Nǹkan mẹ́wàá ni mo ní àfojúsùn láti mójútó tí mo bá di gómìnà Osun - Najeem Salaam
Bi eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Osun ṣe n sunmọ etile naa ni awọn oludije to n dupo naa n sọ oniruuru ohun ti wọn ni lati ṣe ti wọn ba de ipo naa.
Ninu ifọrọwerọ yii, oludije lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Dokita Najeem Saleem ṣalaye awọn nnkan to ni lerongba lati ṣe ni ipinlẹ Osun to ba ni anfaani latoi de ipo gomina.
Salaam sọ fun BBC News Yoruba pe nnkan mẹwaa lo jẹ afojusun ti ijọba oun maa mojuto ti awọn eeyan ipinlẹ Osun ba dibo fun oun nibi eto idibo to maa waye lọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 gẹgẹ bi ajọ to n mojuto eto idibo Naijiria, INEC ṣe la a kalẹ.
Salaam woye pe ọpọ nnkan lo wa ti ijọba kankan ko i tii mọwọba ni ipinlẹ Osun ti oun ni ajofusun lati ṣe ti oun ba depo gomina.
O sọ pe oun maa ṣaridaju rẹ pe ina mọnamọna ko ni ṣẹju mọ ni ipinlẹ Osun ti oun ba ni anfaani lati de ipo gomina.
O fi kun pe lara awọn erongba oun ni lati mu irugọgọ ba eto ọrọ aje nipa awọn iriri ti oun ti ni lẹka eto ọrọ aje toun si ni imọ pe afọwọfa lo maa n mu eto ọrọ aje dẹnu kọlẹ.
O ni oun gbagbọ pe eto agbẹ jẹ ọna kan gboogi ti ijọba fi le mu irugọgọ ba eto ọrọ aje eyi to ni o jẹ ọkan lara awọn afojusun ohun ti oun maa ṣe ti oun di gomina.

Lori awọn ọdọ, Salaam ṣeleri pe oun maa gba awọn ọdọ ti iye wọn ko din ni egbẹrun ogun (20,000) laaarin ọgọrun-un ọjọ ti oun ba kọkọ gba akoso ijọba.
Oludije naa sọ pe ainiṣẹ lọwọ awọn ọdọ wa lara ohun to n fa idi ti eto aabo Naijiria ṣe n mẹhẹ nitori ọwọ to ba dilẹ ni eṣu n ya lo.
O tun tẹsiwaju pe eto ẹyawo fun awọn obinrin ati imugbooro awọn ẹgbẹ alajẹṣẹku lati ṣe iranwọ fawọn eeyan ipinlẹ Osun ni oun maa mojuto laaarin ọdun kan ti oun ba gba akoso.
O wa rọ awọn eeyan lati la oju wọn silẹ, ki wọn dibo fun ẹni to ba wu wọn lọkan.
O ni awọn eeyan le gba owo ti wọn ba fi lọ wọn amọ ki wọn ma jẹ ẹ ki owo ṣe atọna ẹni ti wọn maa dibo fun, ki wọn gba owo amọ ẹni to ba wu wọn lọkan.




























