Obasanjo àti Osoba sọ òkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ìbò 2003, àṣírí ọ̀pọ̀ ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ tú àti ìdí táwọn gómínà AD ṣe pàdánù sọ́wọ́ PDP

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ tẹlẹ ri ni Naijiria, Olusegun Obasanjo ti fesi sawọn ọrọ ti gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Ogun, Olusegun Osoba sọ nipa awọn iṣẹlẹ to waye ṣaaju eto idibo ọdun 2003.
Obasanjo sọ pe oun ko tan ẹnikẹni jẹ tabi parọ fun ẹnikẹni tabi awọn adari ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy, AD lori idibo naa gẹgẹ bi Osoba ṣe sọ.
Ni ọdun 2018 ni Osoba ninu atẹjade kan ti sọ pe Obasanjo ṣe ẹtanjẹ fun gbogbo awọn gomina to wa labe ẹgbẹ oṣelu AD ni ẹkun guusu iwọ oorun Naijiria eyi to mu ki awọn padanu ipo awọn ninu idibo naa.
Amọ Obasanjo ti wa fesi lori awọn iṣẹlẹ to waye nigba naa nibi to ti ni igbakeji oun lasiko ọhun, Atiku Abubakar gbiyanju lati yọ oun nipo aare.
Aarẹ tẹlẹ ri naa sọ pe oun ko gba gbogbo ohun ti Osoba sọ nipa oun, ti oun ko si ni fi aaye gba ko pe oun ni ẹlẹtan nitori oun ko tan ẹnikeni jẹ.
O sọ pe Osoba ko mọ nipa ọpọlọpọ awọn iṣẹlẹ to waye lasiko naa, paapaa lori ọrọ oṣelu laaarin oun atawọn alaṣẹ ẹgbẹ Afenifere, ẹgbẹ oṣelu AD, to si ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ lo n ri si awọn iṣẹlẹ naa nigba naa.
Obasanjo sọ pe bi awọn gomina ẹgbẹ oṣelu AD naa ṣe padanu nibi eto idibo ọdun 2003 ko ṣẹyin ohun tawọn araalu n fẹ ati pe wọn ṣe ayipada esi ibo ni ipinlẹ kan pere ni PDP ko ṣe gba ipinlẹ naa.
O ni Osoba kọ lati polongo fun atundi ibo rẹ nigba naa, to si pada tọrọ aforiji fun iwa aifojudi to hu lọwọ awọn araalu rẹ lasiko tie to idibo ti n tẹnu bodo lọ nigba naa.
O fi kun pe awọn iwa ti awọn gomina naa hu lo jẹ ki wọn padanu eto idibo wọn, ki wọn si ma dẹbi iṣẹlẹ ọhun le oun lori.
"Miliọnu marun-un naira ni Atiku fun olori ile aṣojusofin lati bẹrẹ igbesẹ lati yọ mi nipo aarẹ"
Nigba to n sọrọ lori igbiyanju lati yọ oun nipo aarẹ, Obasanjo sọ pe igbakeji oun, Atiku Abubakar lo lọ lẹdi apopọ pelu olori ile aṣojuṣofin, Ghali Na'Abba lati yọ oun nipo aarẹ nitori erongba rẹ lati di aarẹ Naijiria.
Obasanjo fẹsun kan pe miliọnu marun-un naira ni Atiku fun Na'Abba nigba naa lati fi bẹrẹ igbesẹ lati yọ oun nipo lasiko ti oun ko si nile lọjọ Ẹti kan.
O ṣalaye pe olori oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ lori bi Atiku ṣe fun Na'Abba ni miliọnu marun-un naira naa to si gbọ nipa ohun ti wọn sọ pe ki wọn bẹrẹ igbesẹ lati yọ oun nipo, to ka gbogbo rẹ silẹ to si ṣalaye fun oun.
O fi kun pe oun ko kabaamọ gbogbo igbesẹ ti oun gbe nigba naa nitori oun ko ṣẹṣẹ kankan to le mu ile aṣofin yọ oun nipo bikoṣe pe igbakeji oun n wa gbogbo ọna lati di aarẹ ni tipatipa.
