Àlàyé rèé lórí báwọn dókítà ṣe fi kíndìnrín ẹlẹ́dẹ̀ pààrọ̀ kíndìnrín ọkùnrin kan tí ó sì ṣiṣẹ́ lára rẹ̀ fún ọjọ́ 271

Oríṣun àwòrán, Massachusetts General Hospital
Awọn dokita kan lorilẹede Amẹrika ti fi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ kindinrin ọkunrin kan, eyi to ṣiṣẹ lara rẹ fun ọjọ 271 ti i ṣe oṣu mẹsan an gbako.
Eyi ni igba to pẹ julọ ti kindinrin ẹlẹdẹ yoo ṣiṣẹ lara eeyan ninu itan.
Tim Andrews sọ pe kindinrin ẹlẹdẹ yii fun oun ni igboya, ko si tun jẹ ki oun maa lọ fun itọju nile iwosan ni gbogbo igba.
Ikọ onimọ iṣegun naa nile iwosan Mass General Brigham Hospital l'Amẹrika sọ pe iṣẹ abẹ naa fi han pe awọn le fi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ fun eeyan titi ti iru ẹni bẹẹ yoo fi ri kindinrin eeyan bi tiẹ paarọ.
Amọ, lẹyin o rẹyin, kindinrin ẹlẹdẹ naa pada daṣẹ silẹ, Andrews si nilo ki wọn fi kindinrin eeyan paarọ kindinrin rẹ.
Awon dokita atawọn onimọ sayẹnsi ninu eto ilera ti n ṣe oriṣiiriṣii iwadii lati maa lo kindinrin ẹranko paarọ kindinrin eeyan tori bii kindinrin eeyan ṣe maa n wọn lati fi paarọ fun awọn to ba nilo rẹ.
Lorilẹede Amẹrika nikan, eeyan bii 100,000 ni wọn nilo ki wọn paarọ kindinrin wọn bayii, nigba ti awọn dokita maa n ṣiṣẹ abẹ fun eeyan 25,000 lọdọọdun lati paarọ kindinrin wọn.
Eeyan to le ni ẹgbẹrun un meje ni wọn nilo kindinrin mii lorilẹede UK lọwọ yii, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Kate Flock/Massachusetts General Hospital
Wọn sọ fun Andrews wi pe o le to ọdun meje ki ara rẹ to ya daadaa, amọ, ọdun marun un pere lawọn to ba n gbatọju kindinrin lasan an lai tii paarọ rẹ maa n lo.
''Mo si ni akoko diẹ…o bani lọkan jẹ gan an,'' Andrews lo sọ bẹẹ.
O ṣapejuwe fifi kindinrin ẹlẹdẹ paarọ kindinrin rẹ gẹgẹ bi nnkan idunnu.
Awọn dokita maa n lo kindinrin ẹlẹdẹ tori wọn ri i gẹgẹ bii ẹranko ti kindinrin rẹ le ba ti eeyan mu.
Amọ, dokita ko kan le ṣadeede yọ kindinrin ẹlẹdẹ ki o si fi sinu eeyan, ara eeyan yoo ri i bi alejo.
Idi niyii tawọn onimọ ijinlẹ fi ṣawari irufẹ ẹlẹdẹ Yucatan to jẹ akanda ẹlẹdẹ.
Awọn nnkan kan ti wa lara ẹlẹdẹ naa to le jẹ ki kindinrin rẹ ṣiṣẹ lara eeyan.
Andrews larun kindinrin lẹyin to ti kọkọ ni aisan itọ ṣuga lẹẹmeji, ti kindinrin rẹ mejeeji ko si ṣiṣẹ daadaa mọ.
Kindinrin ẹlẹdẹ ti wọn gbe sinu Andrews bẹrẹ sii ṣiṣẹ lẹsẹ kẹsẹ gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ninu iwe jọna The Lancet
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọriun ni Andrews i ṣe nigba ti wọn ṣiṣẹ abẹ fun un lati paarọ kindinrin rẹ lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kinni ọdun 2025.
Kindinrin ẹlẹdẹ ti wọn gbe sinu rẹ bẹrẹ sii ṣiṣẹ lẹsẹ kẹsẹ gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ninu iwe jọna The Lancet.
Kindinrin ẹlẹdẹ naa lo ọjọ 271 lara rẹ kawọn dokita to yọ ọ loṣu Kẹwaa.
Bayii ni Tim bẹrẹ sii gba itọju fun kindinrin fun ọjọ mejilelọgọrin ki ẹnikan to o fun un ni kindinrin loṣu Kinni ọdun yii.
Dokita Leonardo Riella lati ile iwosan Brigham and Women's Hospital's Center sọ pe aisi awọn eeyan to le maa fawọn to larun kindinrin ni kindinrin lati fi paarọ jẹ nnkan to nira.
Awọn ami kan kọkọ fara han pe ara Andrews fẹ kọ kindinrin ti wọn fi paarọ fun un, amọ, wọn fun un loogun to jẹ ki kindinrin naa pada ṣiṣẹ fun un.
Ṣugbọn lẹyin oṣu mẹfa, kindinrin naa bẹrẹ sii wu pẹlu ẹjẹ to wa ninu rẹ.
Awọn dokita ko le sọ pato nnkan to fa eleyii tori ko si ami wi pe ara rẹ kọ kindinrin naa.


























