn jẹ.
"Mi o lowo, gbogbo igba ni mo maa n sọ pe mi o lowo lati tan kangbọn pẹlu wọn, mi o lowo, ṣugbọn ti araalu ba ṣetan lati yan mi, awọn araalu naa mọ pe mi o lowo," Oriyomi Hamzat sọ bẹẹ fun BBC.
"Ẹni to ba ti ni igbagbọ wi pe owo ni yoo ṣe gbogbo nnkan, funra rẹ gan, yoo maa wo o pe owo ni oun yoo fi ra iwe ti yoo gbe oun wọ paradise ni.
"Ṣugbọn ẹni to ba ti ni igbagbọ ninu iwa ọmọluabi, yoo mura si iwa ọmọluabi.
"To ba jẹ pe loootọ ni Oyo n pe mi, awọn to n sọ pe Oyo n tan mi, awọn gan-an ni wọn n tan ara wọn, awọn naa si mọ lẹmi ara wọn pe awọn n tan ara wọn ni. Nitori ti ko ba ri bẹẹ, ko yẹ ki wọn reran ri mi rara," Oriyomi ṣalaye.
"Nígbà tí àsìkò bá tó, aráàlú yóò dìde"
Oriyomi Hamzat sọ siwaju pe oun duro lori ọrọ oloogbe Obafemi Awolowo to sọ pe nigba ti asiko ba to, awọn araalu yoo gba iṣakoso ijọba.
O ni ohun ti awọn araalu ri lara oun, lo fa pipe ti wọn pe oun lati jade du ipo gomina.
"Ni ti owo, mi o lowo lọwọ rara – ni ti pe mo ṣee ri, mi o ṣee ri – ko to wa di pe awọn eeyan n tẹle mi, wọn n fi owo ra aṣọ ti wọn n fun awọn eeyan lọfẹ, o ni lati jẹ pe wọn ri nnkankan ninu mi.
"Ti akoko ba to, gẹgẹ bi ohun ti Awolowo sọ, o ni araalu yoo dide, wọn yoo si gba ijọba, igba yẹn ni wọn yoo to lẹnu pe ilu awọn ni wọn wa.
"Ti asiko ba ti to, ti asiko ko ba si tii to, gbogbo rẹ wa lọwọ Ọlọrun. Bi eeyan ba wo bi David ṣe ri niwaju Goliath, yoo sọ pe David fẹẹ lọ pa ara rẹ ni, ṣugbọn nigba ti Ọlọrun ṣetan, o ja fun David, o si fi ẹyin Golliath balẹ," sọrọsọrọ naa ṣalaye.
"Mo fúyẹ́ lóòótọ́, ṣùgbọ́n…"
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oun fuyẹ gidi nidi oṣelu, ṣugbọn to sọ pe oun di mọ ọba to tobi
"Mo fuyẹ loootọ, ṣugbọn mo di mọ ọba to tobi – mi o mọ oṣelu, ibi eto idibo abẹle ni wọn ti maa n ba aye oloṣelu jẹ, awa naa mọ bẹẹ, ṣugbọn Ọlọrun ju wọn lọ.
"Ẹni ti wọn n darukọ pe mo ba fa fanfa, oun kọ ni mo ba fa a, oun naa si mọ pe oun kọ. Agbara ko gbọdọ ri tikẹẹti gba, oun lo ba mi fa a.
NIgba t imo si jẹ ọlẹ, ewo ni abọrọ ma ri tikẹẹti gba, nigba to jẹ Ọlọrun lo n fun eeyan ni gbogbo nnkan. Ọlọrun ni, kii ṣe ọgbọn wa," Hamzat sọ bẹẹ.






