Èèyàn mẹ́fà kú, 130 di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi dànù ní Indonesia

Ọkọ oju omi to danu ni Indonesia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O kere tan, eeyan mẹfa ti jade laye, nigba ti awọn 130 mii di awati lẹyin ti ọkọ oju omi kan danu lori okun Java, ni Indonesia.

Eeyan 107 ni wọn ti doola ninu ijamba ọhun bayii lẹyin ti ọkọ oju omi Virgo Transport8 naa danu.

Ṣaaju iṣẹlẹ naa ni ọkọ oju omi ọhun ti n rinrinajo bọ lati Surabaya to si n lọ si agbegbe Banjarmasin ti wọn ko si gbọ nnkankan lati ọdọ rẹ mọ.

Ijọba orilẹede naa ti fi ọkọ ẹlikọpita atawọn ọkọ oju omi mii, to fi mọ adoola ẹmi ti wọn to 280 ṣọwọ si agbegbe naa lati ṣawaru awọn ti iṣẹlẹ naa kan.

Eeyan 213 lo wa ninu ọkọ ọhun, yatọ si awọn oṣiṣẹ ọgbọn to wa ninu rẹ.

Aago mẹwa abọ aarọ ni ọkọ naa gbera ni Surabaya pẹlu ireti pe yoo de ebute Banjarmasin ni aago meji ọsan.

Amọ nigba ti yoo di aago meji kọja iṣẹju mẹwaa ni wọn gba ipe pajawiri pe ọkọ naa ti danu.

Akojọpọ awọn adoola ẹmi ati ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi Indonesia lo wa nibẹ lati doola awọn eeyan nibẹ.

Ọkunrin ti mọlẹbi rẹ mẹjọ wa ninu ọkọ ọhun, Rusmilawati, sọ fun akọroyin BBC pe baalu ni awọn mọlẹbi oun ọhun gbe wọle amọ wọn fẹ ni iriri ọkọ oju omi lo jẹ ki wọn lọ wọ inu rẹ.

O ni "Baalu ni wọn gun wa amọ wọn fẹ ni iriri wiwọ ọkọ oju omi lo jẹ ki wọn pinnu lati lọ wọ ọkọ naa pada.

Titi di asiko to n ba BBC sọrọ, Rusmilawati ni oun ko tii gbọ nnkankan lati ọdọ wọn tabi iroyin nipa ipo ti wọn wa.

Erekusu to le ni 17,000 lo wa ni Indonesia, to n tumọ si pe lọpọ igba lawọn eeyan maa n lo ọkọ oju omi lati rekọja lati awọn agbegbe kan lọ si omiran.

Laarin ọdun 2020 si ọdun 2026 yii, ijamba ọkọ oju omi ọgọrun ati mọkanla lo ti waye nibẹ.

Loṣu to kọja ni ina sọ lara ọkọ oju omi kan ni erekusu Madura, eeyan marun un lo ba iṣẹlẹ naa lọ.