Adeleke gbẹ́sẹ̀ lé ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò l‘Osun, pàṣẹ fún ọlọ́pàá láti ṣoro fún ẹni tó bá tàpá ṣófin

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Lojuna lati fi opin si gbogbo rogbodiyan ati wahala to n fi ojoojumọ ṣẹlẹ nipinlẹ Osun, Gomina Ademola Adeleke ti paṣẹ pe ki gbogbo ẹgbẹ awakọ ati gbogbo awọn to nii ṣe pẹlu tikẹẹti jija lọ rọkunnile.
Gomina Adeleke sọ pe ẹgbẹ kankan to nii ṣe pẹlu jija tikẹẹti f'awọn onimọto, ọlọkada ati awọn miran kaakiri gbogbo garaaji to wa nipinlẹ Osun ni ki wọn da iṣẹ duro.
Ọjọbọ, ọsẹ yii ni Gomina Adeleke gbe aṣẹ naa kalẹ, lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn olori eleto aabo nipinlẹ naa.
"Agbekalẹ ofin yii lo wa lati da alaafia pada si gbogbo awọn garaaji ọkọ ati fifi opin si jija tikẹẹti"
Ninu atẹjade ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ araalu, Kolapo Alimi fi ssita lẹyin ipade ọhun, gomina paṣẹ fun awọn eleto aabo lati fi kele ofin gbe ẹnikẹni to ba tapa si aṣẹ, nipa pipe ara rẹ ni olori tabi ọmọ ẹgbẹ awakọ.
O ni agbekalẹ yii ni lati da alaafia pada si gbogbo awọn garaaji ọkọ ati fifi poin si jija tikẹẹti.
"Gomina ti paṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ileeṣẹ eleto aabo to ku lati fi opin si gbogbo iṣẹ ẹgbẹ awakọ NURTW kaakiri awọn garaaji to wa nipinlẹ yii. Aṣẹ yii ni lati fi opin si gbogbo gbigba oniruuru owo lawọn garaaji," atẹjade naa sọ bẹẹ.
"Mo n fi asiko yii pa a laṣẹ fun awọn ọlọpaa ati awọn ileeṣẹ eleto aabo ni aṣẹ dawọ gbogbo iṣẹ ẹgbẹ awọn awakọ duro kaakiri garaaji. Nko sọ pe ki ẹ tilẹkun awọn agraaji pa o, ṣugbọn ẹ ko gbọdọ gba ẹnikẹni laaye lati ṣiṣẹ lorukọ ẹgbẹ awakọ.
"Ẹnikẹni tọwọ ba tẹ wi pe o tapa si aṣẹ yii ni ki wọn fọwọ ṣikun ofin gbe lori ẹsun dida alaafia ilu laamu," gomina sọ bẹẹ.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC Osun tako àbá Adeleke láti ṣàtúnṣe sí afárá tí Oyetola kọ́

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke
Wayi o, ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ipinlẹ Osun ti tako aba gomina Ademola Adeleke lati ṣatunṣe si afara Olaiya to wa niluu Osogbo.
Ninu atẹjade kan ti Adeleke fi lede lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed, lo ti ni oun kọminu lori ipo ti afara naa wa, o si yẹ ki wọn ṣatunṣẹ rẹ ki wọn to ṣi afara Okefia ti ijọba oun n kọ lọwọ.
O ni "Ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ iṣẹ gbọdọ ri si ọrọ afara Olaiya yii ni kiakia. Ẹ jẹ ka ṣatunsẹ rẹ. Ara dukia ipinlẹ naa ni. A gbọdọ ri pe a ṣe daadaa. Eyii si gbọdọ di ṣiṣẹ ko to di pe a ṣi afara Okefia.
"Mo gbagbọ ninu itẹswauju iṣejọba. Gbogbo iṣẹ ti ijọba wa jogun lọwọ ijọba to kọja ni a n pari lọ. A si gbọdọ maa ṣe atunṣe si gbogbo iṣẹ ti ijọba to kọja ṣe pari."
A ko faramọ igbesẹ yii, Adeleke kan n wa ijẹ fun awọn ọrẹ rẹ ni – APC
Amọ ẹgbẹ oṣelu APC ti kọ aba gomina Adeleke fun atunṣe afara naa lẹyin ti wọn ni digbi ni afara ọhun wa ti ko si nilo atunṣe kankan.
Ninu atẹjade ti agbẹnisọ APC, Kola Olabisi fi lede, o ni niṣe ni Adeleke fẹ mọọmọ ba iṣẹ ti gomina ana, Adegboyega Oyetola, ti ṣi silẹ jẹ.
APC sọ pe "A ri erongba lati ṣatunṣe si afara naa ti ko si nnkankan to ṣe e gẹgẹ bii ọna ti Adeleke fẹ fi wa ijẹ fun awọn ẹmẹwa rẹ ninu oṣelu nigba ti ọpọ iṣẹ wa nilẹ to yẹ ko gbajumọ.
"Gomina Adeleke gbodọ ṣalaye eredi to fi fẹ fi owo ilu ṣowo lori afara Olaiya ti ko si nnkan to ṣe e."
Lẹyin naa lo rọ gbogbo awọn ti ọrọ kan nipinlẹ Osun lati tako igbesẹ Adeleke fun atunṣe afara naa ni gbogbo ọna.
Gẹgẹ bi APC ṣe sọ, ko tii si akọṣẹmọṣẹ kankan to tii sọ pe afara ọhun ti n dagẹgẹ to si nilo atunṣẹ lati ọdun mẹrin ti wọn ti kọ.
Gbasgbos tuntun yii n waye laarin Adeleke ati APC lẹyin abẹwo ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Olatunji Disu si ipinlẹ naa.
Nibi abẹwo naa ni Olatunji Disu ti sọ fun Adeleke pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Ibrahim Gotan, sọ fun oun pe ile ijọba Adeleke ni awọn janduku oṣelu fi n ṣe ibuba.
Amọ Adeleke kọ ẹsun naa, o tun fẹsu kan kọmiṣọna ọlọpaa pe oun gan ni ko ṣiṣẹ rẹ bii iṣẹ lẹyin to kọ lati fi ṣikun ofin gbe awọn janduku ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn n da Osun ru.





























