Ìjọba ṣèkìlọ̀ lórí jíjẹ ẹran ìgbé bí ààrùn 'anthrax' ṣe gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ ẹranko

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn alaṣẹ ni orilẹ ede Zambia ti ṣekilọ fawọn eeyan lati yago fun jijẹ ẹran igbo to fi mọ erin, erinmilokun, ọọni, ẹfọn ati bẹẹ bẹẹ lọ fun igba kan na.
Ikilọ lo n waye latari bi ajakalẹ aarun anthrax ṣe gbilẹ ni orilẹ ede naa.
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni orilẹ ede naa sọ pe eeyan mejila lo ti lugbadi aarun naa lopin ọsẹ lẹyin ti wọn je ẹran igbo kan ni agbegbe Munyamadzi River.
Awọn alaṣẹ tun rọ awọn eeyan lati jina si jijẹ ẹran igbo tabi ẹran igbe to ba jade laye funra wọn lati mọ ohun to pa wọn, ki wọn si maa fi iru oku ẹran bẹẹ to awọn alaṣẹ leti.
Bakan naa ni wọn tun pe fun idaduro igbẹ didẹ ni agbegbe naa titi ti wọn fi maa mọ ibi ti ọwọja aarun naa de duro bayii, ki wọn si mọ bi o ṣe lagbara si.
Awọn alaṣẹ ko i tii le sọ ibi ti aarun naa ti tan de bayii, ti iwadii ati ayẹwo si ti n lọ lọwọ.
Aarun Anthrax jẹ aarun to maa n gbilẹ ni Zambia amọ kii saba mu ẹmi eeyan lọ.
Ni ọdun 2023, eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn sọwọ aarun anthrax bi o ṣe tan wọn ẹkun mẹsan-an ninu mẹwaa to wa lorilẹ ede naa.
Ọdun 2011 ni aarun anthrax to gbilẹ pupọ kọkọ waye ni ni Zambia nibi ti eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹta (500) ti lugbadi rẹ, ti eeyan marun-un si padanu wọn lẹyin ti wọn jẹ ẹran erinmilokun to ni aarun naa.
Ajakalẹ aarun yii to ṣẹṣẹ n gbilẹ bayii lo n waye ni agbegbe Munyamadzi Game Management Area ni ẹkun Muchiga, ti ajọ to n mojuto iṣẹlẹ aburu ni Zambia si sọ pe erinmilokun mẹrindinlaaadọta (46), erin mẹjọ (8), ẹfọn marun-un (5), ọọni kan (1) lo ti jade laye lati inu oṣu Keje to ti bẹrẹ.
Alakooso ajọ naa, Norman Chipakupaku sọ pe ohun to ṣeni laaanu ni pe niṣe ni awọn eeyan n jẹ oku awọn ẹranko naa nitori ohun ti wọn gbarale gẹgẹ bi ounjẹ niyẹn.
Ko i tii si akọọlẹ iku eeyan kankan, ti awọn mejila to lugbadi aisan naa si ti n gba itọju nile iwosan.
Ki ni anthrax?
Kokoro aifojuri kan ti wọn n pe ni Bacillus anthracis lo maa n ṣokunfa aarun anthrax.
O jẹ sẹẹli to le fara pamọ sinu iho fun igba pipẹ to si maa n pọ si funra rẹ ko to di pe o wọ ara ẹranko lati imu tabi egbo.
Awọn ẹranko to maa n jẹ ewe lo saba maa kọlu to si le ṣokunfa iku ojiji fun wọn.
Eeyan le ko aarun lati ẹranko nigba ti eeyan ba jẹ ẹran to b ani aarun naa.
Awọn alaṣẹ ti wa rọ awọn eeyan orilẹ Zambia lati ma jẹ, pin tabi ta ẹran ẹranko kankan to ba ṣadede jade laye tabi ti wọn ba funra si pe aarun anthrax lo pa a.
Bakan naa ni wọn tun ṣekilọ fawọn eeyan lati ye fọwọ kan awọn ẹranko inu igbo tabi ẹran igbẹ fun igba kan na.





