O tun fẹsun kan pe lẹyin ti erongba lati yọ oun nipo ko bọ si mọ, Atiku Abubakar tun mu erongba gba ọna ibomiran, to si bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pẹlu awọn gomina AD.
O ni lara awọn igbesẹ to gbe nigba naa ni lati lọ pẹlu Alex Ekwueme, ki Alex le gbe ijọba fun-un nigba ti wọn ba ti wa nipo fun ọdun mẹta tabi ko ri daju pe awọn gomina ẹgbẹ oṣelu AD ko ni alatako kankan lasiko ibọ ọdun 2003 ki wọn ba le ṣe tirẹ lẹyin ti wọn ba wọle tan.
"Gbogbo yin ohun ti Atiku sọ fun-un yin ti ko bae to iṣejọba awaarawa mu yii. To ba jẹ pe oun ti wọn sọ fun-un yin ni pe emi ni mo wa nidii erongba naa, irọ ni wọn pa fun-un.
"To ba jẹ pe nnkan ti wọn sọ fun-un yin niyẹn, ko si ẹni to gbero ninu yin lati kan si lati beere lọwọ mi abi nitori mi o ki n ṣe ọmọ ẹgbẹ Afenifere ati AD ni ko jẹ ki ẹ beere lọwọ mi."
"Mo kọ lati darapọ mọ AD nitori o jẹ ẹgbẹ oṣelu ẹya Yoruba nikan"
Nigba to n sọrọ lori awọn igbesẹ to waye leyin to kuro lọgba ẹwọn, Obasanjo ni oun to wu oun lati gbajumọ ni idile atawọn ọmọ oun ṣugbọn awọn eeyan lo w aba oun lati darapọ mo oṣelu, ki oun si dije dupo aarẹ.
Obasanjọ ni oun sọ fun awọn to wa ba oun sọrọ lati darapọ mọ oṣelu to jẹ Yoruba pe ti oun ba maa darapọ mọ oṣelu, ẹgbẹ to ko gbogbo ẹya mọra ni oun maa darapọ mọ ti oun si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP.
O ni oun gbagbọ pe eto oṣelu ko yẹ lati da ọta silẹ laaarin awọn eeyan eyi lo si mu ki oun ni ibaṣepọ pelu gbogbo awọn ẹya mii.
O fi kun pe gbogbo igba mẹta ọtọọtọ ti oun lọ sọdọ olori ẹgbẹ Afenifere nigba naa, Abraham Adesanya fun atilẹyin wọn, o ni Adesanya sọ fun oun pe iran Yoruba ko ni dibo fun oun, to si n sọ fun oun pe ki oun darapọ mọ ẹgbe oṣelu AD.
O sọ pe oun fesi pada fun-un pe oun ko darapọ mọ AD nitori oun ri ẹgbẹ oṣelu naa bi eyi to jẹ ti ẹya Yoruba nikan.
Nigba to n sọrọ nipa ẹsun ti Osoba fi kan pe Obasanjo beere fun atilẹyin awọn gomina AD lati mu iduro ire ba iṣejọba rẹ, o ni oun ni awọn igbimọ alaṣẹ atawọn gomina ipinlẹ ọgbọn to n ṣe atilẹyin fun oun ati pe oun ko nilo wọn fun nnkankan.
Aarẹ tẹlẹ ri naa bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ Afenifere fun bi wọn ṣe ti ẹya bọ ẹgbẹ oṣelu wọn to si ni ọpọ awọn olori egbẹ naa bii oloye Adesanya, Gani Daudu ati Ayo Adebanjo ni wọn kabaamọ eyi ṣaaju iku wọn.
Nigbẹyin Obasanjo kan saara si Osoba fun ipese ilẹ ti wọn kọ yara ikawe Olusegun Obasanjo Presidential Library to w ani ilu Abeokuta si.
O ni ipese ilẹ naa ni ohun kan gboogi ti Osoba ṣe fun ipinlẹ Ogun lasiko iṣejọba rẹ.
Bakan naa lo rọ Osoba lati ni iwa irẹlẹ pe eto oṣelu ko yẹ ko ba iwa ọmọluabi jẹ, ti ko si yẹ ko ba ibaṣepọ pẹlu ẹni ti wọn ko ba jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa jẹ.




























